-
Omi Ohun Iyebíye Tó Ń Mú Ká Wà LáàyèJí!—2003 | June 8
-
-
ní ìlú Scottsdale ní Ìpínlẹ̀ Arizona, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ti sọ, “mímu omi tó pọ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti dín sísanra kù. Bí àwọn èèyàn tó fẹ́ dín sísanra kù kì í bá mu omi tó pọ̀ tó, ara ò ní lè lo ọ̀rá bó ṣe yẹ.”
Lóòótọ́, kí omi máa dúró sára ló sábà máa ń fa sísanra jọ̀kọ̀tọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí omi máa ń dúró sára wọn máa ń rò pé dídín omi tí àwọ́n ń mu kù ni ojútùú ìṣòro náà. Àmọ́ èyí kì í ṣòótọ́ rárá. Bí ara kò bá rí omi tó tó, gbogbo omi tó bá ń wọnú ara ló máa fẹ́ gbà dúró nípa fífi wọ́n pa mọ́ sí àwọn ibì kan nínú ara, irú bí ẹsẹ̀ àti ọwọ́. Nítorí náà, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun aṣaralóore dábàá pé ká máa fún ara ní ohun tó nílò—ìyẹn ni omi tó tó. Sì tún rántí o, bí iyọ̀ tó ò ń jẹ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni omi tí ara rẹ á máa gbà dúró láti fi là á ṣe máa pọ̀ tó.
Máa Fún Ara Rẹ Lómi
Lójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ní ìpíndọ́gba, nǹkan bíi lítà omi méjì ló ń jáde lára wa látinú awọ ara, ẹ̀dọ̀fóró, ìfun àti kíndìnrín. Nípa mímí síta nìkan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lítà omi tí à ń pàdánù lójoojúmọ́. Bí a ò bá dá omi yìí padà, ńṣe ni omi ara wa máa gbẹ. Díẹ̀ lára àwọn àmì tó ń fi hàn pé omi ara wa ti gbẹ ni ẹ̀fọ́rí, àárẹ̀ ara, kí ara máa kanni gógó, kí ìtọ̀ ẹni máa pọ́n, àìlè gba ooru mọ́ra, àti kí ẹnu àti ojú gbẹ táútáú.
Nítorí náà, báwo ló ṣe yẹ kí omi tá à ń mu ṣe pọ̀ tó? Dókítà Howard Flaks, tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú béèyàn ṣe lè dènà sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ sọ pé: “Ó kéré tán, ẹni tí ara rẹ̀ le gbọ́dọ̀ máa mu omi tọ́ńbìlà mẹ́jọ sí mẹ́wàá lójúmọ́. Wàá nílò jù bẹ́ẹ̀ lọ bó o bá ń ṣe eré ìmárale gan-an tàbí bó bá jẹ́ ilẹ̀ olóoru lò ń gbé. Àwọn èèyàn tó sì sanra gan-an ní láti máa mu jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Àmọ́, àwọn èèyàn kan ti ń sọ pé mímu omi kìkì nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹni ti tó. Síbẹ̀, nígbà tí òùngbẹ bá fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ ọ́ gan-an, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara rẹ ti gbẹ nìyẹn.
Ṣé èèyàn lè mu àwọn nǹkan dídùn dípò omi? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan olómi ọsàn náà máa ń fún ara lómi, síbẹ̀ wọ́n ṣì ní èròjà kálórì afáralókun nínú. Bákan náà, àwọn nǹkan olómi tí ṣúgà àti mílíìkì pọ̀ nínú wọn máa ń mú kí ara túbọ̀ nílò omi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé omi náà ni wọ́n máa nílò láti mú kí wọ́n dà nínú. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọtí àtàwọn nǹkan mímu bíi kọfí àti tíì máa ń jẹ́ kéèyàn tọ̀ gan-an, tí èyí á sì mú kó pọn dandan láti túbọ̀ mu omi láti dí èyí téèyàn ń tọ̀ jáde. Ó dájú pé kò sí nǹkan tó lè rọ́pò ohun iyebíye tó ń mú ká wà láàyè yìí, ìyẹn omi. Nítorí náà, kí ló dé tó ò lọ mu ife omi kan báyìí?
-
-
Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!Jí!—2003 | June 8
-
-
Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!
“Abúlé kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́lé sí lọ́wọ́ là ń gbé ní orílẹ̀-èdè Belize, igbó púpọ̀ sì yí àrọko náà ká. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, ní nǹkan bí agogo mẹ́sàn-án, ńṣe làwọn ọmọ ogun kan ya bo ilé wa. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìjàlọ bẹ̀rẹ̀ sí gba abẹ́ ilẹ̀kùn àti gbogbo inú ihò tí wọ́n rí wọlé, tí wọ́n ń wá ohun tí wọ́n máa jẹ. Kò sí ohunkóhun tá a lè ṣe ju pé ká fi ilé wa sílẹ̀ fún nǹkan bíi wákàtí kan sí méjì tí àwọn ìjàlọ náà fi kún inú ilé bámúbámú. Nígbà tá a fi máa wọlé padà, wọ́n ti jẹ gbogbo kòkòrò tó wà nínú ilé wa tán pátápátá, àwọn ìjàlọ náà sì ti wábi gbà.”
ÌṢẸ̀LẸ̀ YÌÍ KÌ Í ṢE ohun àjèjì sí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ olóoru, irú bí orílẹ̀-èdè Belize, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bí wọn nínú. Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti palẹ̀ àwọn kòkòrò ayọnilẹ́nu bí aáyán àtàwọn eku mọ́ kúrò nínú ilé. Láfikún sí i, pàǹtírí kankan kì í ṣẹ́ kù sílẹ̀.
Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ńṣe làwọn ìjàlọ tá à ń sọ níbí yìí máa ń ṣe bí ológun nínú gbogbo ìgbòkègbodò wọn.a Dípò kí wọ́n kọ́ ibùgbé tí wọ́n á máa gbé títí lọ, ńṣe làwọn ọmọ ogun tó máa ń ṣí kiri wọ̀nyí, tí iye wọn lè tó ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] nígbà míì, máa ń ṣe ibùgbé onígbà kúkúrú. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe èyí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàlọ wọ̀nyí á fi ẹsẹ̀ kọ́ ara wọn lẹ́sẹ̀ láti ṣe ògiri yíká yèyé ìjàlọ tí ń pamọ àtàwọn ọmọ ìjàlọ tíntìntín tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Látinú ibùgbé onígbà kúkúrú tí wọ́n ṣe yìí ni wọ́n á ti rán àwọn ìjàlọ tó jẹ́ ọmọ ogun jáde láti lọ wá oúnjẹ, ìyẹn oúnjẹ bíi kòkòrò tàbí àwọn ìṣẹ̀dá kéékèèké bí aláǹgbá, ńṣe làwọn ológun wọ̀nyí á sì tò tẹ̀lé ara wọn ní ìlà gígùn. Àwọn ìjàlọ tó jẹ́ aṣáájú nínú ẹgbẹ́ ológun náà tún máa ń ṣe ohun kan láti fi mú kòkòrò tí wọ́n á pa jẹ, ìyẹn ni pé wọ́n máa ń ya sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì kúrò nínú ìlà gbọọrọ náà. Èyí máa ń wáyé nígbà tó bá di pé kò sí kòkòrò kankan tí wọ́n ń tọpasẹ̀ rẹ̀, lákòókò yìí, àwọn ìjàlọ tó jẹ́ aṣáájú á tẹsẹ̀ dúró, wọ́n á sì mú kí gbogbo ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà dúró sójú kan. Ńṣe làwọn ìjàlọ tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn á rọ́ gììrì síwájú, tí àwọn ìjàlọ tó wà lọ́wọ́ iwájú á sì máa ṣù jọ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ìlà náà, èyí á sì mú kí àwọn ọmọ ogun náà máa ya sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì.
Ọjọ́ mẹ́rìndínlógójì làwọn kòkòrò wọ̀nyí fi máa ń ṣe gbogbo ìgbòkègbodò wọn. Wọ́n á fi ọjọ́ mẹ́rìndínlógún yan lọ, wọ́n á sì sinmi fún ogún ọjọ́, láàárín àkókò yìí sì tún ni yèyé ìjàlọ tí ń pamọ máa ń yé ẹyin rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ebi á mú kí àwùjọ àwọn kòkòrò náà tún yan lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ wọn sì lè fẹ̀ tó mítà mẹ́wàá. Àwọn nǹkan bí aláǹtakùn, àkekèé, yímíyímí, àkèré àti aláǹgbá tó ń sá fún wọn á wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹyẹ á máa tẹ̀ lé wọn, àmọ́ kì í ṣe láti jẹ àwọn ìjàlọ wọ̀nyí bí kò ṣe torí àtijẹ àwọn kòkòrò tó ń sá fún wọn.
Nínú Bíbélì, Òwe 30:24, 25 sọ pé àwọn ìjàlọ “ní ọgbọ́n àdámọ́ni,” nítorí náà, wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àpilẹ̀kọ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìjàlọ kan tó ń jẹ́ Eciton, èyí tó wà ní Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìjàlọ
[Credit Line]
© Frederick D. Atwood
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ṣíṣe afárá nípa fífi ẹsẹ̀ kọ́ ara wọn lẹ́sẹ̀
[Credit Line]
Tim Brown/www.infiniteworld.org
-
-
Yẹra fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Tó Máa Ń DunniJí!—2003 | June 8
-
-
Ojú Ìwòye Bíbélì
Yẹra fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Tó Máa Ń Dunni
“Láti inú ẹnu kan náà ni ìbùkún àti ègún ti ń jáde wá. Kò bẹ́tọ̀ọ́ mu, ẹ̀yin ará mi, kí nǹkan wọ̀nyí máa bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí.”—JÁKỌ́BÙ 3:10.
AGBÁRA ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ ohun pàtàkì kan tó mú kí àwa ẹ̀dá èèyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹranko. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn èèyàn kan máa ń ṣi ẹ̀bùn yìí lò. Àwọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, èpè ṣíṣẹ́, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, ọ̀rọ̀ òdì, ọ̀rọ̀ rírùn, àtàwọn èdè àlùfààṣá lè dunni wọra, àní, nígbà míì wọ́n máa ń dunni ju ọgbẹ́ ara lọ. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.”—Òwe 12:18.
Ńṣe làwọn èèyàn tó ń sọ èpè ṣíṣẹ́ dàṣà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ ń ròyìn pé ńṣe ni sísọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i láàárín àwọn èwe. Àmọ́, àwọn èèyàn kan sọ pé, sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa dun ẹlòmíràn wọra ṣàǹfààní tí inú bá ń bí èèyàn kí ara ẹni lè wálẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣèlú kọ̀wé pé: “Ó yẹ kéèyàn máa lo àwọn èdè àlùfààṣá, nígbà tí ọ̀rọ̀ lásán kò bá lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe dùnni tó.” Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni fi irú ojú yẹpẹrẹ bẹ́ẹ̀ wo àwọn ọ̀rọ̀ tó lè dun àwọn ẹlòmíràn? Irú ojú wo ni Ọlọ́run tiẹ̀ fi ń wò ó?
Kórìíra Àwọn Àwàdà Rírùn
Lílo èdè rírùn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dáyé o. Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu pé àwọn èèyàn lo èdè rírùn nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, lóhun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Bí àpẹẹrẹ, ó hàn pé àwọn kan nínú ìjọ Kólósè lo àwọn èdè àlùfààṣá nígbà tí àwọn kan múnú bí wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí àtifi ìbínú wọn hàn tàbí láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì lè jẹ́ láti gbẹ̀san. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lo àwọn èdè rírùn nígbà tínú bá ń bí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kólósè bá àkókò wa mu. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” (Kólósè 3:8) Ní kedere, a gba àwọn Kristẹni níyànjú láti yẹra fún fífi ìbínú hàn àti lílo àwọn èdè àlùfààṣá èyí tó sábà máa ń bá ìbínú rìn.
Lóòótọ́, kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń lo èdè rírùn ní in lọ́kàn láti gbéjà ko àwọn ẹlòmíràn tàbí láti nà wọ́n ní pàṣán ọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ti mọ́ wọn lára láti máa lò ó láìbìkítà. Èdè tó ń ríni lára á wá tipa bẹ́ẹ̀ di ohun tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má lò nínú ọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́. Kò tiẹ̀ rọrùn rárá fún àwọn kan láti sọ̀rọ̀ láìlo èdè àlùfààṣá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn kan máa ń dìídì sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ káwọn èèyàn bàa lè rẹ́rìn-ín. Àmọ́, ṣé ojú kò-tó-nǹkan ló yẹ ká máa fi wo irú àwọn àwàdàkáwàdà bẹ́ẹ̀, bí ohun téèyàn lè fàyè gbà? Gbé àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wó.
Àwàdà rírùn ni ọ̀rọ̀ tó ń kóni nírìíra táwọn kan máa ń sọ láti pa àwọn mìíràn lẹ́rìn-ín. Láyé òde òní, orí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ni púpọ̀ àwàdà burúkú sábà máa ń dá lé. Ọ̀pọ̀ àwọn tó sì kara wọn sí ọmọlúwàbí èèyàn ló máa ń gbádùn títẹ́tí sí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Róòmù 1:28-32) Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, àti ìbálòpọ̀ tó bójú mu àtèyí tí kò bójú mu ni ọ̀rọ̀ àwọn òṣèré tó jẹ́ aláwàdà sábà máa ń dá lé. Ọ̀rọ̀ rírùn kì í ṣe kó máà sí nínú ọ̀pọ̀ fíìmù títí kan àwọn ètò orí tẹlifísọ̀n àti rédíò.
Bíbélì kò ṣàì sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Éfésù pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ.” (Éfésù 5:3, 4) Èyí mú un ṣe kedere pé, Ọlọ́run kórìíra lílo àwọn èdè rírùn, láìka ohunkóhun tó lè mú ẹnì kan sọ ọ́ sí. Kò bójú mu. Ọ̀rọ̀ tó lè dunni wọra ni.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Burúkú Tí Kì Í Dùn Mọ́ Ọlọ́run Nínú
Dájúdájú, ọ̀rọ̀ burúkú kọjá kéèyàn máa lo èdè rírùn nìkan. Àwọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, fífini ṣẹ̀sín àti ṣíṣàríwísí ẹlòmíràn máa ń dunni gan-an. Òótọ́ ni pé gbogbo wa là ń fi ahọ́n wa ṣẹ̀, pàápàá lónìí tí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti sísọ̀rọ̀ ẹlòmíràn lẹ́yìn ti di ohun tó wọ́pọ̀. (Jákọ́bù 3:2) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ wo lílo èdè èébú bí ohun tí kò jẹ́ nǹkan kan. Bíbélì fi hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra gbogbo ọ̀rọ̀ tó lè dun àwọn ẹlòmíràn wọra.
Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Àwọn Ọba Kejì nínú Bíbélì, a kà nípa àwọn ọmọdékùnrin kan tí wọ́n ń ṣẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú sí wòlíì Èlíṣà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,” wọ́n sì “ń wí fún un ṣáá pé: ‘Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!’” Jèhófà, ẹni tó lè rí ohun tó wà nínú ọkàn àwọn ọmọ kéékèèké wọ̀nyí tó sì mọ èròkerò ọkàn wọn, kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ èébú tí wọ́n ń sọ náà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé Ọlọ́run pa àwọn ọmọdékùnrin méjìlélógójì nítorí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ ẹnu wọn ọ̀hún.—2 Àwọn Ọba 2:23, 24.
Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì “ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbọ̀rìṣà àti àìgbọ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ lolórí ohun tó fa ìbínú Ọlọ́run, síbẹ̀ ó yẹ ká kíyè sí i pé Bíbélì dìídì sọ̀rọ̀ nípa èébú tí wọ́n ń bú àwọn wòlíì Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí irú ìwà bẹ́ẹ̀ rárá.
-