ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 9
  • Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Ìmọ̀ràn Àgbàlagbà Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2019
  • Ẹ̀yin Òbí Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn Ọmọ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 9
Bàbá kan ń bá ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sọ̀rọ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn òbí kan sọ

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan lóde òní, àwọn ọmọdé máa ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ káwọn òbí wọn tọ́ wọn sọ́nà. Àmọ́ láwọn ilẹ̀ míì, àwọn ọmọdé sábà máa ń gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà wọn.

Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ojúgbà wọn làwọn ọmọdé ti ń gbàmọ̀ràn, wọ́n ò ní fi bẹ́ẹ̀ ka ìmọ̀ràn àwọn òbí sí. Nígbà táwọn ọmọ náà bá fi máa di ọ̀dọ́, á wá máa ṣe àwọn òbí wọn bíi pé ẹnu wọn ò ká wọn mọ́. Ìyẹn ò sì jẹ́ tuntun mọ́! Táwọn ọmọ bá ti ń lo àkókò púpọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn ọmọdé bíi tiwọn, ṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn ọmọ náà ló tọ́ ara wọn dàgbà dípò àwọn òbí wọn.

Kí nìdí tó fi sábà máa ń rọrùn fáwọn ọmọdé láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn dípò àwọn òbí wọn? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

  • Ilé Ìwé. Táwọn ọmọdé bá ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn ọmọdé bíi tiwọn, wọ́n á di kòríkòsùn wọn, wọ́n á sì máa fara mọ́ ohun táwọn ojúgbà wọn bá sọ fún wọn ju ohun táwọn òbí wọn sọ fún wọn lọ. Ìṣòro náà tiẹ̀ lè wá burú sí i táwọn ọmọ náà bá di ọ̀dọ́.

    Ọmọkùnrin kan ń juwọ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílé ìwé

    Ó yẹ káwọn ọmọ ká ohun táwọn òbí wọ́n bá sọ fún wọn sí pàtàkì ju tàwọn ọmọ ilé ìwé wọn lọ

  • Kò fi bẹ́ẹ̀ sáyè láti wà papọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìdílé, táwọn ọmọdé bá ti dé láti ilé ìwé, wọn ò kì í bá ẹnikẹ́ni nílé, bóyá tórí pé àwọn òbí wọn wà níbi iṣẹ́.

  • Ohun táwọn ọ̀dọ́ nífẹ̀ẹ́ sí. Gbàrà táwọn ọmọdé bá ti di ọ̀dọ́, ohun tó sábà máa ń gbà wọ́n lọ́kàn jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa múra, bí wọ́n á ṣe máa sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì máa hùwà bíi tàwọn ọ̀dọ́ míì. Wọ́n máa ń ka ohun táwọn ojúgbà bá sọ fún wọn sí ju tàwọn òbí wọn.

  • Ìpolówó ọjà. Àwọn nǹkan táwọn oníṣòwò máa ń ṣe àtàwọn eré ìnàjú tí wọ́n máa ń gbé jáde sábà máa ń wà fáwọn ọ̀dọ́ nìkan. Ìdí nìyẹn tó fi túbọ̀ ṣòro fáwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ láti lóye ara wọn. Dr. Robert Epstein kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ńlá ló máa kógbá wọlé táwọn oníṣòwò ò bá ṣe àwọn nǹkan tó wà fáwọn ọ̀dọ́ nìkan mọ́.”a

Ohun tó o lè ṣe

  • Jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti ọmọ rẹ lágbára.

    Bíbélì sọ pé: “Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”​—⁠Diutarónómì 6:​6, 7.

    Kò burú tàwọn ọmọ rẹ bá láwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ ojúgbà wọn, àmọ́ má ṣe jẹ́ káwọn ojúgbà wọn gba iṣẹ́ rẹ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí òbí. Àmọ́ má sọ̀rètí nù: Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé, ọ̀pọ̀ ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ ló máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti múnú wọn dùn. Tó o bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, wàá lè máa darí wọn ju báwọn ojúgbà wọn ti ń ṣe lọ.

    Bàbá kan àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jọ wà papọ̀ níbi ìgbọ́kọ̀sí, wọ́n jọ ń lo Kọ̀ǹpútà, wọ́n sì jọ ń tún ọkọ̀ ṣe

    “Ó yẹ kó o máa wáyè fáwọn ọmọ rẹ, ẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́, bíi kẹ́ ẹ jọ se oúnjẹ, kẹ́ ẹ jọ tún ilé ṣe, kẹ́ ẹ sì jọ ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá. Ẹ máa ṣeré papọ̀, bíi kẹ́ ẹ máa gbá géèmù, kẹ́ ẹ máa wo fíìmù tàbí tẹlifíṣọ̀n papọ̀. Má ṣe rò pé, tó o bá ṣáà ti lo àkókò díẹ̀ tó nítumọ̀ pẹ̀lú wọn, ìyẹn náà ti tó. Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, wàá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn!”​—⁠Lorraine.

  • Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yan ojúgbà wọn nìkan lọ́rẹ̀ẹ́.

    Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ọmọdé ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.”​—Òwe 22:15.

    Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀. Àmọ́, ó yẹ kí wọ́n ṣọ́ra, torí pé ọmọ kan lè láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, síbẹ̀ kó má láwọn ọ̀rẹ́ tọ́jọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, tó lè ràn án lọ́wọ́ bó ṣe ń dàgbà. Àwọn ọ̀dọ́ ò lè rí ìtọ́sọ́nà tó wúlò lọ́dọ̀ ojúgbà wọn, àwọn òbí wọn nìkan ló lè pèsè ìtọ́sọ́nà tó dára jùlọ.

    “Ojúgbà ọmọ kan lè ní òye nípa àwọn ohun kan, àmọ́ wọn ò ní ìrírí, wọn ò sì ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n lè fi ran ọ̀dọ́ bíi tiwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tó dára jùlọ nígbèésí ayé. Tàwọn ọ̀dọ́ bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn, wọ́n á dẹni tó gbọ́n dáadáa níbi tọ́jọ́ orí wọn mọ.”​—⁠Nadia.

  • Pèsè ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”​—⁠Òwe 13:⁠20.

    Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọ́n máa kọ́ lára ẹ tó o bá ń lo àkókò pẹ̀lú wọn. Àpẹẹrẹ rere ló yẹ kó o jẹ́ fún wọn.

    “Àpẹẹrẹ àwọn òbí ló ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ káwọn ọmọ tẹ̀ lé. Tí wọn bá kọ́ àwọn ọmọ pé ó yẹ kí wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ohun tàwọn ọmọ náà máa ṣe nìyẹn tí wọ́n bá dàgbà.”​—⁠Katherine.

Ohun táwọn òbí kan sọ

Wendell àti ìyàwó rẹ̀, Susan

“Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń lo òye díẹ̀ tí wọ́n ní nígbèésí ayé láti ṣe ìpinnu, irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ sì lè kó wọ́n sí wàhálà. Àmọ́ tí wọ́n bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn, wọ́n á túbọ̀ lóye bí nǹkan ṣe rí torí pé wọ́n tí kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àwọn òbí wọn, èyí sì máa jẹ́ kí wọ́n ṣe ìpinnu tó dáa.”​—⁠Wendell àti ìyàwó rẹ̀, Susan.

Courtney àti ọkọ rẹ̀ Erik

“Máa ṣe àwọn nǹkan táwọn ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ sí, kódà bí kò bá tiẹ̀ wù ẹ́ láti ṣe. Jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti wà pẹ̀lú wọn. Jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán, ẹni tí wọ́n lè sọ àṣírí wọn fún àti ẹni tí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé o fẹ́ kí wọ́n láyọ̀.”​—⁠Courtney àti ọkọ rẹ̀, Erik.

Àtúnyẹ̀wò: Bí Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà

  • Jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti ọmọ rẹ lágbára. Àwọn ọmọ rẹ lè yan ojúgbà wọn lọ́rẹ̀ẹ́, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí wọ́n gba ipò rẹ gẹ́gẹ́ bi òbí mọ́ ẹ lọ́wọ́.

  • Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yan ojúgbà wọn nìkan lọ́rẹ̀ẹ́. Ọmọ kan lè láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, síbẹ̀ ó yẹ kó láwọn ọ̀rẹ́ tọ́jọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́ bó ṣe ń dàgbà. Àwọn ọ̀dọ́ ò lè rí ìtọ́sọ́nà tó wúlò lọ́dọ̀ ojúgbà wọn, àwọn òbí wọn nìkan ló lè pèsè ìtọ́sọ́nà tó dára jùlọ.

  • Pèsè ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọ́n máa kọ́ lára ẹ tó o bá ń lo àkókò pẹ̀lú wọn.

a Látinú ìwé Teen 2.0—Saving Our Children and Families From the Torment of Adolescence.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́