ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jékọ́bù Rí Ogún Gbà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jékọ́bù fún Ísọ̀ lóúnjẹ, ó sì gba ogún tó tọ́ sí Ísọ̀

      Ẹ̀KỌ́ 12

      Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

      Ísákì àti Rèbékà pẹ̀lú àwọn ìbejì wọn, Jékọ́bù àti Ísọ̀

      Nígbà tí Ísákì pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó fẹ́ Rèbékà. Ísákì nífẹ̀ẹ́ Rèbékà ìyàwó ẹ̀ gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n bí ìbejì, ọkùnrin sì làwọn méjèèjì.

      Orúkọ èyí àkọ́kọ́ ni Ísọ̀, orúkọ èkejì sì ni Jékọ́bù. Ísọ̀ fẹ́ràn kó máa ṣeré jáde, ó sì tún máa ń pa ẹran gan-an. Àmọ́ Jékọ́bù fẹ́ràn kó máa wà nílé.

      Láyé àtijọ́, tí bàbá kan bá kú, àkọ́bí ẹ̀ ọkùnrin ló máa ń gba ohun tó pọ̀ jù lára ohun tí bàbá náà ní. Àwọn nǹkan tí bàbá náà fi sílẹ̀ lẹ́yìn tó kú là ń pè ní ogún. Àwọn ìlérí tí Jèhófà bá Ábúráhámù ṣe wà lára ogún ìdílé Ísákì. Ísọ̀ ò ka àwọn ìlérí yẹn sí pàtàkì, àmọ́ Jékọ́bù mọyì àwọn ìlérí yẹn gan-an.

      Jékọ́bù àti Ísọ̀

      Lọ́jọ́ kan tí Ísọ̀ dé láti ibi tó ti lọ pa ẹran, ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Nígbà tó wọlé, ó gbóòórùn oúnjẹ tí Jékọ́bù ń sè, ó wá sọ fún un pé: ‘Ebi ń pa mí gan-an! Fún mi ní díẹ̀ lára oúnjẹ tó ò ń sè!’ Jékọ́bù dáhùn pé: ‘Màá fún ẹ, àmọ́ kọ́kọ́ ṣèlérí fún mi pé èmi ni màá gba ogún tó yẹ kó o gbà.’ Ísọ̀ wá dáhùn pé: ‘Kí ló kàn mí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ogún! Wò ó, ó ti di tìẹ. Ṣáà fún mi lóúnjẹ.’ Ṣé o rò pé ohun tí Ísọ̀ ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Kò bọ́gbọ́n mu rárá. Ísọ̀ sọ ohun pàtàkì nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré.

      Nígbà tí Ísákì darúgbó, ó rí i pé ó yẹ kóun bù kún àkọ́bí òun. Àmọ́ Rèbékà ìyá wọn ran Jékọ́bù tó jẹ́ àbúrò lọ́wọ́, Jékọ́bù ló sì rí ìbùkún náà gbà. Nígbà tí Ísọ̀ mọ̀ pé Jékọ́bù ti gba ìbùkún tó yẹ kóun gbà, inú bí i gan-an, ó sì pinnu pé òun máa pa ìkejì òun. Ísákì àti Rèbékà ò fẹ́ kí Jékọ́bù kú, torí náà wọ́n sọ fún un pé: ‘Ó yá, wá lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá ẹ títí dìgbà tí inú Ísọ̀ á fi rọ̀.’ Jékọ́bù ṣe ohun táwọn òbí ẹ̀ sọ fún un, ó sì sá kúrò nílé.

      “Àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, tó sì wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Ká sòótọ́, kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?”​—Máàkù 8:36, 37

      Ìbéèrè: Irú ẹni wo ni Ísọ̀ jẹ́? Irú ẹni wo ni Jékọ́bù jẹ́? Kí ló fà á tí Jékọ́bù fi gba ìbùkún tó yẹ kí Ísọ̀ gbà?

      Jẹ́nẹ́sísì 25:20-34; 27:1–28:5; Hébérù 12:16, 17

  • Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jékọ́bù tẹrí ba, Ísọ̀ sì ń sáré bọ̀ wá bá a

      Ẹ̀KỌ́ 13

      Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

      Jèhófà ṣèlérí fún Jékọ́bù pé òun máa dáàbò bò ó bóun ṣe dáàbò bo Ábúráhámù àti Ísákì. Ìlú Háránì ni Jékọ́bù ń gbé, ó fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó ní ọmọ tó pọ̀, ó ní àwọn ìránṣẹ́, ó sì ní nǹkan tó pọ̀ gan-an.

      Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Pa dà sí ìlú rẹ.’ Torí náà, Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò pa dà sílé. Ojú ọ̀nà ni wọ́n wà táwọn èèyàn kan ti wá sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Ísọ̀ ìkejì ẹ ń bọ̀ wá pàdé ẹ, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin ló sì wà pẹ̀lú ẹ̀!’ Ẹ̀rù ba Jékọ́bù, torí ó gbà pé ńṣe ni Ísọ̀ fẹ́ wá bá òun àti ìdílé òun jà. Ó wá gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ ìkejì mi.’ Lọ́jọ́ kejì, Jékọ́bù fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Ísọ̀. Àwọn nǹkan tó fi ránṣẹ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

      Nígbà tí Jékọ́bù dá wà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó rí áńgẹ́lì kan. Òun àti áńgẹ́lì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í jà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì. Jékọ́bù ṣèṣe, síbẹ̀ kò fi áńgẹ́lì náà sílẹ̀. Áńgẹ́lì yẹn wá sọ pé: ‘Fi mi sílẹ̀, jẹ́ kí n máa lọ.’ Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: ‘Mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, àyàfi tó o bá súre fún mi.’

      Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà súre fún Jékọ́bù. Ó wá dá Jékọ́bù lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí Ísọ̀ bá òun jà.

      Nígbà tílẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí Ísọ̀ àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀ ní iwájú. Jékọ́bù fi ìdílé ẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó lọ bá Ísọ̀, ó sì tẹrí ba fún un nígbà méje. Ísọ̀ náà sáré lọ bá Jékọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn. Àwọn méjèèjì bú sẹ́kún, wọ́n sì parí ìjà wọn. Ǹjẹ́ o rò pé inú Jèhófà dùn sí ọ̀nà tí Jékọ́bù gbà yanjú ọ̀rọ̀ yẹn?

      Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ pa dà sílé ẹ̀, Jékọ́bù náà sì pa dà sílé tiẹ̀. Ọmọkùnrin méjìlá (12) ni Jékọ́bù ní. Orúkọ wọn ni Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì, Júdà, Dánì, Náfútálì, Gádì, Áṣérì, Ísákà, Sébúlúnì, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. Jèhófà lo ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin yẹn láti gba àwọn ìbátan ẹ̀ là. Ọmọkùnrin náà ni Jósẹ́fù. Ṣé o mọ bí Jèhófà ṣe lò ó? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

      “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín, kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́.”​—Mátíù 5:44, 45

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún Jékọ́bù? Báwo ni Jékọ́bù àti Ísọ̀ ṣe parí ìjà wọn?

      Jẹ́nẹ́sísì 28:13-15; 31:3, 17, 18; 32:1-29; 33:1-18; 35:23-26

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́