ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Thursday, August 28

Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.

Jèhófà “Ọlọ́run ìfẹ́” wà pẹ̀lú wa! (2 Kọ́r. 13:11) Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí wa ká.’ (Sm. 32:10) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó ń bójú tó wa, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ fún un pé kó túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí wa. A lè sọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún un, kó sì dá wa lójú pé ó mọ ohun tá a fẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 145:19) Bó ṣe máa ń wù wá pé ká yáná nígbà tí òtútù bá mú wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá kí Jèhófà fìfẹ́ hàn sí wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lágbára gan-an, ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni. Jẹ́ kínú ẹ máa dùn torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbà kí Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí wa, ká sì máa sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà”!—Sm. 116:1. w24.01 31 ¶19-20

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, August 29

Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.—Jòh. 17:26.

Jésù ò kàn sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run torí pé àwọn Júù tí Jésù ń kọ́ ti mọ orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Jésù ni “ẹni tó ṣàlàyé” ẹni tí Jèhófà jẹ́ lọ́nà tó dáa jù. (Jòh. 1:​17, 18) Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń gba tẹni rò. (Ẹ́kís. 34:​5-7) Jésù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé wa dáadáa nígbà tó sọ àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá àti bàbá ẹ̀. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì ń gba tẹni rò. Nígbà tí bàbá yìí rí ọmọ ẹ̀ tó ti ronú pìwà dà tó “ń bọ̀ ní òkèèrè,” ó sáré lọ pàdé ẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì dárí jì í tọkàntọkàn. (Lúùkù 15:​11-32) Torí náà, Jésù ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. w24.02 10 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Saturday, August 30

Fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú.—2 Kọ́r. 1:4.

Jèhófà máa ń tu àwọn tó níṣòro nínú, kára lè tù wọ́n. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà bó ṣe ń ṣàánú àwọn èèyàn, tó sì ń tù wọ́n nínú? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká láwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká máa tu àwọn èèyàn nínú. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ náà? Kí lá jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ká sì ‘máa tu ara wa nínú’ lójoojúmọ́? (1 Tẹs. 4:18) Ohun táá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa bára wa kẹ́dùn, ká ní ìfẹ́ ará àti inú rere. (Kól. 3:12; 1 Pét. 3:8) Báwo làwọn ànímọ́ yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Tá a bá lójú àánú, tá a sì tún láwọn ànímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí, kò sí bá ò ṣe ní máa tu àwọn tó níṣòro nínú. Jésù sọ pé “ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ. Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀.” (Mát. 12:​34, 35) Torí náà, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká máa tù wọ́n nínú. w23.11 10 ¶10-11

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́