AUGUST 25-31
ÒWE 28
Orin 150 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ẹni Burúkú àti Olódodo
(10 min.)
Ẹ̀rù máa ń ba ẹni burúkú àmọ́ olódodo máa ń láyà (Owe 28:1; w93 5/15 26 ¶1)
Ẹni burúkú ò lè ṣèpinnu tó tọ́, àmọ́ olódodo máa ń ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání (Owe 28:5; it-2 1139 ¶3)
Tí ẹni burúkú bá tiẹ̀ lówó, olódodo tó tálákà ṣeyebíye jù ú lọ (Owe 28:6; it-1 1211 ¶4)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 28:14—Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w01 12/1 12 ¶1)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 28:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
Orin 112
8. Ṣé O Kórìíra Ìwà Ipá?
(6 min.) Ìjíròrò.
Ọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù tí Jésù pè ní “apààyàn” ni ìwà ipá ti bẹ̀rẹ̀. (Jo 8:44) Lẹ́yìn táwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀, ìwà ipá wá pọ̀ láyé débi tí Ọlọ́run fi sọ pé ayé ti bà jẹ́. (Jẹ 6:11) Bí ayé tó kún fún ìwà ipá yìí ṣe ń lọ sópin, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ń hùwà tó burú gan-an, tí wọn ò sì lè kó ara wọn níjàánu.—2Ti 3:1, 3.
Ka Sáàmù 11:5. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó fẹ́ràn ìwà ipá, kí sì nìdí?
Kí la kíyè sí nípa ọ̀pọ̀ eré ìdárayá àti eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe lónìí tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn fẹ́ràn ìwà ipá?
Ka Òwe 22:24, 25. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni irú eré ìnàjú tá à ń wò àtàwọn tá à ń bá ṣọ̀rẹ́ ṣe lè mú ká kórìíra tàbí nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá?
Báwo ni eré ìnàjú tá à ń wò ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá?
9. Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù September
(9 min.)
Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ lọ́nà táá jẹ́ kó wu àwọn ará láti kópa nínú àkànṣe ìwàásù náà, kó o sì sọ ètò tí ìjọ ti ṣe.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Àlàáfíà Ayérayé! (Orin Àpéjọ Agbègbè 2022).
10. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 12-13