AUGUST 11-17
ÒWE 26
Orin 88 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Bá “Òmùgọ̀” Da Nǹkan Pọ̀
(10 min.)
Ògo kò yẹ “òmùgọ̀” (Owe 26:1; it-2 729 ¶6)
Lọ́pọ̀ ìgbà “òmùgọ̀” nílò ká fún un níbàáwí tó lágbára (Owe 26:3; w87 10/1 19 ¶12)
“Òmùgọ̀” ò ṣe é fọkàn tán (Owe 26:6; it-2 191 ¶4)
ÌTUMỌ̀: Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “òmùgọ̀,” ṣe ló ń tọ́ka sí ẹni tó ń kọ ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ tí kì í sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà lórí ohun tó tọ́.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 26:4—Kí la rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w23.09 19 ¶18)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 26:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Máa bá ìjíròrò ẹ lọ nínú ìwé ìléwọ́ tó o fún un nígbà tó o kọ́kọ́ pàdé ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè wàásù fún mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan. (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 5)
Orin 94
7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Máa Jẹ́ Kó O Di “Ọlọ́gbọ́n Kí O Lè Rí Ìgbàlà”
(15 min.) Ìjíròrò.
Láti kékeré jòjòló ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì jẹ́ kó rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́. Àwọn ohun tí Tímótì kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ ló jẹ́ kó di ‘ọlọ́gbọ́n kí ó lè rí ìgbàlà.’ (2Ti 3:15) Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwa Kristẹni máa wáyè ka Bíbélì, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ torí pé òtítọ́ tó wà nínú ẹ̀ ṣeyebíye gan-an. Àmọ́, kí la lè ṣe tá ò bá kí ń gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́?
Ka 1 Pétérù 2:2. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Kí la lè ṣe kó lè ‘máa wù wá gan-an’ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—w18.03 29 ¶6
Báwo ni àwọn irinṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run pèsè bíi JW Library ṣe lè mú ká túbọ̀ ní òye tó pọ̀ sí i tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe—Àwọn Ohun Tá A Lè Ṣe Lórí JW Library. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Àwọn àǹfààní wo lo ti rí bó o ṣe ń lo JW Library®?
Àwọn apá wo lo fẹ́ràn láti máa lò níbẹ̀?
Àwọn apá wo ló wù ẹ́ kó o mọ̀ ọ́n lò?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 8-9