ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Ìfihàn 21:4—“Ọlọ́run Yóò sì Nu Omijé Gbogbo Nù Kúrò ní Ojú Wọn”
“Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:4, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:4, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Ìtumọ̀ Ìfihàn 21:4
Ọlọ́run ṣèlérí pé kì í ṣe ìṣòro tó ń bá aráyé fínra nìkan lòun máa mú kúrò, òun á tún yanjú gbogbo ohun tó ń fa ìṣòro náà.
“Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìlérí tí Jèhófàa gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé òun “máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn” máa ṣẹ. (Àìsáyà 25:8; Ìfihàn 7:17) Ọ̀rọ̀ yìí tún jẹ́ ká rí i pé gbogbo àwọn tó ń sunkún torí pé èèyàn wọn kú tàbí torí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn ni Ọlọ́run ń rí, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lọ́kàn.
“Ikú ò ní sí mọ́.” Gbólóhùn náà tún lè túmọ̀ sí “ikú máa pòórá.” Ọlọ́run sọ pé òun máa mú ikú àti ìrora tí ikú ń fà kúrò. Bákan náà, ó máa jí àwọn tó ti kú dìde. (1 Kọ́ríńtì 15:21, 22) Paríparí ẹ̀, Ọlọ́run máa sọ ikú “di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
“Kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Ti pé Ọlọ́run ṣèlérí pé kò ní sí ìrora mọ́, kò túmọ̀ sí pé a ò ní mọ nǹkan lára mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìrora kan máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ara wa nílò àwọn nǹkan kan tàbí ewu wà nítòsí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlérí yìí jẹ́ ká mọ̀ pè kò ní sí ìrora tí ẹ̀ṣẹ̀b àti àìpé ń fà mọ́, irú bí ẹ̀dùn ọkàn, ìdààmú, ara ríro àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Róòmù 8:21, 22.
“Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ohun tó parí ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìyípadà tó ń mọ́kàn yọ̀ tó máa bá àwa èèyàn. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Ìgbé ayé ọ̀tún máa rọ́pò ìgbé ayé àtijọ́, níbi tí ikú, ọ̀fọ̀, ẹkún àti ìrora ti ń han àwa èèyàn léèmọ̀.” Tó bá dìgbà yẹn, àwa èèyàn máa gbádùn ayé wa títí láé lórí ilẹ̀ ayé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí gẹ́lẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Ìfihàn 21:4
Níbẹ̀rẹ̀ orí 21, àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó rí nínú ìran, ó ní: “Mo rí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.” (Ìfihàn 21:1) Ó lo ọ̀rọ̀ àfiwé láti ṣàlàyé ìyípadà tàwọn ẹsẹ Bíbélì míì náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Àìsáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13) Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn “ọ̀run tuntun,” máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, á sì ṣàkóso lórí “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tó máa gbé láyé.—Àìsáyà 65:21-23.
Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ayé ni ìran tí Jòhánù rí yìí ti máa ṣẹ? Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìlérí Ọlọ́run yìí ni: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé.” (Ìfihàn 21:3) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé àwa èèyàn tó wà láyé ni Ọlọ́run ṣe ìlérí yìí fún kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run. Ìkejì, ìran náà sọ pé “ikú ò ní sí mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Àwa tá a wà láyé la máa ń kú, kì í ṣe àwọn tó wà lọ́run. (Róòmù 5:14) Torí náà ó bọ́gbọ́n mu tá a bá gbà pé àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ láyé ni ìran yẹn sọ nípa ẹ̀.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta ni Jèhófà?”
b Nínú Bíbélì ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkóhun tó ta ko ìlànà Ọlọ́run, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀, èrò tàbí ìṣe. (1 Jòhánù 3:4) Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?”