Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Ọmọ Wọn Tó Ti Bàlágà
FOJÚ inú wò ó pé o rìnrìn àjò láti ilẹ̀ kan tó móoru lọ sí ilẹ̀ olótùútù. Gbàrà tó o bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ òfuurufú lo ti rí i pé ńṣe ni yìnyín bo gbogbo ilẹ̀. Ǹjẹ́ ipò ojú ọjọ́ tó yí pa dà yìí máa bá ẹ lara mu? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa bá ẹ lára mu, àmọ́ wàá ni láti ṣe àwọn àtúnṣe mélòó kan.
Irú ohun kan náà lo máa dojú kọ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ bá bàlágà. Lójijì, ńṣe ló máa dà bíi pé ojú ọjọ́ ti yí pa dà. Ní báyìí, ó máa tẹ́ ọmọ rẹ ọkùnrin lọ́rùn láti wà lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà rẹ̀, ju kó wà lọ́dọ̀ rẹ lọ́, bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ọmọ rẹ obìnrin tó jẹ́ pé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́jọ́ kan ló máa ń fẹ́ sọ fún ẹ tẹ́lẹ̀ á wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún ẹ ní ìdáhùn ṣókí.
Tó o bá béèrè pé “Báwo ni iléèwé lónìí?”
Ńṣe ló kàn máa dáhùn pé “Ó dáa.”
Á dákẹ́.
Tó o bá béèrè pé “Ṣé kò sí ìṣòro kankan?”
Ńṣe ló kàn máa dáhùn pé “Kò sí.”
Á tún dákẹ́.
Kí ló fa àyípadà yìí? Nígbà tí ìwé Breaking the Code ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ṣé máa ń rí kí wọ́n tó bàlágà, ó ní “ńṣe ló dà bí pé o ní tíkẹ́ẹ̀tì láti wọ inú yàrá tí wọ́n ti ń múra fún àwọn tó fẹ́ ṣe eré orí ìtàgé kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ eré, ìyẹn ni pé o mọ gbogbo nǹkan nípa àwọn ọmọ rẹ, àmọ́ ní báyìí kò sí tíkẹ́ẹ̀tì yẹn lọ́wọ́ rẹ mọ́, àyè ìjókòó tó wà fún gbogbo èèyàn lo wá jókòó sí, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o kò ní rí àyè jókòó dáadáa.”
Ǹjẹ́ ó wá túmọ̀ sí pé o kò lè sún mọ́ àwọn ọmọ rẹ tó ti bàlágà? Rárá o. O lè sún mọ́ àwọn ọmọ rẹ ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń bàlágà. Lákọ̀ọ́kọ́, àkókò tó ń múni lórí yá ni àkókò yìí, àmọ́ ó tún jẹ́ àkókò tí nǹkan kò rọgbọ fún àwọn ọmọ bí wọ́n ṣe ń dàgbà, torí náà o ní láti lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn gan-an lákòókò yìí.
Bíbọ́ sí Ipò Àgbà
Èrò tí àwọn olùṣèwádìí ní nígbà kan ni pé tí ọmọ bá fi máa pé ọmọ ọdún márùn-ún, ọpọlọ rẹ̀ á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàgbà débi tó yẹ kó dé. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n gbà pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọ lè tóbi díẹ̀ sí i lẹ́yìn tí ọmọ bá ti kọjá ọdún márùn-ún, iṣẹ́ rẹ̀ máa ń sunwọ̀n sí i bí ọmọ ṣe ń dàgbà. Bí àwọn ọmọ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà, àwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara wọn máa ń mú kí ìrònú wọn yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó o bá sọ fún àwọn ọmọdé ni wọ́n máa fara mọ́, àmọ́ ní ti àwọn ọmọ tó ti bàlágà wọ́n máa ń ro àròjinlẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nídìí ọ̀ràn kan. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Wọ́n máa ń fẹ́ kí nǹkan dá wọn lójú, wọn kì í sì í tijú láti sọ èrò wọn jáde.
Paolo tó wá láti orílẹ̀-èdè Ítálì kíyè sí ìyípadà yìí lára ọmọ rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Ó sọ pé: “Bí mo bá wo ọmọkùnrin mi tó ti ń bàlágà, ó máa ń ṣe mí bíi pé ọkùnrin kan tó ti dàgbà ló wà níwájú mi, kì í ṣe ọmọdé mọ́. Èyí kọjá ọ̀rọ̀ pé kí ọmọ dàgbà sí i. Ohun tó ń jọ mí lójú ni bó ṣe máa ń ronú. Ẹ̀rù kì í bà á láti sọ èrò rẹ̀ jáde, kó sì dúró lórí ohun tó sọ!”
Ǹjẹ́ o ti kíyè sí ohun tó jọ èyí nípa ọmọ rẹ tó ti bàlágà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó o bá ti sọ ló máa ń tẹ̀ lé nígbà tó wà lọ́mọdé. Nígbà yẹn, tó bá béèrè pé kí nìdí? Gbogbo ohun tó o ní láti sọ kò ju pé “ohun tí mo sọ ni kó o ṣe.” Àmọ́ ní báyìí tó ti bàlágà, ó máa fẹ́ mọ ìdí, kódà ó ṣeé ṣe kó máa kọminú sí àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe nínú ìdílé yín. Nígbà míì, bó ṣe máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà máa ń jẹ́ kó dà bí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ.
Àmọ́ má ṣe parí èrò sí pé ńṣe ni ọmọ rẹ tó ti bàlágà ń fẹ́ yí àwọn ìlànà rere tẹ́ ẹ̀ ń tẹ̀ lé pa dà o. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń sapá láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà nígbèésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ kó láti ilé kan lọ sí ilé míì, o sì fẹ́ kó àga, tábìlì àti ṣẹ́ẹ̀fù tó o ní lọ síbẹ̀. Ǹjẹ́ ó máa rọrùn láti rí àyè fún gbogbo rẹ̀ ní ilé tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ? O lè má rí àyè fún gbogbo wọn. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, o kò ni sọ ohun iyebíye nù.
Ohun tó jọ èyí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ tó ti bàlágà, bó ṣe ń múra sílẹ̀ láti fi “baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lóòótọ́, ọjọ́ náà ṣì lè jìn; ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà kò sì tíì di àgbàlagbà. Àmọ́ láwọn ọ̀nà kan, ó ti ń múra sílẹ̀. Láàárín ìgbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí ọdún mọ́kàndínlógún, ó ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà tẹ́ ẹ fi tọ́ ọ dàgbà, ó sì ń pinnu èwo ló máa bá a dé ipò àgba.a
Ẹ̀rù lè bà ẹ́ láti gbọ́ pé ọmọ rẹ ń ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bí ọmọ rẹ bá di àgbàlagbà, kìkì àwọn ìlànà tó kà sí pàtàkì nìkan ni yóò máa tẹ̀ lé. Torí náà, ní báyìí tí ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà ṣì ń gbé pẹ̀lú rẹ, àkókò nìyí fún un láti ṣèwádìí tó jinlẹ̀ nípa àwọn ìlànà tí yóò máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé rẹ̀.—Ìṣe 17:11.
Kò sí àní-àní pé, ó máa ṣàǹfààní pé kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà ṣe èyí. Torí pé, tó bá kàn ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ láìronú jinlẹ̀ báyìí, bí yóò ṣe máa tẹ̀ lé ìlànà àwọn ẹlòmíì láìronú jinlẹ̀ náà nìyẹn nígbà tó bá yá. (Ẹ́kísódù 23:2) Bíbélì sọ pé bí ọ̀dọ́ kan bá jẹ́ ẹni tí àwọn èèyàn lè tètè tàn jẹ, irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni “tí ọkàn-àyà kù fún,” èyí tó túmọ̀ sí pé ó jẹ́ ẹni tí kò ní ìfòyemọ̀. (Òwe 7:7) Ọ̀dọ́ kan tí ohun tó ń ṣe kò dá lójú lè dẹni tí “a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn.”—Éfésù 4:14.
Báwo lo ṣe lè ṣé e tí èyí kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ? Ńṣe ni kó o rí i dájú pé ọmọ rẹ ní ohun mẹ́ta yìí:
1 AGBÁRA ÌWÒYE
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti . . . kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Àmọ́ o lè sọ pé ‘mo ti kọ́ ọmọ mi láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.’ Kò sí àní-àní pé ẹ̀kọ́ tó o kọ́ ọmọ rẹ ṣe é láǹfààní nígbà yẹn, ó sì múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ìpele tó kàn nínú ìdàgbàsókè rẹ̀. (2 Tímótì 3:14) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn èèyàn ní láti kọ́ agbára ìwòye wọn. Àwọn ọmọdé lè ní ìmọ̀ nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, àmọ́ àwọn ọmọ tó ti bàlágà ní láti “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Kọ́ríńtì 14:20; Òwe 1:4; 2:11) O kò ní fẹ́ kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà kàn máa tẹ̀ lé ohun tó o bá sọ láìronú nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n wàá fẹ́ kó máa ronú jinlẹ̀ dáadáa. (Róòmù 12:1, 2) Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ọ̀nà kan ni pé kó o jẹ́ kó máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Má ṣe máa dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kó o sì sapá láti má ṣe bínú sódì, kódà tó bá sọ ohun tí o kò fẹ́ gbọ́. Bíbélì sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19; Òwe 18:13) Síwájú sí i Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Tó o bá fetí sílẹ̀, wàá lè mọ ohun tó ń jẹ ọmọ rẹ lọ́kàn.
Tó o bá wá ń sọ̀rọ̀, gbìyànjú láti máa lo ìbéèrè dípò tí wàá fi máa pàṣẹ fún un. Nígbà míì, Jésù máa ń béèrè ìbéèrè bíi “Kí ni ẹ̀yin rò?” kí ó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn míì tó tiẹ̀ jẹ́ olórí kunkun. (Mátíù 21:23, 28) O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí nígbà tó o bá ń bá ọmọ rẹ tó ti bàlágà sọ̀rọ̀, kódà tí èrò rẹ̀ bá yàtọ̀ sí tìrẹ. Bí àpẹẹrẹ:
Bí ọmọ rẹ tó ti bàlágà bá sọ pé: “Mi ò rò pé mo gba Ọlọ́run gbọ́.”
Dípò tí wàá fi sọ pé: “Ìwọ lo tún ń sọ báyìí, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ tá a kọ́ ẹ—mo mọ̀ pé o gba Ọlọ́run gbọ́!”
O lè sọ pé: “Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?”
Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ kí ọmọ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Ìdí ni pé, ohun tó sọ lo ṣì gbọ́ báyìí, o ṣe pàtàkì pé kó o mọ ohun tó ń rò lọ́kàn. (Òwe 20:5) Ọmọ rẹ lè gbà pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, àmọ́ ó lè jẹ́ pé títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run ni ìṣòro rẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń ṣe ọ̀dọ́ kan bíi pé kó rú òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lè gbìyànjú láti máa sọ lọ́kàn rẹ̀ pé Ọlọ́run kò sí. (Sáàmù 14:1) Ó lè máa ronú pé ‘Bó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kò sí, kò sídìí láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nìyẹn.’
Tó bá jẹ́ pé irú èrò tí ọmọ rẹ ní nìyẹn, ọmọ náà lè ní láti ronú lórí ìbéèrè yìí, Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ gbà pé àǹfààní mi ni àwọn ìlànà Ọlọ́run wà fún? (Aísáyà 48:17, 18) Tí ọmọ rẹ bá gbà pé àǹfààní òun ni àwọn ìlànà Ọlọ́run wà fún, ńṣe ni kó o ràn án lọ́wọ́ láti rí i pé ó yẹ kó ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n máa ṣe é láǹfààní.—Gálátíà 5:1.
Bí ọmọ rẹ tó ti bàlágà bá sọ pé: “Ó lè jẹ́ ẹ̀sìn tiyín ni èyí tí ẹ̀ ń ṣe yìí, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ ẹ̀sìn tèmi.”
Dípò tí wàá fi sọ pé: “Ẹ̀sìn wa ni, àwa la bí ẹ, ohun tá a bá sì sọ fún ẹ lo gbọ́dọ̀ gbà gbọ́.”
O lè sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ńlá lo sọ yìí o. Àmọ́, tí o kò bá fara mọ́ ohun tí mo gbà gbọ́, ó yẹ kó o ní òmíràn tí wàá fi rọ́pò rẹ̀. Kí wá làwọn ohun tó o gbà gbọ́? Àwọn ìlànà wo lo ronú pé ó tọ́ láti máa tẹ̀ lé?”
Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Torí pé tó o bá fèrò wérò pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà yìí, ó lè mú kó tún inú rò. Ó lè ya ọmọ rẹ lẹ́nu pé ohun tó o gbà gbọ́ ni òun náà gbà gbọ́, kó sì wá jẹ́ pé nǹkan mìíràn ló jẹ́ ìṣòro rẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ọmọ rẹ kò mọ bó ṣe máa ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíì. (Kólósè 4:6; 1 Pétérù 3:15) Ó sì lè jẹ́ pé ìfẹ́ ọmọbìnrin tàbí ọmọkùnrin kan ló kó o sí i lórí, tó sì jẹ́ pé ìgbàgbọ́ onítọ̀hún kò bá tirẹ̀ mu. Rí i pé o mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro náà gan-an, kó o sì ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí òun náà lè mọ̀ ọ́n. Bó bá ṣe ń lo agbára ìwòye rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni á ṣe wà ní ìmúrasílẹ̀ tó láti bọ́ sí ipò àgbà.
2 ÀWỌN ỌMỌ NÍLÒ ÌTỌ́SỌ́NÀ ÀGBÀLAGBÀ
Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan lóde òní, kò sí ohun tó jọ “ìbínú líle àti ìdààmú ọkàn” tí àwọn afìṣemọ̀rònú kan sọ pé àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún máa ń ní. Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé ní irú àwùjọ bẹ́ẹ̀, látìgbà tí àwọn ọ̀dọ́ ti wà lọ́mọdé ni wọ́n ti máa ń da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà. Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà, wọ́n máa ń gbafẹ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà, wọ́n sì máa ń gbé ojúṣe tó jẹ́ ti àgbàlagbà lé wọn lọ́wọ́. Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ náà, kò sí àwọn ọ̀rọ̀ bíi “àṣà àwọn ọ̀dọ́,” “ìwà ìpáǹle àwọn ọ̀dọ́,” àti “àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà.”
Àmọ́, ronú nípa àwọn ọ̀dọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé iléèwé tí èrò kún fọ́fọ́ ni wọ́n ń lọ, tó sì jẹ́ pé kìkì àwọn ọmọdé bíi tiwọn ni wọ́n ń rí bá kẹ́gbẹ́. Bí wọ́n bá pa dà délé, wọn kì í bá ẹnì kankan nílé. Bàbá ń lọ sí ibiṣẹ́ ìyá náà ń lọ sí ibiṣẹ́. Kò sí mọ̀lẹ́bí kankan nítòsí. Àwọn ojúgbà wọn nìkan ni wọ́n lè rí bá dá nǹkan pọ̀.b Ǹjẹ́ o rí ewu tó wà níbẹ̀? Kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé wọ́n ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ nìkan là ń sọ o. Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n níwà tó dáa pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkíwà tí wọ́n bá jìnnà sí àwọn àgbàlagbà.
Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, wọ́n kì í ya àwọn ọ̀dọ́ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà.c Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ùsáyà tó di ọba Júdà nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún. Kí ló jẹ́ kí Ùsáyà lè bójú tó ojúṣe ńlá yìí? Kò sí àní-àní pé àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Sekaráyà wà lára àwọn tó ní ipa rere lórí rẹ̀, Bíbélì sọ pé Sekaráyà jẹ́ “olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.”—2 Kíróníkà 26:5.
Ǹjẹ́ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí ìwọ fúnra rẹ ń tẹ̀ lé wà tí wọ́n lè máa tọ́ ọmọ rẹ sọ́nà? Má ṣe jowú ipa rere tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ní lórí ọmọ rẹ. Bí ọmọ rẹ bá ní irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, ó lè jẹ́ kó máa ṣe ohun tó tọ́. Òwe Bíbélì kan sọ pe: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.
3 BÍ ÀWỌN ỌMỌ ṢE LÈ DI ẸNI TÓ DÁŃGÁJÍÁ
Láwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin sọ pé ó ní iye wákàtí tí àwọn ọ̀dọ́ fi gbọ́dọ̀ máa síṣẹ́ lọ́sẹ̀, àwọn iṣẹ́ kan sì wà tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe. Ìdí tí wọ́n fi ṣe òfin yìí ni pé kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ iṣẹ́ tó lè ṣèpalára fún wọn—èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìyípadà tí wọ́n ṣe nínú ọ̀ràn àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin tí wọ́n ṣe nípa àṣà fífi ọmọdé ṣiṣẹ́ jẹ́ láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ewu àti lílò wọ́n ní ìlòkulò, síbẹ̀ àwọn ògbógi kan sọ pé òfin yìí kì í jẹ́ kí wọ́n di ẹni tó dáńgájíá. Ìwé Escaping the Endless Adolescence sọ pé, èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún dẹni “tó máa ń fẹ́ fi agídí gba nǹkan, wọ́n máa ń fẹ́ ní àwọn nǹkan láìjẹ́ pé wọ́n ṣiṣẹ́ fún un.” Ẹni tó kọ ìwé yìí kíyè sí i pé “ohun tó jẹ àwọn èèyàn lógún jù láyé yìí ni pé kí wọ́n máa dá àwọn ọ̀dọ́ lára yá, wọn kò ronú nípa ohun tí àwọn ọ̀dọ́ lè gbé ṣe.”
Ní òdìkejì sí èyí, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ojúṣe pàtàkì nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí. Ọ̀kan lára irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ni Tímótì, tó ṣeé ṣe kó máà tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó pàdé Pọ́ọ̀lù tó ní ipa tó lágbára lórí rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: ‘Máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ sókè bí iná.’ (2 Tímótì 1:6) Ó ṣeé ṣe kí Tímótì máà tíì pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún nígbà tó kúrò nílé, tó sì ń rin ìrìn àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, tó ń ràn án lọ́wọ́ láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń gbé àwọn ará ró. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ti ṣiṣẹ́ pọ̀ fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.”—Fílípì 2:20.
Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń fẹ́ ní ojúṣe tí wọ́n á máa bójú tó, àgàgà tí wọ́n bá rí i pé ó máa jẹ́ kí àwọn máa ṣe iṣẹ́ tó nítumọ̀ tó sì máa mú kí nǹkan dáa sí i. Kì í ṣe pé èyí máa jẹ́ kí wọ́n di àgbàlagbà tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún máa jẹ́ kí wọ́n ṣe dáadáa gan-an nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ọ̀dọ́.
Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Jẹ́ Kí “Ojú Ọjọ́” Tó Yí Pa Dà Bá Wọn Lára Mu
Bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, tó o bá ní ọmọ tó ti bàlágà, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé “ojú ọjọ́” ibi tó o wà báyìí yàtọ̀ sí èyí tó o wà ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè ṣàṣeyọrí, gẹ́gẹ́ bó o ṣe ṣe nígbà tí ọmọ rẹ wà ní àwọn ìpele míì nígbà ìdàgbàsókè wọn.
Máa wo àkókò tí ọmọ rẹ ń bàlágà gẹ́gẹ́ bí àǹfààní tó o ní láti (1) ràn án lọ́wọ́ kó lè dẹni tó ní agbára ìwòye, (2) láti jẹ́ kó rí àgbàlagbà kan tó máa tọ́ ọ sọ́nà àti (3) láti ràn án lọ́wọ́ kó lè dẹni tó dáńgájíá. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń múra ọmọ rẹ sílẹ̀ láti bọ́ sí ipò àgbà.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ tọ́ka sí àkókò ìbàlágà gẹ́gẹ́ bí “àkókò gígùn tẹ́nì kan fi ń dágbére pé ó dàbọ̀.” Fún àfikún àlàyé, wo Ilé Ìṣọ́ May 1, 2009, ojú ìwé 10 sí 12, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b Àwọn eré ìnàjú tí wọ́n dìídì ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ máa ń dá lórí bó ṣe máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ láti wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn, ó sì máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ rò pé àwọn ọ̀dọ́ ní àṣà tí wọ́n ń dá tí kò lè yé àwọn àgbàlagbà.
c Gbólóhùn náà “ìbàlágà” kò sí nínú Bíbélì. Ó ṣe kedere pé àtìgbà ọmọdé ni àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọrun ti máa ń bá àwọn àgbàlagbà da nǹkan pọ̀, kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé àti lẹ́yìn tó dé. Èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ lóde òní.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
“Abiyamọ Gidi Làwọn Òbí Mi”
Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Éfésù 6:4) Àmọ́ ṣá o, wọn kì í fipá mú wọn. Àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé tí àwọn ọmọ wọn bá ti dàgbà dé àyè kan, àwọn fúnra wọn ló máa pinnu ìlànà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé.
Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún méjìdínlógún kan tó ń jẹ́ Aislyn, tó tẹ̀ lé àwọn ìlànà táwọn òbí rẹ̀ fi tọ́ ọ sọ pé: “Ní tèmi o, ẹ̀sìn tí mò ń ṣe kì í ṣe ohun tí mo kàn máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ó jẹ́ nǹkan tó máa ń hàn nínú ọ̀nà tí mò ń gbà gbé ìgbé ayé mi. Ó máa ń ní ipa lórí gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe àti gbogbo ìpinnu mi. Tó fi mọ́ irú àwọn tí mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́, irú ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ níléèwé àti irú ìwé tí mò ń kà.”
Ọ̀dọ́bìnrin yìí mọyì ọ̀nà táwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni gbà tọ́ ọ dàgbà. Ó sọ pé: “Abiyamọ gidi làwọn òbí mi, inú mi dùn gan-an pé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ mi ti mú kó wù mí láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí mo sì ń bá a nìṣó títí dòní olónìí. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì wà láàyè, mi ò ní ṣíwọ́ títẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn òbí mi.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jẹ́ kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà máa sọ tinú rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí àgbàlagbà kan bá wà tó ń tọ́ ọmọ rẹ sọ́nà, èyí lè ní ipa rere lórí ọmọ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Iṣẹ́ tó nítumọ̀ máa ń mú kí àwọn ọ̀dọ́ di ẹni tó dáńgájíá