ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Wednesday, August 27

Mo rí òfin míì nínú ara mi tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara mi.—Róòmù 7:23.

Inú ẹ lè má dùn torí pé nígbà míì nǹkan tí ò dáa máa ń wá sí ẹ lọ́kàn. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ìlérí tó o ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, wàá lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. Lọ́nà wo? Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo sẹ́ ara ẹ. Ìyẹn ni pé o ti kọ gbogbo ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí àtàwọn nǹkan tí ò dáa tó lè máa wù ẹ́. (Mát. 16:24) Torí náà, tí ìdẹwò bá dé, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nǹkan tó o máa ṣe. Ìdí ni pé o ti mọ ohun tó o máa ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ni pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìpinnu ẹ ni pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5. w24.03 9 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, August 28

Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.

Jèhófà “Ọlọ́run ìfẹ́” wà pẹ̀lú wa! (2 Kọ́r. 13:11) Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí wa ká.’ (Sm. 32:10) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó ń bójú tó wa, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ fún un pé kó túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí wa. A lè sọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún un, kó sì dá wa lójú pé ó mọ ohun tá a fẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 145:19) Bó ṣe máa ń wù wá pé ká yáná nígbà tí òtútù bá mú wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá kí Jèhófà fìfẹ́ hàn sí wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lágbára gan-an, ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni. Jẹ́ kínú ẹ máa dùn torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbà kí Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí wa, ká sì máa sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà”!—Sm. 116:1. w24.01 31 ¶19-20

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, August 29

Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.—Jòh. 17:26.

Jésù ò kàn sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run torí pé àwọn Júù tí Jésù ń kọ́ ti mọ orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Jésù ni “ẹni tó ṣàlàyé” ẹni tí Jèhófà jẹ́ lọ́nà tó dáa jù. (Jòh. 1:​17, 18) Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń gba tẹni rò. (Ẹ́kís. 34:​5-7) Jésù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé wa dáadáa nígbà tó sọ àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá àti bàbá ẹ̀. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì ń gba tẹni rò. Nígbà tí bàbá yìí rí ọmọ ẹ̀ tó ti ronú pìwà dà tó “ń bọ̀ ní òkèèrè,” ó sáré lọ pàdé ẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì dárí jì í tọkàntọkàn. (Lúùkù 15:​11-32) Torí náà, Jésù ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. w24.02 10 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́