Ẹ̀KỌ́ 5
Ìmọ̀ràn Àgbàlagbà Ṣe Pàtàkì
ÌMỌ̀RÀN ÀGBÀLAGBÀ
Àwọn ọmọ nílò ìtọ́sọ́nà àti ìmọ̀ràn àgbàlagbà kí ayé wọn lè lójú. Ìwọ tó o jẹ́ òbí wọn lo sì wà ní ipò tó dáa jù láti fún wọn ní ìmọ̀ràn kó o sì tọ́ wọn sọ́nà, ojúṣe rẹ ni. Àmọ́, àwọn àgbàlagbà míì náà tún lè fún ọmọ rẹ ní ìmọ̀ràn.
KÍ NÌDÍ TÍ ÌMỌ̀RÀN ÀGBÀLAGBÀ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ọ̀dọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ lo àkókò pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà. Bí àpẹẹrẹ:
Ilé ìwé làwọn ọmọdé ti sábà máa ń lo àkókò wọn jù, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn àgbàlagbà nílé ìwé.
Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn ọmọ bá fi máa pa dà sílé, wọn kì í dé bá ẹnikẹ́ni torí pé àwọn òbí wọn ti lọ síbi iṣẹ́.
Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà ní ọdún mẹ́jọ sí méjìlá sábà máa ń lo nǹkan bí wákàtí mẹ́fà lójoojúmọ́ nídìí tẹlifísọ̀n, orin tàbí géèmù.a
Ìwé kan tó ń jẹ́ Hold On to Your Kids sọ pé: “Kàkà kí àwọn ọ̀dọ́ máa wá ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni lọ sọ́dọ̀ ìyá wọn, bàbá wọn àti olùkọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì, ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bíi tiwọn ni wọ́n ti ń gbàmọ̀ràn.”
BÓ O ṢE LÈ TỌ́ ỌMỌ RẸ SỌ́NÀ
Lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ máa ń fẹ́ kí àwọn òbí wọn tọ́ wọn sọ́nà. Kódà, àwọn olùṣèwádìí sọ pé tí àwọn ọmọ bá ti ń sún mọ́ ìgbà ọ̀dọ́, wọ́n máa ń fẹ́ gba ìmọ̀ràn àwọn òbí wọn dípò tàwọn ẹgbẹ́ wọn. Dr. Laurence Steinberg tiẹ̀ sọ nínú ìwé You and Your Adolescent pé: “Àwọn òbí máa ń nípa tó lágbára lórí ìwà táwọn ọmọ wọn ń hù láti ìgbà èwe títí dé ìgbà ọ̀dọ́.” Ó tún sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ mọ èrò àwọn òbí wọn kódà tí wọ́n ò bá tiẹ̀ ṣe tán láti tẹ̀ lé ohun tí wọn bá sọ.”
Ní báyìí tí ọmọ ẹ ń wojú rẹ fún ìmọ̀ràn, lo àǹfààní yìí láti tọ́ ọ sọ́nà. Lo àkókò pẹ̀lú ọmọ rẹ, máa sọ èrò rẹ fún un, jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, kó o sì sọ àwọn ohun tí ojú ẹ ti rí àtàwọn ẹ̀kọ́ tó o ti kọ́.
Yan ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà fún ọmọ rẹ.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” —Òwe 13:20.
Ṣé o mọ ẹnì kan tó níwà àgbà, tó máa ń fúnni nímọ̀ràn tó dára, tó sì lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ọmọ rẹ? Ó máa dáa kó o ṣètò fún ọmọ rẹ láti máa lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú ẹni náà. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o gbé ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí fún ẹlòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, àfikún ni ìmọ̀ràn tí ẹni náà bá ń fún ọmọ rẹ máa jẹ́ sí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ọ. Ọ̀kan lára àwọn tó ní irú àǹfààní yẹn nínú Bíbélì ni Tímótì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni, ó jàǹfààní nínú àjọṣe tó ní pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, bákan náà Pọ́ọ̀lù jàǹfààní nínú bó ṣe bá Tímótì ṣọ̀rẹ́.—Fílípì 2:20, 22.
Nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìdílé máa ń gbé pa pọ̀, àmọ́ ní báyìí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ torí pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí, òbí àgbà àtàwọn mọ̀lẹ́bí míì ń gbé níbi tó jìnnà síra. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ rí, ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó ní irú ìwà tí wàá fẹ́ kí ọmọ rẹ ní.
a Ìwádìí yẹn fi hàn pé, àwọn ọ̀dọ́ ní tiwọn máa ń lo nǹkan bí wákàtí mẹ́sàn-án lójoojúmọ́ nídìí tẹlifísọ̀n, orin tàbí géèmù. Èyí kò sí lára àkókò tí wọ́n ń lò lórí ìkànnì nílé ìwé tàbí fún iṣẹ́ ilé ìwé wọn.