ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀sẹ̀ Yìí
August 11-17
Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—2025 | July

AUGUST 11-17

ÒWE 26

Orin 88 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Bá “Òmùgọ̀” Da Nǹkan Pọ̀

(10 min.)

Ògo kò yẹ “òmùgọ̀” (Owe 26:1; it-2 729 ¶6)

Lọ́pọ̀ ìgbà “òmùgọ̀” nílò ká fún un níbàáwí tó lágbára (Owe 26:3; w87 10/1 19 ¶12)

“Òmùgọ̀” ò ṣe é fọkàn tán (Owe 26:6; it-2 191 ¶4)


ÌTUMỌ̀: Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “òmùgọ̀,” ṣe ló ń tọ́ka sí ẹni tó ń kọ ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ tí kì í sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà lórí ohun tó tọ́.

Nílé ìwé, ọ̀dọ́kùnrin kan fìgboyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń wo nǹkan kan lórí fóònù wọn.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 26:4—Kí la rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w23.09 19 ¶18)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 26:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Máa bá ìjíròrò ẹ lọ nínú ìwé ìléwọ́ tó o fún un nígbà tó o kọ́kọ́ pàdé ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè wàásù fún mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan. (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 5)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 94

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Máa Jẹ́ Kó O Di “Ọlọ́gbọ́n Kí O Lè Rí Ìgbàlà”

(15 min.) Ìjíròrò.

Àwòrán: 1. Arábìnrin kan ń kẹ́kọ̀ọ́ nílé. Ó ń wo fídíò èdè àwọn adití lórí ìkànnì jw.org lórí kọ̀ǹpútà ẹ̀. 2. Arákùnrin kan ń fi fóònù ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó wà lákòókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. 3. Arábìnrin àgbàlagbà kan ń lo “JW Library” lórí fóònù ẹ̀. 4. Ìyá kan àti ọmọkùnrin ẹ̀ ń lo “JW Library” lórí fóònù nípàdé.

Láti kékeré jòjòló ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì jẹ́ kó rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́. Àwọn ohun tí Tímótì kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ ló jẹ́ kó di ‘ọlọ́gbọ́n kí ó lè rí ìgbàlà.’ (2Ti 3:15) Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwa Kristẹni máa wáyè ka Bíbélì, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ torí pé òtítọ́ tó wà nínú ẹ̀ ṣeyebíye gan-an. Àmọ́, kí la lè ṣe tá ò bá kí ń gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́?

Ka 1 Pétérù 2:2. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  • Kí la lè ṣe kó lè ‘máa wù wá gan-an’ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—w18.03 29 ¶6

  • Báwo ni àwọn irinṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run pèsè bíi JW Library ṣe lè mú ká túbọ̀ ní òye tó pọ̀ sí i tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe—Àwọn Ohun Tá A Lè Ṣe Lórí JW Library. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn àǹfààní wo lo ti rí bó o ṣe ń lo JW Library®?

  • Àwọn apá wo lo fẹ́ràn láti máa lò níbẹ̀?

  • Àwọn apá wo ló wù ẹ́ kó o mọ̀ ọ́n lò?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 8-9

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 89 àti Àdúrà

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025 | May

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 23: August 11-17, 2025

26 Ṣé O Gbà Pé Orúkọ Jèhófà Ló Ṣe Pàtàkì Jù?

Àfikún

Àwọn àpilẹ̀kọ míì tó wà nínú ìwé yìí

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́