ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/11 ojú ìwé 10-12
  • Bó O Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Láti Ìgbà Ọmọdé Títí Dìgbà Ìbàlágà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Láti Ìgbà Ọmọdé Títí Dìgbà Ìbàlágà
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Fífetí Sílẹ̀
  • Ẹ “Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà Lẹ́nì Kìíní-Kejì”
  • Fi Hàn Pé O Mọ Ọpẹ́ Dá
  • “Má Fawọ́ Ìbáwí Sẹ́yìn”
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfòyebánilò Yín Di Mímọ̀”
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 10/11 ojú ìwé 10-12

Bó O Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Láti Ìgbà Ọmọdé Títí Dìgbà Ìbàlágà

“Títí dìgbà tí ọmọ á fi pé ọmọ ọdún márùn-ún, àárín ìdílé tí kò ti séwu fún wọn ni wọ́n wà, ó sì rọrùn láti fi ìwà rere kọ́ wọn. Àmọ́, bí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ iléèwé, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í rí onírúurú ọ̀nà láti gbà ṣe nǹkan àti onírúurú ọ̀nà láti sọ̀rọ̀.”—Valter, Ítálì.

BÍ ÀWỌN ọmọ ṣe ń dàgbà, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú onírúurú èèyàn. Wọ́n á máa bá àwọn èèyàn tó pọ̀ sí i sọ̀rọ̀, irú bí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣeré, àwọn ọmọléèwé wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí. Bí Valter tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè ṣe sọ, kì í ṣe ìwọ nìkan lò ń ní ipa lórí ìgbésí ayé ọmọ rẹ mọ́, bíi ti ìgbà tó ṣì wà ní ọmọ ọwọ́. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kó o lo àkókò tí ọmọ rẹ ṣì jẹ́ ìkókó láti jẹ́ kó mọ ìdí tó fi yẹ kó jẹ́ onígbọràn ọmọ, kó o sì kọ́ ọ ní ìwà ọmọlúwàbí. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o fún un ní ìtọ́sọ́nà nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.

Kì í ṣe ohun tó rọrùn láti tọ́ ọmọ ìkókó bá a ṣe sọ lókè yìí o, wọn kì í sì í bí i mọ́ni. Torí pé, o máa ní láti “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Tímótì 4:2) Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ òbí pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe fi hàn, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa bá a nìṣó láti máa fún àwọn ọmọ rẹ ní ìtọ́ni.

Ojúṣe àwọn òbí láti tọ́ àwọn ọmọ wọn máa ń mú àwọn ìpèníjà kan lọ́wọ́. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.

Ìgbà Fífetí Sílẹ̀

Bíbélì sọ pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà, ìgbà fífetí sílẹ̀ náà sì wà. (Oníwàásù 3:7) Báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti máa fetí sílẹ̀ nígbà tí ìwọ tàbí àwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀? Ọ̀nà kan ni pé kó o fi àpẹẹrẹ rẹ kọ́ wọn. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀, tó fi mọ́ àwọn ọmọ rẹ?

Ọkàn àwọn ọmọ máa ń tètè kúrò nínú ohun téèyàn ń bá wọn sọ, torí náà àfi kó o ní sùúrù gan-an tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ yàtọ̀ síra, torí náà ó yẹ kó o ní àkíyèsí, kó o mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa gbà bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, bàbá kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David, sọ pé: “Mo máa ń ní kí ọmọbìnrin mi tún ohun tí mo sọ fún un sọ lọ́rọ̀ ara rẹ̀. Èyí ti jẹ́ kó túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ bó ṣe ń dàgbà.”

Nígbà tí Jésù ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Bí àwọn àgbàlagbà bá ní láti fiyè sí bí wọ́n ṣe ń fetí sílẹ̀, ṣé kò wá yẹ kí àwọn ọmọdé náà máa ṣe bẹ́ẹ̀?

Ẹ “Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà Lẹ́nì Kìíní-Kejì”

Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kólósè 3:13) A lè kọ́ àwọn ọmọdé láti dẹni tó máa ń dárí ji àwọn ẹlòmíì. Báwo la ṣe lè ṣe é?

Bá a ṣe sọ lókè nípa béèyàn ṣe lè máa fetí sílẹ̀, o ní láti fi àpẹẹrẹ rẹ kọ́ wọn. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé ìwọ náà máa ń dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ọ́. Màmá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marina lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, sapá láti ṣe ohun tá a sọ yìí. Ó ní: “A sapá láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa láti máa dárí ji àwọn ẹlòmíì, kí wọ́n ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò, kí wọ́n má sì ṣe máa bínú. Bí mo bá sì ṣẹ àwọn ọmọ mi, mo máa ń tọrọ àforíjì. Mo fẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣe ohun kan náà nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ẹlòmíì da nǹkan pọ̀.”

Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n dàgbà di ẹni tó mọ béèyàn ṣe ń yanjú aáwọ̀, kí wọ́n sì máa dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wọ́n. Ní báyìí tí àwọn ọmọ rẹ ṣì kéré ni kó o ti kọ́ wọn láti máa gba tàwọn èèyàn rò, kí wọ́n sì gbà pé àwọn jẹ̀bi nígbà tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye lò ń fún wọn yẹn, ó sì máa wúlò fún wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Fi Hàn Pé O Mọ Ọpẹ́ Dá

Ní “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tímótì 3:1, 2) Ní báyìí tí àwọn ọmọ rẹ ṣì kéré, àkókò nìyí fún ẹ láti kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa dúpẹ́ oore. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.”—Kólósè 3:15.

Kódà nígbà tí àwọn ọmọ ṣì kéré, a lè kọ́ wọn láti máa hùwà ọmọlúwàbí, kí wọ́n sì máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwọn. Báwo la ṣe lè ṣe é? Dókítà Kyle Pruett sọ nínú ìwé ìròyìn Parents, pé: “Ọ̀nà tó dáa jù lọ tó o lè gbà jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ dẹni tó mọ ọpẹ́ dá ni pé, kẹ́ ẹ máa dúpẹ́ dáadáa nínú ilé yín. Èyí túmọ̀ sí pé kó o máa sọ bó o ṣe mọrírì oore tẹ́nìkan ṣe fún ẹ tàbí ìwà ìgbatẹnirò míì tí wọ́n hù . . . Èyí sì gba pé kéèyàn máa ṣe é léraléra.”

Bàbá kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Richard sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó bá fi inúure hàn sí wa, irú bí àwọn olùkọ́ tàbí àwọn òbí wa àgbà. Nígbàkigbà tí ìdílé kan bá gbà wá lálejò, a máa ń kọ ìwé pélébé kan láti fi dúpẹ́, gbogbo àwọn ọmọ wa ló sì máa buwọ́ lù ú tàbí kí wọ́n ya àwòrán sínú rẹ̀.” Bí àwọn ọmọ rẹ bá ní ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n sì mọ ọpẹ́ dá, wọ́n á lè ní àjọṣe tó wà pẹ́ títí tó sì ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

“Má Fawọ́ Ìbáwí Sẹ́yìn”

Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n mọ̀ pé kò sí àṣegbé. Kódà nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣì kéré, wọ́n máa gba èrè ìwà wọn lọ́dọ̀ àwọn tó láṣẹ lórí wọn, yálà lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, níléèwé àti ládùúgbò pẹ̀lú. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tí wọ́n bá gbìn ni wọ́n máa ká. (Gálátíà 6:7) Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Bíbélì sọ pé: “Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn.” (Òwe 23:13) Bó o bá ti jẹ́ kó ṣe kedere sí àwọn ọmọ rẹ pé ohun báyìí lo máa ṣe fún wọn bí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa, má ṣe bẹ̀rù láti ṣe ohun tó o sọ. Ìyá kan ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Norma sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì ká dúró lórí ohun tá a bá sọ. Téèyàn ò bá dúró lórí ohun tó sọ, ó máa ń jẹ́ kí ọmọ fẹ́ ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀.”

Ohun kan tí àwọn òbí lè ṣe kó má bàa di pé wọ́n á máa bá àwọn ọmọ wọn rojọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣàìgbọràn ni pé kí wọ́n máa sọ fún wọn ṣáájú, ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn bí wọ́n bá ṣàìgbọràn. Àwọn ọmọ kì í sábà ṣe ohun tí àwọn òbí wọn bá sọ pé àwọn kò fẹ́, bí wọ́n bá ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bí àwọn bá ṣe é, tí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn òbí wọn máa dúró lórí ohun tí wọ́n bá sọ.

Àmọ́ ṣá o, kí ìbáwí lè so èso rere, a kò gbọ́dọ̀ ṣe é pẹ̀lú ìbínú. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) A kò gbọ́dọ̀ bá ọmọ wí nípa híhùwà òǹrorò sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò gbọ́dọ̀ máa ka èébú sí i lára tàbí ká sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i.

Àmọ́, báwo lo ṣe lè kó ara rẹ ní ìjánu nígbà tí ọmọ bá tán ẹ ní sùúrù? Bàbá kan lórílẹ̀-èdè New Zealand tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peter gbà pé “kì í ṣe ohun tó rọrùn, àmọ́ àwọn ọmọ ní láti mọ̀ pé ohun tí kò dáa tí àwọn ṣe ló mú ká bá àwọn wí, kì í ṣe torí pé òbí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu.”

Peter àti ìyàwó rẹ̀ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àǹfààní tó wà pẹ́ títí tó wà nínú gbígba ìbáwí. Ó sọ pé: “Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn ọmọ ṣe ohun kan tó burú gan-an, dípò tí a ó fi bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìwà tí kò dá tí wọ́n hù, irú èèyàn tó yẹ kí wọ́n jẹ́ la máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfòyebánilò Yín Di Mímọ̀”

Ọlọ́run sọ nípa ìtọ́sọ́nà tó máa fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ṣe ni èmi yóò nà ọ́ dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 46:28) Wàá lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ tó o bá fún wọn ní ìbáwí tó tọ́, tó sì ṣe déédéé pẹ̀lú ohun tí kò dáa tí wọ́n ṣe. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.”—Fílípì 4:5.

Ara ọ̀nà tó o lè gbà fúnni ní ìbáwí tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o ṣe é lọ́nà tí o kò fi ní dójú ti àwọn ọmọ rẹ. Bàbá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Santi, lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Mi ò kì í fojú kéré àwọn ọmọ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fa ìṣòro gan-an ni mo máa ń gbìyànjú láti mọ̀, ìyẹn sì ni màá bójú tó. Mi ò kì í bá àwọn ọmọ mi wí lójú àwọn ẹlòmíì, kódà tó bá ṣeé ṣe, mi ò kì í bá wọn wí lójú àwọn ọmọ mi tó kù. Bákan náà, mi ò kì í fi àṣìṣe wọn dápàárá ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀.”

Richard tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan rí i pé ó mọ́gbọ́n dání kéèyàn máa fòye hùwà. Ó sọ pé: “Kó dáa kéèyàn máa bá ọmọ dé ẹ̀ṣẹ̀ pa mọ́, kó o wá sún ìbáwí di ìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá ti pọ̀ gan-an. Lẹ́yìn tó o bá ti bá ọmọ wí, kò dáa kéèyàn tún máa rán an mẹ́nu, kó o sì máa sọ fún ọmọ pé bó o ṣe ṣe nígbà báyìí náà nìyẹn.”

Iṣẹ́ àṣekára tó gba kéèyàn múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan ni ọmọ títọ́, ṣùgbọ́n èrè wà níbẹ̀. Ìyá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yelena lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ tó máa fún mi láyè láti máa lo àkókò tó pọ̀ sí i pẹ̀lú ọmọkùnrin mi ni mo yàn láti máa ṣe. Ó gba ìsapá, owó tó ń wọlé fún mi kò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, àmọ́ ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé ó ń mú inú ọmọ mi dùn gan-an ni, ó sì jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

A lè kọ́ àwọn ọmọ láti máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bá àwọn ọmọ wí lọ́nà tí o kò fi ní dójú tì wọ́n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́