AUGUST 18-24
ÒWE 27
Orin 102 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Bí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní
(10 min.)
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ò ní bẹ̀rù láti bá ẹ sòótọ́ ọ̀rọ̀ (Owe 27:5, 6; w19.09 5 ¶12)
Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ lè tètè ràn wá lọ́wọ́ ju àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ torí wọ́n wà nítòsí (Owe 27:10; it-2 491 ¶3)
Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń jẹ́ ká ṣe ohun tó tọ́ (Owe 27:17; w23.09 10 ¶7)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 27:21—Báwo ni ohun tá a bá ṣe nígbà tí wọ́n yìn wá ṣe ń fi irú ẹni tá a jẹ́ hàn? (w06 9/15 19 ¶11)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 27:1-17 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà kì í ṣe Kristẹni. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi fídíò kan látinú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwyp àpilẹ̀kọ 75—Àkòrí: Kí Ni Kí N Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Mi Bá Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí? (th ẹ̀kọ́ 14)
Orin 109
7. “Ọmọ Ìyá Tí A Bí fún Ìgbà Wàhálà”
(15 min.) Ìjíròrò.
Jèhófà ti bù kún wa pẹ̀lú ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé níbi tá a ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Òótọ́ ni pé ara wa lè yọ̀ mọ́ àwọn ará tó wà nínú ìjọ, àmọ́ mélòó nínú wọn ló jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́? Ohun tó máa mú kí okùn ọ̀rẹ́ àwa àtàwọn míì túbọ̀ lágbára ni pé ká sapá láti mọ ara wa dáadáa, ká fọkàn tán ara wa, ká máa sọ tinú wa, ká jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. Èyí jẹ́ ká rí i pé, ó máa gba àkókò àti ìsapá ká tó lè di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn míì.
Ka Òwe 17:17. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ báyìí kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀?
Ka 2 Kọ́ríńtì 6:12, 13. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́?
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ “Ohun Gbogbo Ni Àkókò Wà Fún”—Ó Máa Ń Gba Àkókò Káwa Àtẹnì Kan Tó Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí ni fídíò yìí kọ́ ẹ nípa bó o ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́?
Tó o bá fẹ́ mú ẹnì kan lọ́rẹ̀ẹ́, o lè kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín sí ẹni náà tàbí kó o kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Lẹ́yìn náà, máa ṣe àwọn ohun táá fi hàn pé o fẹ́ràn ẹ̀. Èyí máa gba àkókò torí náà ó yẹ kó o ṣe sùúrù. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àjọṣe yín á lágbára débi pé ẹ lè jẹ́ ọ̀rẹ́ títí láé.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 10-11