Ohun Tí Àwọn Òbí Sọ
Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ onígbọràn? Báwo lo ṣe lè kọ́ wọn láwọn ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní bí wọ́n ṣe ń bọ́ sípò àgbà? Wo ohun tí àwọn òbí káàkiri ayé sọ.
ÀJỌṢE PẸ̀LÚ ÀWỌN ÈÈYÀN ÀTI IṢẸ́ ILÉ
“Tá a bá ń jẹun pa pọ̀ tá a sì ń sọ bí ìgbòkègbodò ọjọ́ náà ṣe lọ sí, ńṣe ni ọmọ kọ̀ọ̀kan máa ń kọ́ béèyàn ṣe ń fetí sílẹ̀. Bí wọ́n bá rí bí àwa tá a jẹ́ òbí wọn ṣe ń fetí sílẹ̀ dáadáa, èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n kọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó kù, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ka ara wọn sí.”—Richard, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Inú wa máa ń dùn tá a bá rí i tí àwọn ọmọ wa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, tí wọ́n sì ń yanjú àwọn èdèkòyédè tí wọ́n bá ní láì jẹ́ pé a bá wọn dá sí i. Ara wọn sì máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ń bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀.”—John, South Africa.
“Mo máa ń ṣe àṣìṣe nígbà míì, torí náà àwọn ìgbà kan wà tí mo máa ń ṣe ohun tó dun àwọn ọmọ mi láìmọ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí n tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ mi.”—Janelle, Ọsirélíà.
“A kọ́ àwọn ọmọ wa láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ ilé. Bá a ṣe ń kọ́ wọn láti máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní máa ń jẹ́ kí nǹkan lọ dáadáa nínú ìdílé wa, kí aláàfíà sì jọba, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn náà ṣe àṣeyọrí.”—Clive, Ọsirélíà.
“Lóòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn ọmọ wa bí wọ́n á ṣe máa lóye ara wọn, kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì máa dárí ji ara wọn.”—Yuko, Japan.
ÌMỌ́TÓTÓ ÀTI ÌLERA
“Nígbà tí àwọn ọmọ wa ṣì kéré, a kọ́ wọn pé kí wọ́n máa dá wẹ̀ fúnra wọn, a sì ṣé e lọ́nà táá fi máa wù wọ́n láti ṣe, a gbẹ́ ọṣẹ ní àwòrán èèyàn, wọ́n máa ń lo ọṣẹ ìfọrun tí wọ́n ya àwòrán àwọn bèbí sí, wọ́n sì máa ń lo kàn-ǹ-kàn tá a gé ní àwòrán àwọn ẹranko.”—Edgar, Mẹ́síkò.
“Nígbà tá à ń gbé níbi tí kò sí omi ẹ̀rọ, mo máa ń rí i dájú pé ọṣẹ àti korobá omi wà níbi tó rọrùn, kó lè ṣeé ṣe fún wa láti fọ ọwọ́ wa nígbà tá a bá wọlé.”—Endurance, Nàìjíríà.
“A máa ń fún àwọn ọmọ wa ní oúnjẹ tó ṣara lóore lójoojúmọ́, a sì ṣàlàyé ìdí tí jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore fi ṣe pàtàkì. Àwọn ọmọ wa máa ń fẹ́ mọ onírúurú èròjà tí mo máa ń fi sínú oúnjẹ, torí náà mo máa ń jẹ́ ká jọ gbọ́únjẹ. Àkókò tá a fi ń ṣe gbogbo ìyẹn tún máa ń jẹ́ ká lè jọ sọ̀rọ̀.”—Sandra, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Eré ìmárale ṣe pàtàkì, torí náà àwa tá a jẹ́ òbí máa ń gbìyànjú láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Àwọn ọmọ wa fẹ́ràn kí ìdílé wa máa sáré kúṣẹ́kúṣẹ́, ká máa lúwẹ̀ẹ́, ká máa gbá tẹníìsì, bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ tàbí ká gun kẹ̀kẹ́ pa pọ̀. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe pé eré ìmárale ṣe pàtàkì nìkan ni, ó tún máa ń dáni lára yá.”—Keren, Ọsirélíà.
“Ohun tí àwọn ọmọ nílò jù lọ ni pé kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Kò sí ohun tá a lè fi rọ́pò rẹ̀, ì báà jẹ́ owó, ẹ̀bùn tàbí rírin ìrìn àjò. Iṣẹ́ àárọ̀ nìkan ni mo máa ń ṣe nígbà tí àwọn ọmọ bá ti lọ sílé ìwé. Tó bá wá di ọ̀sán, màá lè wà pẹ̀lú wọn.”—Romina, Ítálì.
ÌBÁWÍ
“A ti wá rí i pé kò sí irú ìbáwí kan tó dára jù lọ, bí ipò nǹkan bá ṣe rí ló máa pinnu. Nígbà míì ó lè jẹ́ pé ńṣe lèèyàn kàn máa bá ọmọ sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀, ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ńṣe lèèyàn máa gba àwọn àǹfààní kan lọ́wọ́ ọmọ náà.”—Ogbiti, Nàìjíríà.
“Tá a bá sọ fún àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n ṣe ohun kan, a máa ń ní kí wọ́n tún un sọ, ká lè mọ̀ bóyá ó yé wọn. A sì máa ń ṣe ohun tá a bá sọ. Tá a bá fẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ́ onígbọràn, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣe wa nípa fífún wọn ní ìbáwí tí wọ́n bá ṣàìgbọràn.”—Clive, Ọsirélíà.
“Mo ti rí i pé ó gbéṣẹ́ gan-an kí n máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí mo bá ń bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ìyẹn máa jẹ́ kí n lè máa wo ojú wọn. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè máa pọkàn pọ̀ tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lè máa wo bí mo ṣe ń ṣe ojú, torí pé ojú lọ̀rọ̀ wà.”—Jennifer, Ọsirélíà.
“A kì í sọ fún àwọn ọmọ wa pé, ‘O ò gbọ́ràn rí láyé ẹ,’ bó tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ díẹ̀ lè wà níbẹ̀. Bákan náà, a kì í bá àwọn ọmọ wa wí lójú àwọn yòókù. A lè rọra fi ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sọ̀rọ̀ tàbí ká pe ẹni tó bá ṣẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tá a sì máa bá òun nìkan sọ̀rọ̀.”—Rudi, Mòsáńbíìkì.
“Èèyàn lè tètè nípa lórí àwọn ọmọdé, wọ́n sì fẹ́ràn kí wọ́n máa fara wé àwọn ẹlòmíì. Nítorí náà, a ní láti fi ìwà ọmọlúwàbí tó dá lórí àwọn ìlànà tó dára rọ́pò ipa búburú tó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ iléèwé wọn, ilé iṣẹ́ tó ń gbé ìsọfúnni jáde àti àwọn èèyàn tó yí wọn ká ní lórí àwọn ọmọ wa. Tá a bá ti fi ìwà rere kọ́ wọn, ó máa jẹ́ kí wọ́n lè sá fún ohunkóhun tó lè ṣe ìpalára fún wọn.”—Grégoire, Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò.
“Ìbáwí ní láti ṣe pàtó, èèyàn ò gbọ́dọ̀ ki àṣejù bọ̀ ọ́, kó má sì ṣe ségesège. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ mọ ohun tó o máa ṣe fún wọn bí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa, kí wọ́n sì mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré.”—Owen, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
“Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
ÌSỌFÚNNI NÍPA ÌDÍLÉ
Bí Mo Ṣe Ṣàṣeyọrí Gẹ́gẹ́ Bí Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Lucinda Forster
Kí lohun tó ṣòro fún ẹ gan-an gẹ́gẹ́ bí òbí tó ń dá tọ́mọ?
Kò rọrùn láti jẹ́ òbí, àmọ́ gẹ́gẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ, ó tún wá ṣòro fún mi gan-an láti máa lo àkókò mi àti okun mi bó ṣe yẹ. Ó máa ń gba àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ ní àwọn ìlànà àti ìwà rere, kéèyàn sì tún wá àyè láti sinmi kó sì tún bá wọn ṣeré. Àkókò tó yẹ kí n fi sinmi ni mo sábà máa ń fi ṣe àwọn iṣẹ́ ilé.
Báwo lo ṣe máa ń wá àyè láti bá àwọn ọmọbìnrin rẹ sọ̀rọ̀?
Lẹ́yìn tí ọkọ àti aya bá kọ ara wọn sílẹ̀, ọkàn àwọn ọmọ kì í balẹ̀, inú sì máa ń bí wọn. Mo ti wá rí i pé bí ìṣòro bá wáyé, wíwo ojú àwọn ọmọ àti fífi ohùn jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì. Mo máa ń dúró dìgbà tí ara wa bá balẹ̀, màá wá sapá láti sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn láì sọ ọ́ di ọ̀ràn ńlá. Mo máa ń ní kí wọ́n sọ èrò wọn, màá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ, màá sì fi hàn pé mo ka èrò wọn sí pàtàkì. Mo máa ń fẹ́ mọ bí ẹ̀kọ́ wọn ṣe ń lọ sí, mo sì máa ń gbóríyìn fún wọn nítorí ohun tí wọ́n ṣe. Orí tábìlì kan náà la ti máa ń jẹun, ara sì máa ń tù wá dáadáa. Mo sì máa ń sọ fún wọn ní gbogbo ìgbà pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
Báwo lo ṣe máa ń bá wọn wí?
Àwọn ọmọdé nílò ìlànà tó ṣe kedere, ó sì ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa dúró lórí ohun tó bá sọ. Mi ò kì í fọwọ́ tó le mú wọn, àmọ́ mi ò gba gbẹ̀rẹ́. Mo máa ń fèròwérò pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, mo sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí àwọn ìwà kan kò fi dára. Mo tún máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n sọ tinú wọn kí n tó bá wọn wí, kí n lè mọ ohun tó fà á tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Tó bá jẹ́ pé èmi ni mi ò lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ dáadáa, mo máa ń tọrọ àforíjì.
Báwo lo ṣe kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíì?
Mo máa ń rán wọn létí ohun tí Jésù kọ́ wa, pé ohun tá a bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe fún wa ni ká máa ṣe fún wọn. (Lúùkù 6:31) Mo máa ń sọ fún wọn pé bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wọn, kí wọ́n gbìyànjú láti yanjú rẹ̀ fúnra wọn, mo sì kọ́ wọn pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa fi ohùn jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù nígbà tí inú bá ń bí wọn.
Báwo lẹ ṣe máa ń fún ara ní ìsinmi?
Gbogbo ìgbà kọ́ la máa ń lè rin ìrìn àjò fún ìsinmi, torí náà a máa ń wo inú àwọn ìwé ìròyìn láti rí àwọn nǹkan tá a lè ṣe tí kò ní fi bẹ́ẹ̀ ná wa lówó. A máa ń jáde lọ ṣe fàájì tàbí ká lọ rìn yíká ọgbà tí wọ́n ti ń tọ́jú òdòdó. A gbin àwọn irúgbìn tó máa ń mú kí oúnjẹ ta sánsán sínú ọgbà wa, a sì máa ń fi dá ara wa lára yá nígbà tá a bá fẹ́ yan èyí tá a máa fi se oúnjẹ. Eré ìtura náà ṣe pàtàkì, kódà kó jẹ́ ọgbà ìtura tó wà nítòsí la máa lọ.
Kí ló ń fún ẹ láyọ̀, èrè wo lo sì ti rí gbà?
Kò rọrùn láti máa gbé nínú ilé tó jẹ́ pé òbí kan ló ń dá gbogbo rẹ̀ ṣe, àmọ́ a ti sún mọ́ ara wa gan-an, a sì ti kọ́ láti mọrírì àwọn ohun rere tí Ọlọrun ti ṣe fún wa. Inú mi máa ń dùn láti rí bí ọmọ kọ̀ọ̀kàn ṣe ń dàgbà tó sì ń ní ìwà tó dáa. Níbi tí wọ́n dàgbà dé yìí, wọ́n máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú mi, mó sì máa ń mọyì rẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ mi. Wọ́n máa ń mọ̀ bí inú mi bá dùn tàbí tí inú mi kò bá dùn, nígbà míì wọ́n á sì gbá mi mọ́ra láti fi mí lọ́kàn balẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sí mi máa ń múnú mi dùn gan-an. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a rọ́wọ́ ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá wa lára wa, ó ti ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò ìṣòro tó le gan-an. Bíbélì máa ń fún mi lókun láti máa ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí òbí rere.—Aísáyà 41:13.
[Àwòrán]
Lucinda àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì, Brie àti Shae