Monday, September 1
Ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga.—Lúùkù 1:78.
Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti yanjú ìṣòro aráyé. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe fi hàn pé ó lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tá ò lè yanjú fúnra wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lágbára láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún àtàwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fà irú bí àìsàn àti ikú. (Mát. 9:1-6; Róòmù 5:12, 18, 19) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe fi hàn pé ó lè wo “onírúurú” àìsàn, ó sì lè jí òkú dìde. (Mát. 4:23; Jòh. 11:43, 44) Bákan náà, ó lágbára láti dáwọ́ ìjì líle dúró, ó sì lágbára láti gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀mí burúkú. (Máàkù 4:37-39; Lúùkù 8:2) Àwọn nǹkan yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti fún Ọmọ ẹ̀ lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro wa! Ó dá wa lójú háún-háún pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn ohun rere tó ṣèlérí nínú Ìjọba rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. w23.04 3 ¶5-7
Tuesday, September 2
Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 2:10.
Táwọn ará tó wà nínú ìjọ tó o wà bá pọ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti dáhùn. Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ láti nawọ́ kó o lè dáhùn. Múra ìdáhùn tó pọ̀. Tí wọn ò bá pè ẹ́ níbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà, wọ́n ṣì lè pè ẹ́ bẹ́ ẹ ṣe ń bá ẹ̀kọ́ náà lọ. Tó o bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ronú nípa bí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ṣàlàyé àkòrí ẹ̀kọ́ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, o lè múra láti dáhùn àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ tó lè nira fáwọn ará láti ṣàlàyé. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tó máa nawọ́ láti dáhùn apá yìí kì í pọ̀. Ká sọ pé o ṣì rí i pé wọn kì í pè ẹ́ ńkọ́? Lọ bá ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, kó o sì sọ ìpínrọ̀ tó o fẹ́ dáhùn fún un. w23.04 21-22 ¶9-10
Wednesday, September 3
Jósẹ́fù . . . ṣe ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà ní kó ṣe, ó mú ìyàwó rẹ̀ lọ sílé.—Mát. 1:24.
Ìgbà gbogbo ni Jósẹ́fù máa ń fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò, ìyẹn ló sì mú kó jẹ́ ọkọ rere. Ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ ohun tó máa ṣe nípa ìdílé ẹ̀ fún un. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì máa ń gbé ìgbésẹ̀ kódà nígbà tó ní láti ṣe àwọn àyípadà tó le gan-an. (Mát. 1:20; 2:13-15, 19-21) Torí pé Jósẹ́fù ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ó dáàbò bo Màríà, ó ràn án lọ́wọ́, ó sì pèsè àwọn nǹkan tó nílò. Ẹ wo bí àwọn nǹkan tí Jósẹ́fù ṣe yẹn ṣe máa mú kí Màríà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kó sì bọ̀wọ̀ fún un! Ẹ̀yin ọkọ, ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù tẹ́ ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó ìdílé yín. Tó o bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, tó bá tiẹ̀ máa gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà kan, wàá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ, okùn ìfẹ́ yín á sì máa lágbára sí i. Arábìnrin kan láti Vanuatu tó ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé lógún (20) ọdún sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí ọkọ mi bá ní kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, tó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ ni mo túbọ̀ máa ń bọ̀wọ̀ fún un. Ọkàn mi máa ń balẹ̀, mo sì máa ń fọkàn tán an pé ìpinnu tó dáa ló máa ṣe.” w23.05 21 ¶5