ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 31
  • Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Àti Ọ̀wọ̀ Hàn Fún Ara Yín Nípa Kíkó Ahọ́n Yín Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Ló Dé Tó Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Dáa Ló Máa Ń Jáde Lẹ́nu Mi Ṣáá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Bá A Ṣe Lè Máa Sọ̀rọ̀ Tó Mọ́gbọ́n Dání
    Jí!—2011
  • Ìgbàgbọ́ Ń sún Wa Ṣiṣẹ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 31
Ẹyẹ akùnyùnmù kan ń yọ ahọ́n ẹ̀ jáde kó lè lá omi inú òdòdó kan.

Moment/Robert D. Barnes via Getty Images

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù

Ìgbà kan wà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ronú pé ẹyẹ akùnyùnmù máa ń fi ahọ́n ẹ̀ fa omi dídùn tó wà nínú òdòdó bí ìgbà téèyàn ń fẹnu fa omi. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣèwádìí sí i, wọ́n rí i pé ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pátápátá ni ẹyẹ náà máa ń gbà lá omi tó wà nínú òdòdó.

Rò ó wò ná: Tí ẹyẹ akùnyùnmù bá fẹ́ mu omi tó wà nínú òdòdó, ṣe ni ahọ́n ẹ̀ máa là sí méjì. Ohun kan wà lára ahọ́n yìí tó sábà máa ń wà ní pípadé, àmọ́ tó bá ti ki ahọ́n ẹ̀ bọ inú omi dídùn, ṣe ni ohun náà máa ṣí, táá sì gba omi dídùn náà sára bí ìgbà tá a bá ki fóòmù bọ omi tó sì gba omi náà sára. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ kí ẹyẹ yìí máa lá omi dídùn náà dípò kó máa fà á fúnra ẹ̀. Tó bá wá yọ ahọ́n nínú omi dídùn náà, ṣe ni ahọ́n ẹ̀ máa padé pa dà, gbogbo omi dídùn tí ahọ́n náà ti gbà sára sì máa lọ sẹ́nu ẹ̀.

Àwòrán: Ẹyẹ akùnyùnmù kan ń la omi inú òdòdó. Àwòrán tó wà ní inú: 1. Ahọ́n ẹyẹ náà ń wọ inú omi dídùn. 2. Ahọ́n ẹ̀ ń gba omi dídùn náà sára, á sì gbé e lọ sẹ́nu ẹ̀.

Alejandro Rico-Guevara, Tai-Hsi Fan àti Margaret Rubega tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àkókò tí ẹyẹ yìí fi ń la omi dídùn náà kéré “kódà kéèyàn tó ṣẹ́jú, ó ti lá a tán.” Wọ́n tún sọ pé: ‘Orí ahọ́n ẹyẹ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an torí pé ṣe ló máa ń yíra pa dà bó ṣe ń ki ahọ́n bọ omi dídùn tó sì ń yọ ọ́.’

Yàtọ̀ síyẹn, ẹyẹ náà kì í lo agbára rárá tó bá fẹ́ la omi yìí. Ṣe ni orí ahọ́n ẹ̀ máa ń ṣí tó sì máa ń padé fúnra ẹ̀ tó bá ti kan omi dídùn.

Torí pé ahọ́n ẹyẹ akùnyùnmù ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé táwọn bá lè ṣe àwọn ẹ̀rọ tó ń ṣiṣẹ́ bí ahọ́n ẹyẹ yìí, ó máa ṣèrànwọ́ gan-an tó bá kan ọ̀rọ̀ ìṣègùn àtàwọn nǹkan míì. Kódà, wọ́n lè wò ó láti ṣe àwọn ẹ̀rọ tó lè lá epo rọ̀bì àtàwọn kẹ́míkà míì tó bá dà sínú òkun.

Wo bí ẹyẹ akùnyùnmù ṣe ń yọ ahọ́n ẹ̀ jáde

Kí lèrò ẹ? Ṣé ahọ́n ẹyẹ akùnyùnmù yìí kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́