Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
e Ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì William Thomson, tí wọ́n tún ń pè ní Lord Kelvin, ṣàwárí òfin kejì nípa agbára ooru, èyí tó ṣàlàyé ìdí tí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run fi máa ń bà jẹ́ bí àkókò ti ń lọ. Ohun tó mú kó ní èrò yìí ni pé ó fara balẹ̀ ka ohun tó wà ní Sáàmù 102:25-27.