BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Àwọn Ohun Tó Ń Ṣe Àwọn Ará Wa Láǹfààní Tí Ò sì Ba Àyíká Jẹ́
APRIL 1, 2025
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé láìpẹ́ Jèhófà máa dá sọ́rọ̀ ayé yìí, á sì ṣàtúnṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn ti bà jẹ́. (Ìfihàn 11:18) Síbẹ̀, a máa ń gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tí ò ní ba àyíká jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn lọ́nà tí ò ní ba àyíká jẹ́.
Onírúurú nǹkan la máa ń ṣe tá a bá ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò kó má bàa ba àyíká jẹ́. Èwo la ti ṣe? Báwo sì lohun tá à ń ṣe yìí ṣe ń jẹ́ ká ṣọ́wó ná?
Ọgbọ́n Tá A Dá Sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ Kan Tó Máa Ń Móoru
Nígbà tí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ Matola tó wà ní Mòsáńbíìkì gbayawu ló wà, wọ́n sì fi páànù bò ó. Páànù yìí máa ń jẹ́ kí abẹ́ gbọ̀ngàn náà móoru gan-an. Arákùnrin kan tiẹ̀ sọ pé: “Ṣe la máa ń làágùn yọ̀bọ̀ tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́! Bí ìpàdé bá ṣe ń parí báyìí ni gbogbo wa máa ń sá jáde, ká lè gba atẹ́gùn kára sì tù wá.” Kí la wá ṣe sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ yẹn kí ara lè tu àwọn ará wa, kí wọ́n sì túbọ̀ máa gbádùn àwọn àpéjọ wa?
Ohun tá a ṣe ni pé, a ṣe àwọn fáànù kan síbẹ̀ tó jẹ́ pé atẹ́gùn ni wọ́n ń lò wọn kì í lo iná, a sì tẹ́ nǹkan kan sábẹ́ òrùlé gbọ̀ngàn náà. Ohun tá a tẹ́ síbẹ̀ yìí kì í jẹ́ kí ooru mú nígbà tí oòrùn bá yọ lọ́sàn-án gangan. Àwọn fáànù náà sì máa ń jẹ́ kí atẹ́gùn máa fẹ́ sáwọn tó wà lábẹ́ gbọ̀ngàn náà. Ohun míì táwọn fáànù yìí tún máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń fa ooru tó bá wà lábẹ́ gbọ̀ngàn náà sí ìta. Àwọn fáànù yìí ò sì wọ́n, nǹkan bí àádọ́ta (50) dọ́là la ra ìkọ̀ọ̀kan wọn.a
Àwọn fáànù ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Matola
Ohun tá a ṣe yìí máa ń jẹ́ kí atẹ́gùn tó dáa fẹ́ sáwọn tó wà lábẹ́ gbọ̀ngàn náà. Torí ooru kì í pọ̀ níbẹ̀ mọ́, èbíbu kì í fi bẹ́ẹ̀ yọ mọ́ lára Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Bákan náà, bí atẹ́gùn ṣe ń wọlé tó sì ń jáde ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ oxygen tó pọ̀ tó wà fáwọn tó wà níbẹ̀. Torí náà, ara máa ń tu àwọn ará, ó sì máa ń rọrùn fún wọn láti máa fọkàn bá àsọyé lọ. Arákùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ní báyìí, a kì í sáré jáde nígbà tí àpéjọ bá parí. Kódà, abẹ́ gbọ̀ngàn náà la ti máa ń jẹun ọ̀sán tá a sì máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀. Tá a bá jókòó sábẹ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà, ṣe ló máa ń dà bíi pé a jókòó sábẹ́ igi kan tó tutù!”
Àwọn ará túbọ̀ ń gbádùn àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè báyìí
Iná Tó Ń Lo Agbára Oòrùn
A ti ṣe iná Solar sí ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà kárí ayé. Oòrùn ni iná Solar yìí ń lò, agbára oòrùn ò sì lè tán, ìyẹn ti jẹ́ ká dín epo tá à ń lò kù. Àwọn iná Solar yìí kì í tú èéfín olóró jáde bíi ti jẹnẹrátọ̀, ó sì tún ń jẹ́ ká lè máa ṣọ́wó ná.
Lọ́dún 2022, a ṣe iná Solar sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Slovenia. Ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá iná tí wọ́n ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí ló jẹ́ pé orí Solar yìí ló wà. Nígbàkigbà tí iná tí Solar yìí ń gbé jáde bá pọ̀ ju iná tí ẹ̀ka ọ́fíìsì nílò, a máa darí èyí tó ṣẹ́kù sọ́dọ̀ àwọn aráàlú kí wọ́n lè lò ó. 360,000 dọ́là ló ná wa láti parí Solar yìí. Àmọ́ torí pé owó tá à ń san fún iná ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti dín kù gan-an, a máa rí owó yìí pa dà láàárín ọdún mẹ́rin.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Slovenia
Lọ́dún 2024, a ṣe iná Solar sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Sri Lanka. Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là ló ná wa láti parí iṣẹ́ yìí. Solar yìí ló ń gbé èyí tó pọ̀ jù nínú iná tá à ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn. Torí pé iye tí àá máa ná sórí iná ti dín kù, a máa rí owó yìí pa dà láàárín ọdún mẹ́ta. Lọ́dún yẹn kan náà, a ṣe iná Solar sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Netherlands. Mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún dọ́là ló sì ná wa láti ṣe é. Solar yìí ló ń gbé ìdajì nínú iná tá à ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn. Torí pé iye tá à ń san fún owó iná níbẹ̀ náà ti dín kù, a máa rí owó tá a fi ṣe Solar yìí pa dà láàárín ọdún mẹ́sàn-án (9).
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Netherlands
A tún ṣe iná Solar sí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè mélòó kan ní Mẹ́síkò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Tarahumara (Central) tó wà ní Chihuahua. Tó bá di àsìkò òtútù, òtútù máa ń mú gan-an lágbègbè yẹn. Tó bá sì tún dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ooru máa ń mú gan-an níbẹ̀. Àmọ́ torí pé owó iná tí wọ́n ń san níbẹ̀ pọ̀ gan-an, àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè yìí kì í lo ẹ̀rọ amúlétutù nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, wọn kì í ṣì í lo ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru lásìkò òtútù. Arákùnrin Jonathan tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sọ pé: “A máa ń lo aṣọ ìbora tó nípọn lásìkò òtútù, a sì máa ń ṣí wíńdò kalẹ̀ kí atẹ́gùn lè wọlé tó bá dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.”
Lọ́dún 2024, a ṣe Solar sí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè yìí. 21,480 owó dọ́là ló sì ná wa láti ṣe é. Torí iye tá a máa san fún owó iná ti dín kù, a máa rí owó yìí pa dà láàárín ọdún márùn-ún. Ní báyìí, àwọn ará wa lè lo ẹ̀rọ amúlétutù àti èyí tó ń mú kí ilé móoru lásìkò tí wọ́n bá fẹ́. Jonathan wá sọ pé: “Ara tù wá báyìí, a sì ń gbádùn iṣẹ́ wa. Inú wa tún dùn pé ètò Ọlọ́run ń lo owó tá a fi ń ṣètorẹ lọ́nà tó dáa tó sì ṣe àwọn míì láǹfààní.”
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Tarahumara (Central) túbọ̀ ń gbádùn iṣẹ́ wọn báyìí
À Ń Fọgbọ́n Lo Omi Òjò
Nílẹ̀ Áfíríkà, kò sómi láwọn Ilé Ìpàdé wa kan. Káwọn ará lè rómi lò ní Ilé Ìpàdé, ṣe ni wọ́n á lọ pọnmi wá láti ibi tó jìnnà gan-an. Láwọn Ilé Ìpàdé míì, àwọn ará máa ń ra omi lọ́wọ́ àwọn tó ń fi mọ́tò já omi. Àmọ́ owó gegere ni wọ́n máa ń ra omi yìí, omi náà sì lè má dáa.
Káwọn ará wa lè rí omi lò láwọn Ilé Ìpàdé wa ní Áfíríkà, a ṣe àwọn páìpù tí wọ́n fi ń gbe omi òjò síbi òrùlé, a sì ra àwọn táǹkì ńlá tí wọ́n lè fi tọ́jú omi òjò náà pa mọ́. Àwọn ará máa kọ́kọ́ wo bí ojú ọjọ́ ṣe rí ládùúgbò kan kí wọ́n lè mọ irú páìpù tó ń gbe omi òjò tí wọ́n lè lò ní Ilé Ìpàdé tó wà lágbègbè yẹn. Ó máa ń ná wa ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta owó dọ́là tá a bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan yìí sí Ilé Ìpàdé kan. Àmọ́ ètò tá a ṣe yìí ti mú kí owó táwọn ará ń ná láti bójú tó àwọn Ilé Ìpàdé dín kù torí pé wọn kì í ra omi mọ́.
Táǹkì omi ní Ilé Ìpàdé kan ní South Africa
Ètò yìí ti ṣe àwọn ará wa láǹfààní gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Noemia tó ń gbé ní Mòsáńbíìkì sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ibi tá a ti máa lọ ń pọnmi wá jìnnà gan-an. Tá a bá fi máa gbé omi ọ̀hún dé Ilé Ìpàdé, á ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sómi, ó máa ń ṣòro fún wa láti fọwọ́. Àmọ́ ní báyìí, gbogbo wa la lè fọ ọwọ́ wa. Bákan náà, tá a bá lọ sípàdé, a máa ń gbádùn ìpàdé torí pé kì í rẹ̀ wá bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ yín!”
Arábìnrin kan àti ọmọ ẹ̀ ní South Africa ń lo omi tá a ṣètò
Báwo la ṣe ń rí owó tá a fi ń bójú tó àwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí? Owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé la fi ń ṣe é. Ọ̀pọ̀ ẹ̀ ló sì jẹ́ pé àtorí ìkànnì donate.jw.org lẹ ti ń ṣe é. Ẹ ṣeun ẹ kú ànawọ́sí o!
a Gbogbo dọ́là tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ dọ́là ti Amẹ́ríkà.