ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • ORÍ 11

      Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”

      Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà táwọn èèyàn ta kò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

      Ó dá lórí Ìṣe 13:1-52

      1, 2. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrìn àjò tí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù fẹ́ rìn, báwo ni iṣẹ́ wọn sì ṣe máa mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣe 1:8 ṣẹ?

      ỌJỌ́ ayọ̀ lọjọ́ náà jẹ́ fáwọn ará ìjọ tó wà ní Áńtíókù. Nínú gbogbo àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà níbẹ̀, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ni ẹ̀mí mímọ́ yàn láti mú ìhìn rere lọ sáwọn ibi tó jìnnà.a (Ìṣe 13:1, 2) Òótọ́ ni pé wọ́n ti rán àwọn ọkùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn jáde lọ sáwọn ibì kan ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára ibi tí wọ́n rán wọn lọ làwọn Kristẹni ti wà. (Ìṣe 8:14; 11:22) Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n máa rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù lọ sáwọn ilẹ̀ tí ìhìn rere ò tíì dé, Jòhánù tó tún jẹ́ Máàkù máa wà pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.

      2 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, Jésù ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní báyìí tí wọ́n ti yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ míṣọ́nnárì, ìyẹn máa mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn ṣẹ!b

      ‘Ẹ Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Kí Wọ́n Lè Ṣe Iṣẹ́ Tí Mo Pè Wọ́n Sí’ (Ìṣe 13:1-12)

      3. Kí ló mú kó ṣòro láti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

      3 Lóde òní, ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti rìnrìn àjò lọ síbi tó jìn láàárín wákàtí kan sí méjì nítorí àwọn ohun ìrìnnà bíi mọ́tò àti ọkọ̀ òfúrufú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Nígbà yẹn, ẹsẹ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rìnrìn àjò láwọn ojú ọ̀nà tó rí gbágungbàgun. Èèyàn lè fi odindi ọjọ́ kan rin ìrìn ọgbọ̀n (30) kìlómítà, ìrìn náà sì máa ń tánni lókun!c Torí náà, bí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ṣe ń fayọ̀ retí iṣẹ́ wọn tuntun yìí, ó dájú pé wọ́n á tún máa ronú pé àwọn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi, àwọn sì máa ní láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan.​—Mát. 16:24.

      ÌRÌN ÀJÒ NÍGBÀ AYÉ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ

      Láyé àtijọ́, ìrìn àjò orí ilẹ̀ kì í yá, ó máa ń tánni lókun, ó sì máa ń náni lówó ju kéèyàn wọ́ ọkọ̀ ojú omi lọ. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ibi lèèyàn ò lè dé nígbà yẹn láìjẹ́ pé ó fẹsẹ̀ rìn.

      Èèyàn lè fẹsẹ̀ rin nǹkan bí ọgbọ̀n (30) kìlómítà lóòjọ́. Ẹni náà máa ní láti fara da àwọn nǹkan bí oòrùn, òjò, ooru àti òtútù. Ó sì ṣeé ṣe kó pàdé àwọn dánàdánà lójú ọ̀nà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun wà “nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà.”​—2 Kọ́r. 11:26.

      Àwọn ọ̀nà tó dáa wà lọ́pọ̀ ibi káàkiri Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Láwọn òpópónà térò sábà máa ń gbà, wọ́n máa ń ṣe ilé ìgbàlejò táwọn arìnrìn-àjò ti lè sùn mọ́jú lẹ́yìn ìrìn àjò ọjọ́ kan. Àwọn ilé ìgbàlejò náà tún máa ń ní ilé ìtajà táwọn arìnrìn àjò ti lè ra àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọ́n nílò. Àwọn òǹkọ̀wé kan sọ pé àwọn ilé ìgbàlejò àti ilé ìtajà yẹn máa ń kún fọ́fọ́, ó máa ń dọ̀tí, ó máa ń móoru, ẹ̀fọn sì máa ń pọ̀ níbẹ̀. Àwọn èèyànkéèyàn ló sì máa ń kúnbẹ̀. Àwọn tó ń bójú tó àwọn ilé ìgbàlejò náà sábà máa ń ja àwọn arìnrìn-àjò lólè, wọ́n sì tún láwọn aṣẹ́wó tó ń ṣiṣẹ́ fún wọn.

      Ó dájú pé àwọn Kristẹni máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa máa dé sáwọn ilé ìgbàlejò yẹn. Àmọ́, tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò láwọn ìlú tí wọn ò ti ní mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́, wọ́n máa ní láti sùn síbẹ̀.

      4. (a) Kí ló darí àwọn tó yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù, ojú wo sì làwọn onígbàgbọ́ yòókù fi wo bí wọ́n ṣe yàn wọ́n? (b) Báwo la ṣe lè máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?

      4 Àmọ́, kí nìdí tí ẹ̀mí mímọ́ fi dìídì sọ pé kí wọ́n ‘ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run pè wọ́n sí’? (Ìṣe 13:2) Bíbélì ò sọ fún wa. Ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí wọ́n yan àwọn ọkùnrin náà. Kò sì sóhun tó fi hàn pé àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Áńtíókù ta ko ìpinnu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣètìlẹyìn fáwọn ọkùnrin náà. Fojú inú wo bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára Bánábà àti Sọ́ọ̀lù báwọn arákùnrin wọn ṣe ‘gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ’ láìsí pé wọ́n ń jowú wọn. (Ìṣe 13:3) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, títí kan àwọn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Dípò tí àá fi máa jowú àwọn tó nírú àǹfààní bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa “kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”​—1 Tẹs. 5:13.

      5. Báwo ni Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ṣe wàásù ìhìn rere ní erékùṣù Sápírọ́sì?

      5 Lẹ́yìn tí wọ́n ti fẹsẹ̀ rìn dé Séléúkíà, ìyẹn èbúté kan nítòsí Áńtíókù, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí erékùṣù Sápírọ́sì, èyí tó jẹ́ nǹkan bí ìrìn àjò ọgọ́rùn-ún méjì (200) kìlómítà.d Ọmọ ìbílẹ̀ Sápírọ́sì ni Bánábà, torí náà inú ẹ̀ dùn gan-an pé ó láǹfààní láti wàásù ìhìn rere fáwọn ará ìlú ẹ̀. Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ò fàkókò ṣòfò nígbà tí wọ́n dé Sálámísì, tó jẹ́ èbúté kan ní ìlà oòrùn erékùṣù náà. Ojú ẹsẹ̀ ni “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù.”e (Ìṣe 13:5) Bánábà àti Sọ́ọ̀lù rìnrìn àjò dé gbogbo erékùṣù tó wà ní Sápírọ́sì, ó sì jọ pé wọ́n ń wàásù láwọn ìlú tó wà lójú ọ̀nà bí wọ́n ṣe ń lọ. Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kí wọ́n rin ìrìn nǹkan bí ọgọ́jọ (160) kìlómítà.

      SÍNÁGỌ́GÙ ÀWỌN JÚÙ

      Ohun tí “sínágọ́gù” túmọ̀ sí ni “kíkójọ pọ̀.” Ó sì ń tọ́ka sí àpéjọ tàbí ìjọ àwọn Júù. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo orúkọ yìí fún ibi kan tàbí ilé táwọn èèyàn ń kóra jọ pọ̀ sí láti jọ́sìn Jèhófà.

      Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà táwọn Júù wà nígbèkùn fún àádọ́rin ọdún (70) ní Bábílónì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo Sínágọ́gù tàbí kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n pa dà dé. Nínú Sínágọ́gù, wọ́n máa ń fúnni ní ìtọ́ni, wọ́n máa ń jọ́sìn, wọ́n máa ń ka Ìwé Mímọ́, wọ́n sì máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbani níyànjú. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, gbogbo ìlú tó wà ní Palẹ́sìnì ló ní sínágọ́gù tiẹ̀. Àwọn ìlú ńlá máa ń ní ju ẹyọ kan lọ, torí náà ọ̀pọ̀ sínágọ́gù ló wà ní Jerúsálẹ́mù.

      Kì í ṣe gbogbo àwọn Júù ló pa dà sí Palẹ́sìnì lẹ́yìn ìgbèkùn wọn ní Bábílónì. Ọ̀pọ̀ lára wọn ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì torí ọrọ̀ ajé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù ń gbé káàkiri ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínláàádóje (127) ilẹ̀ ọba Páṣíà. (Ẹ́sít. 1:1; 3:8) Nígbà tó yá, àwọn Júù tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbé láwọn ìlú tó wà nítòsí Òkun Mẹditaréníà. Àwọn Júù yìí bẹ̀rẹ̀ sí í dá sínágọ́gù sílẹ̀ láwọn ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí.

      Láwọn ọjọ́ Sábáàtì, wọ́n máa ń ka Òfin, wọ́n sì máa ń ṣàlàyé ẹ̀ nínú sínágọ́gù. Orí pèpéle tó ga ni wọ́n máa ń dúró sí láti ka òfin, ìjókòó sì wà ní ìwájú àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì pèpéle náà. Táwọn Júù bá kóra jọ lọ́jọ́ Sábáàtì, gbogbo ọkùnrin Júù tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ló lè kàwé, wàásù tàbí gbani níyànjú látinú Ìwé Mímọ́.

      6, 7. (a) Ta ni Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, kí nìdí tí Baa-Jésù sì fi gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́ kó má bàa fetí sí ìhìn rere? (b) Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe paná àtakò Baa-Jésù?

      6 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹ̀sìn èké lọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní erékùṣù Sápírọ́sì ń ṣe. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn nígbà tí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù dé Páfò tó wà létíkun ìwọ̀ oòrùn erékùṣù náà. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní “Baa-Jésù” níbẹ̀. ‘Oníṣẹ́ oṣó àti wòlíì èké ni. Ó wà pẹ̀lú Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀, tó sì jẹ́ ọkùnrin onílàákàyè.’f Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ará Róòmù tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn títí kan àwọn “ọkùnrin onílàákàyè” bíi Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, sábà máa ń lọ woṣẹ́ lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ oṣó tàbí awòràwọ̀ kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Àmọ́, ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run wọ Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì lọ́kàn, ‘ara rẹ̀ sì ti wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Inú Baa-Jésù ò dùn rárá bó ṣe rí i pé Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Élímà ni orúkọ oyè Baa-Jésù, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ni “Oníṣẹ́ oṣó.”​—Ìṣe 13:6-8.

      7 Baa-Jésù ta ko ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Òun ni agbaninímọ̀ràn Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, ó sì gbà pé tóun ò bá fẹ́ kí ipò náà bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, òun ní láti “yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 13:8) Àmọ́, Sọ́ọ̀lù ò fẹ́ lajú ẹ̀ sílẹ̀ kí oníṣẹ́ oṣó kan wá yí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì lọ́kàn pa dà. Kí ni Sọ́ọ̀lù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ni Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n tún ń pè ní Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, bá tẹjú mọ́ ọn [Baa-Jésù], ó sì sọ pé: ‘Ìwọ ọkùnrin tí oríṣiríṣi jìbìtì àti ìwà ibi kún ọwọ́ rẹ̀, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ ọ̀tá gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo, ṣé o kò ní ṣíwọ́ yíyí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po ni? Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà wà lára rẹ, wàá fọ́ lójú, o ò ní rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún àkókò kan.’ Lójú ẹsẹ̀, kùrukùru tó ṣú àti òkùnkùn bò ó, ó sì ń táràrà, ó ń wá ẹni tó máa di òun lọ́wọ́ mú lọ.”g Kí ni Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì wá ṣe? “Bí alákòóso ìbílẹ̀ náà ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó di onígbàgbọ́, torí ẹ̀kọ́ Jèhófà yà á lẹ́nu gan-an.”​—Ìṣe 13:9-12.

      Arákùnrin kan ṣí Bíbélì dání, ó ń gbèjà òtítọ́ nílé ẹjọ́.

      Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà ń fìgboyà gbèjà òtítọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wa

      8. Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi ti Pọ́ọ̀lù lóde òní?

      8 Pọ́ọ̀lù ò bẹ̀rù Baa-Jésù. Bákan náà, kò yẹ káwa náà bẹ̀rù nígbà táwọn alátakò bá fẹ́ bomi paná ìgbàgbọ́ àwọn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ o, ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa “máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn.” (Kól. 4:6) Síbẹ̀, kò yẹ ká torí pé ká má bàa mú àwọn èèyàn bínú ká wá máa fà sẹ́yìn láti wàásù fáwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Jèhófà. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú ká fà sẹ́yìn láti tú àṣírí ẹ̀sìn èké tó ń bá a lọ láti máa “yí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po” bíi ti Baa-Jésù. (Ìṣe 13:10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ káwa náà máa ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, ká máa fìgboyà wàásù fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Lónìí, Jèhófà lè má fún wa lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bíi ti Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fa àwọn ẹni yíyẹ wá sínú òtítọ́.​—Jòh. 6:44.

      “Ọ̀rọ̀ Ìṣírí” (Ìṣe 13:13-43)

      9. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni lóde òní?

      9 Ó dájú pé ohun kan yí pa dà nígbà táwọn ọkùnrin náà kúrò ní Páfò, tí wọ́n sì wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Pẹ́gà ní etíkun Éṣíà Kékeré, èyí tó jẹ́ ìrìn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta (250) kìlómítà lójú òkun. Nínú Ìṣe 13:13, wọ́n pe àwùjọ náà ní “Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ló ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn náà. Àmọ́ o, kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Bánábà jowú Pọ́ọ̀lù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ọkùnrin náà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Àpẹẹrẹ rere ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jẹ́ fáwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni lónìí. Dípò káwọn Kristẹni máa wá ipò ọlá, ńṣe ni wọ́n máa ń rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Arákùnrin . . . ni gbogbo yín.” Jésù tún sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”​—Mát. 23:8, 12.

      10. Báwo ni ìrìn àjò láti Pẹ́gà sí Áńtíókù ti Písídíà ṣe rí?

      10 Nígbà tí wọ́n dé Pẹ́gà, Jòhánù Máàkù fi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sílẹ̀, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ò sọ ìdí tó fi pa dà lójijì bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń bá ìrìn àjò wọn lọ, wọ́n gba Pẹ́gà kọjá lọ sí Áńtíókù ti Písídíà, ìyẹn ìlú kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Gálátíà. Ìrìn àjò kékeré kọ́ lèyí, torí pé Áńtíókù ti Písídíà fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún (1,100) mítà ga ju ojú òkun lọ. Ọ̀nà ibẹ̀ rí gbágungbàgun, ó sì léwu torí pé àwọn dánàdánà máa ń wà níbẹ̀. Ohun míì ni pé, ó jọ pé ara Pọ́ọ̀lù ò yá nígbà yẹn.h

      11, 12. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù tó wà ní Áńtíókù ti Písídíà, kí ló ṣe kọ́rọ̀ ẹ̀ lè wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?

      11 Ní Áńtíókù ti Písídíà, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wọnú sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Lẹ́yìn kíka Òfin àti ìwé àwọn Wòlíì fún àwọn èèyàn, àwọn alága sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: ‘Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, tí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí fún àwọn èèyàn, ẹ sọ ọ́.’ ” (Ìṣe 13:15) Pọ́ọ̀lù wá dìde láti sọ̀rọ̀.

      12 Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fetí sílẹ̀.” (Ìṣe 13:16) Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, wọn ò sì mọ̀ ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Torí náà, kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kọ́rọ̀ ẹ̀ lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn? Ńṣe ló kọ́kọ́ sọ ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ó ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe “gbé àwọn èèyàn náà ga nígbà tí wọ́n jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì” àti bí Ọlọ́run ṣe “fara dà á fún wọn ní aginjù” fún ogójì (40) ọdún. Pọ́ọ̀lù tún sọ báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí Jèhófà ṣe “fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún” fún wọn. (Ìṣe 13:17-19) Àwọn kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kà látinú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ayẹyẹ Sábáàtì ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, á jẹ́ pé òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù mọ bó ṣe lè “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.”​—1 Kọ́r. 9:22.

      13. Báwo la ṣe lè jẹ́ kọ́rọ̀ wa wọ àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?

      13 Àwa náà gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa wọ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mọ ẹ̀sìn tẹ́nì kan ń ṣe, ìyẹn lè jẹ́ ká yan àkòrí tó máa fa ẹni náà mọ́ra. Bákan náà a lè tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì tó ṣeé ṣe kí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀. Nígbà míì, ohun táá dáa jù ni pé ká ní kí ẹni náà kà á látinú Bíbélì tiẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa oríṣiríṣi nǹkan tá a lè ṣe kọ́rọ̀ wa lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.

      14. (a) Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń wàásù ìhìn rere nípa Jésù, báwo ló sì ṣe kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀? (b) Kí làwọn èèyàn náà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù?

      14 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àtọmọdọ́mọ àwọn ọba Ísírẹ́lì ni Jésù. Ó tún sọ bí Jòhánù Onírìbọmi ṣe múra ọkàn àwọn èèyàn sílẹ̀ kí wọ́n lè gba Jésù tó jẹ́ “olùgbàlà.” Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe pa Jésù àti bí Ọlọ́run ṣe jí i dìde. (Ìṣe 13:20-37) Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín . . . à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.” Àpọ́sítélì náà wá kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì má bàa ṣẹ sí yín lára, pé: ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣègbé, nítorí mò ń ṣe iṣẹ́ kan lásìkò yín, iṣẹ́ tí ẹ ò ní gbà gbọ́ láé bí ẹnì kan bá tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún yín.’ ” Ohun táwọn èèyàn náà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù wúni lórí. Bíbélì ròyìn pé: “Àwọn èèyàn bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e.” Bákan náà, lẹ́yìn tí àpéjọ sínágọ́gù parí, “ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà.”​—Ìṣe 13:38-43.

      “A Yíjú sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè” (Ìṣe 13:44-52)

      15. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e?

      15 Ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú náà” ló kóra jọ láti gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù. Èyí ò dùn mọ́ àwọn Júù kan nínú, torí náà wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ òdì ta ko àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” Òun àti Bánábà wá fìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún. Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí Jèhófà ti pa àwọn ọ̀rọ̀ yìí láṣẹ fún wa pé: ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí o lè jẹ́ ìgbàlà fún gbogbo ayé.’ ”​—Ìṣe 13:44-47; Àìsá. 49:6.

      Àwọn alátakò tínú ń bí wọ́ Bánábà lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú Áńtíókù ti Písídíà.

      “Wọ́n gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà . . .  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń ní ìdùnnú àti ẹ̀mí mímọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​—Ìṣe 13:50-52

      16. Kí làwọn Júù ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ líle táwọn míṣọ́nnárì yìí sọ fún wọn, kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ṣe nígbà táwọn alátakò jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn?

      16 Inú àwọn Kèfèrí tó gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù dùn gan-an, “gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 13:48) Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀rọ̀ Jèhófà fi tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ohun táwọn Júù ṣe yàtọ̀. Nítorí náà, àwọn míṣọ́nnárì yìí sọ fún wọn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, wọ́n yàn láti kọ Mèsáyà, ìdájọ́ Ọlọ́run sì tọ́ sí wọn. Torí náà, àwọn Júù ru àwọn obìnrin olókìkí àtàwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú náà sókè, wọ́n wá “gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn.” Kí wá ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe? Ńṣe ni “wọ́n gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù sí wọn, wọ́n sì lọ sí Íkóníónì.” Ṣé ibẹ̀ yẹn wá ni ẹ̀sìn Kristẹni máa dé dúró ní Áńtíókù ti Písídíà? Rárá o! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílẹ̀ síbẹ̀ “ń ní ìdùnnú àti ẹ̀mí mímọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​—Ìṣe 13:50-52.

      17-19. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi lélẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ máa láyọ̀?

      17 Ẹ̀kọ́ pàtàkì la rí kọ́ látinú bí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ṣe ń fi ayọ̀ bá iṣẹ́ wọn lọ láìka ti pé àwọn èèyàn ta kò wọ́n. Àwa náà ò ní dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró, kódà táwọn tó wà nípò àṣẹ bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn èèyàn Áńtíókù kọ ìhìn rere, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà “gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù.” Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò túmọ̀ sí pé wọ́n bínú o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fi hàn pé ọrùn àwọn mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn náà. Àwọn míṣọ́nnárì yìí mọ̀ pé àwọn ò lè fipá mú àwọn èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere. Ohun tí wọ́n lè ṣe ò ju pé kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní yéé wàásù. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n pinnu láti lọ sí Íkóníónì.

      18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílẹ̀ sí Áńtíókù ńkọ́? Lóòótọ́, àárín àwọn ọ̀tá ni wọ́n wà. Àmọ́, kì í ṣe bí iye àwọn tó gbọ́ ìhìn rere ṣe pọ̀ tó ló pinnu bóyá wọ́n máa láyọ̀ àbí wọn ò ní láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Áńtíókù ti Písídíà sì pinnu láti ṣe nìyẹn.

      19 Bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, ẹ jẹ́ ká máa rántí ní gbogbo ìgbà pé ojúṣe wa ni láti wàásù ìhìn rere. Ó wá kù sọ́wọ́ àwọn èèyàn láti yàn bóyá wọ́n máa gbọ́ tàbí wọn ò ní gbọ́. Táwọn tá à ń wàásù fún bá kọtí ikún sí wa, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Táwa náà bá mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́, tá a sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí wa, àá máa láyọ̀, kódà nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá.​—Gál. 5:18, 22.

      BÁNÁBÀ​—“ỌMỌ ÌTÙNÚ”

      Ọ̀kan lára àwọn tó múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́gọ́rùn ọdún kìíní ni ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù, tó sì jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Sápírọ́sì. Torí pé ó máa ń ṣoore fáwọn èèyàn, àwọn àpọ́sítélì fún un ní orúkọ kan, ìyẹn Bánábà tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú.” (Ìṣe 4:36) Nígbà tí Bánábà rí i pé àwọn ará nílò ìrànlọ́wọ́, kíákíá ló wá bó ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

      Bánábà ń fi àpò owó méjì ṣètìlẹyìn.

      Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Sànmánì Kristẹni, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn rìnrìn àjò wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe àjọyọ̀ náà, wọ́n sì lè má ní in lọ́kàn pé àwọn máa pẹ́ níbẹ̀. Torí náà, ìjọ nílò owó tí wọ́n á fi pèsè ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn nílò. Bánábà wá ta ilẹ̀ kan, ó sì fi tinútinú kó owó náà fún àwọn àpọ́sítélì kó lè fi ti ìjọ lẹ́yìn.​—Ìṣe 4:32-37.

      Alábòójútó tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ni Bánábà, ó máa ń wù ú gan-an pé kó ran àwọn ará lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, òun ló ran Sọ́ọ̀lù ará Tásù lọ́wọ́ nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ń bẹ̀rù rẹ̀ torí pé ó máa ń ṣenúnibíni sáwọn ará tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 9:26, 27) Bánábà tún fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún òun àti Pétérù nípa bó ṣe yẹ káwọn Júù máa ṣe sáwọn Kèfèrí tó di Kristẹni. (Gál. 2:9, 11-14) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé “Ọmọ Ìtùnú” ni Bánábà lóòótọ́.

      a Wo àpótí náà, “Bánábà​—‘Ọmọ Ìtùnú.’”

      b Lásìkò yẹn, wọ́n ti wàásù ìhìn rere dé àwọn ibi tó jìnnà, wọ́n sì ti dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ibì kan, bí Áńtíókù ti Síríà tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) kìlómítà sí àríwá Jerúsálẹ́mù.

      c Wo àpótí náà, “Ìrìn Àjò Nígbà Ayé Àwọn Àpọ́sítélì.”

      d Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọkọ̀ ojú omi kan lè rin ìrìn àjò nǹkan bí àádọ́jọ (150) kìlómítà lóòjọ́ tí ojú ọjọ́ bá dáa. Àmọ́, ó lè má tó bẹ́ẹ̀ tí ojú ọjọ́ ò bá dáa.

      e Wo àpótí náà, “Sínágọ́gù Àwọn Júù.”

      f Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin àwọn ará Róòmù ló ń ṣàkóso erékùṣù Sápírọ́sì. Àwọn ará Róòmù ló máa ń yan gómìnà tó ń ṣákóso erékùṣù náà.

      g Ibí yìí ni Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí í pe Sọ́ọ̀lù ní Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan sọ pé, torí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ló ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ Róòmù yìí. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò yí orúkọ náà pa dà lẹ́yìn tó kúrò ní Sápírọ́sì, èyí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe torí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ló ṣe ń jẹ́ orúkọ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dìídì pinnu láti máa jẹ́ orúkọ yìí torí pé “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ni. Yàtọ̀ síyẹn, ó jọ pé ọ̀rọ̀ kan wà lédè Gíríìkì tó ní ìtumọ̀ tí ò dáa, tó sì jọ Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ orúkọ Pọ́ọ̀lù lédè Hébérù. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí Pọ́ọ̀lù pinnu pé òun ò ní jẹ́ Sọ́ọ̀lù mọ́.​—Róòmù 11:13.

      h Lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ará Gálátíà. Nínú lẹ́tà yẹn, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín.”​—Gál. 4:13.

  • Wọ́n “Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípasẹ̀ Àṣẹ Jèhófà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • ORÍ 12

      Wọ́n “Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípasẹ̀ Àṣẹ Jèhófà”

      Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní ìrẹ̀lẹ̀, ìforítì àti ìgboyà

      Ó dá lórí Ìṣe 14:1-28

      1, 2. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wà ní Lísírà?

      ÌDÀRÚDÀPỌ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó ń gbé ní Lísírà. Àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ àjèjì mú ọkùnrin kan tó ti yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i lára dá. Ńṣe ni inú ọkùnrin náà ń dùn ṣìnkìn, bẹ́ẹ̀ ló ń fò káàkiri. Ẹnu ya àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ gan-an! Torí náà, àlùfáà Súúsì kan mú òdòdó ẹ̀yẹ wá fáwọn ọkùnrin méjì náà, torí pé wọ́n gbà gbọ́ pé ọlọ́run ni wọ́n. Àwọn akọ màlúù bẹ̀rẹ̀ sí í ké bí àlùfáà náà ṣe fẹ́ máa pa wọ́n. Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá figbe ta pé kí wọ́n má ṣe rúbọ sáwọn. Àwọn méjèèjì fa aṣọ wọn ya, wọ́n bọ́ sáàárín èrò náà, wọ́n sì ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn. Àmọ́, agbára káká ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi dá wọn dúró.

      2 Lẹ́yìn náà, àwọn Júù alátakò dé láti Áńtíókù ti Písídíà àti Íkóníónì. Wọ́n sì sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láìdáa lọ́dọ̀ àwọn ará Lísírà. Àwọn èèyàn tó ti fẹ́ jọ́sìn Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ lókùúta títí tó fi dá kú. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fìyà jẹ Pọ́ọ̀lù dáadáa, wọ́n wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi ìlú, torí wọ́n rò pé ó ti kú.

      3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú orí yìí?

      3 Kí ló fa gbogbo wàhálà yìí? Ẹ̀kọ́ wo làwọn oníwàásù ìhìn rere lóde òní lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù? Kí la lè rí kọ́ nínú báwọn ará Lísírà ṣe ṣàdédé yí ìpinnu wọn pa dà? Báwo sì làwọn Kristẹni alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bánábà àti Pọ́ọ̀lù nípa bí wọ́n ṣe ní ìforítì lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, tí wọ́n sì “fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà”?​—Ìṣe 14:3.

      “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ . . . Di Onígbàgbọ́” (Ìṣe 14:1-7)

      4, 5. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi rìnrìn àjò lọ sí Íkóníónì, kí ló sì ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?

      4 Ní ọjọ́ bíi mélòó kan ṣáájú, lẹ́yìn táwọn Júù alátakò ti dá wàhálà sílẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n lé wọn jáde kúrò ní Áńtíókù ti Písídíà nílùú Róòmù. Dípò kí wọ́n bínú, ńṣe ni wọ́n “gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù” lòdì sí àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ olóríkunkun yẹn. (Ìṣe 13:50-52; Mát. 10:14) Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò ṣe bá àwọn alátakò yẹn fa wàhálà rárá, ńṣe ni wọ́n fà wọ́n lé Ọlọ́run lọ́wọ́. (Ìṣe 18:5, 6; 20:26) Àwọn míṣọ́nnárì méjì yìí ò jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ba ayọ̀ wọn jẹ́, ńṣe ni wọ́n ń bá ìrìn àjò wọn lọ tí wọ́n sì ń wàásù. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìnrìn àjò nǹkan bí àádọ́jọ (150) kìlómítà lọ sápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn, wọ́n dé orí òkè kan tó tẹ́jú tó sì lọ́ràá dáadáa, èyí tó wà láàárín àwọn òkè Táúrù àti òkè Sọ́táànì.

      5 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kọ́kọ́ dúró ní Íkóníónì, ìlú kan tí kò fi àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì ṣeré rárá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú pàtàkì-pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Gálátíà, tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù.a Àwọn Júù tó lẹ́nu láwùjọ àti ọ̀pọ̀ àwọn aláwọ̀ṣe tí kì í ṣe Júù ló ń gbé ìlú yìí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n wọnú sínágọ́gù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. (Ìṣe 13:5, 14) Wọ́n “sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́.”​—Ìṣe 14:1.

      ÍKÓNÍÓNÌ​—ÌLÚ ÀWỌN ARÁ FÍRÍJÍÀ

      Ibi gíga tó tẹ́jú, tó lómi dáadáa, tó sì lọ́ràá ni ìlú Íkóníónì wà. Àwọn oníṣòwò máa ń gbabẹ̀ kọjá dáadáa, torí pé ọ̀nà ibẹ̀ lọ sí ìlú Síríà, Róòmù, Gíríìkì, àtàwọn àgbègbè tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso ní Éṣíà.

      Abo ọlọ́run ìbímọlémọ àwọn ará Fíríjíà tí wọ́n ń pè ní Síbílì làwọn ará Íkóníónì ń jọ́sìn. Inú àṣà àwọn Gíríìkì ni ìjọsìn yìí ti wá, àsìkò tí wọ́n sì ń ṣàkóso ìlú Íkóníónì làwọn ará ibẹ̀ gba ẹ̀sìn náà. Ìjọba Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ìlú yìí ní ọdún 65 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wà níbẹ̀, ojúkò ìṣòwò àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ìlú náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó lẹ́nu láwùjọ ló ń gbé ìlú Íkóníónì, ó jọ pé àṣà ìbílẹ̀ Gíríìkì ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Kódà, ìwé Ìṣe sọ pé àwọn Júù àtàwọn “Gíríìkì” ń gbé ní Íkóníónì.​—Ìṣe 14:1.

      Àárín ìlú Likaóníà àti Fíríjíà ni ìlú Íkóníónì wà lágbègbè Gálátíà. Àwọn òǹkọ̀wé ìgbàanì kan, títí kan Cicero àti Strabo sọ pé ìlú Íkóníónì náà ni ìlú Likaóníà, tá a bá sì wo ibi tí ìlú Íkóníónì wà, àgbègbè ìlú Likaóníà ló bọ́ sí. Àmọ́, ìwé Ìṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Íkóníónì yàtọ̀ sí Likaóníà tí wọ́n ti ń sọ “èdè Likaóníà.” (Ìṣe 14:1-6, 11) Nítorí èyí, àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé ìwé Ìṣe kò péye. Àmọ́ lọ́dún 1910, àwọn awalẹ̀pìtàn rí àwọn àkọsílẹ̀ kan nílùú Íkóníónì tó fi hàn pé èdè Fíríjíà ni wọ́n ń sọ nílùú náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Nítorí náà, ó tọ́ bí ẹni tó kọ ìwé Ìṣe ṣe fìyàtọ̀ sáàárín ìlú Íkóníónì àtàwọn ìlú Likaóníà.

      6. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an, báwo la sì ṣe lè fara wé wọn?

      6 Kí ló mú kí ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbà sọ̀rọ̀ wọni lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa ọgbọ́n tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Pẹ̀lú ọgbọ́n ló fi fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìtàn, àsọtẹ́lẹ̀ àti Òfin Mósè, kó bàa lè fẹ̀rí hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà. (Ìṣe 13:15-31; 26:22, 23) Ó hàn kedere pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn máa ń jẹ Bánábà lógún gan-an. (Ìṣe 4:36, 37; 9:27; 11:23, 24) Àwọn méjèèjì ò gbára lé òye tara wọn, àmọ́ wọ́n ń sọ̀rọ̀ “nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà.” Báwo lo ṣe lè fara wé àwọn míṣọ́nnárì yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí: Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé ẹ dáadáa. Yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣeé ṣe kó wọ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn. Wá àwọn ọ̀nà tó o lè gbà tu àwọn tó ò ń wàásù fún nínú. Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni kó o máa kọ́ àwọn èèyàn, kì í ṣe ọgbọ́n ara ẹ.

      7. (a) Kí ni ìhìn rere tá à ń wàásù máa ń yọrí sí? (b) Táwọn èèyàn ẹ bá kẹ̀yìn sí ẹ torí pé o ṣègbọràn sí ìhìn rere, kí ló yẹ kó o rántí?

      7 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn ará Íkóníónì ni inú wọn dùn sóhun tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ. Lúùkù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Àwọn Júù tí kò gbà gbọ́ ru àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sókè, wọ́n sì sún wọn láti kórìíra àwọn arákùnrin.” Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn dúró kí wọ́n lè fi hàn pé òótọ́ ni ìhìn rere táwọn ń wàásù. Torí náà, wọ́n “lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi ìgboyà sọ̀rọ̀.” Àbájáde èyí ni pé, “àwọn èrò inú ìlú náà pín sí méjì; àwọn kan wà lẹ́yìn àwọn Júù, àwọn míì sì wà lẹ́yìn àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 14:2-4) Ohun tí ìhìn rere tá à ń wàásù lóde òní náà máa ń yọrí sí nìyẹn. Ó máa ń mú káwọn kan wà níṣọ̀kan, ó sì ń pín àwọn kan níyà. (Mát. 10:34-36) Tó bá jẹ́ torí pé o ṣègbọràn sí ìhìn rere làwọn èèyàn ẹ ṣe kẹ̀yìn sí ẹ, máa rántí pé ọ̀rọ̀ àhesọ tàbí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń gbọ́ nípa wa ló sábà máa ń mú kí wọ́n ṣàtakò. Ìwà rere rẹ lè pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tó ń ta kò ẹ́, èyí sì lè mú kí wọ́n yíwà pa dà.​—1 Pét. 2:12; 3:1, 2.

      8. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi kúrò ní Íkóníónì, kí la sì rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn?

      8 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà táwọn alátakò ní Íkóníónì fi gbìmọ̀ pọ̀ láti sọ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lókùúta pa. Nígbà táwọn míṣọ́nnárì yìí gbọ́ nípa èyí, ńṣe ni wọ́n lọ wàásù níbòmíì. (Ìṣe 14:5-7) Àwa tá à ń wàásù ìhìn rere lóde òní náà máa ń lo irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀. Táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ burúkú nípa wa tàbí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, a máa ń fìgboyà dá wọn lóhùn. (Fílí. 1:7; 1 Pét. 3:13-15) Àmọ́, tá a bá rí i pé wàhálà ń bọ̀, a máa ń yẹra fún ṣíṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu tó lè fi àwa àtàwọn míì tá a jọ ń sin Jèhófà sínú ewu.​—Òwe 22:3.

      ‘Ẹ Yí Pa Dà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Alààyè’ (Ìṣe 14:8-19)

      9, 10. Ibo ni ìlú Lísírà wà, kí la sì mọ̀ nípa àwọn ará ìlú náà?

      9 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà forí lé ìlú Lísírà, ìyẹn ìlú kan tó wà lábẹ́ àkóso ìlú Róòmù. Ìlú yìí wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) kìlómítà sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Íkóníónì. Àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín ìlú Lísírà àti Áńtíókù ti Písídíà, àmọ́ àwọn Júù kò pọ̀ nílùú Lísírà bíi ti Áńtíókù ti Písídíà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ìlú Lísírà máa ń sọ èdè Gíríìkì, Likaóníà gangan lèdè ìbílẹ̀ wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé kò sí sínágọ́gù nílùú Lísírà ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù níta gbangba. Nígbà tí Pétérù wà ní Jerúsálẹ́mù, ó wo ọkùnrin aláàbọ̀ ara kan sàn. Ní Lísírà, Pọ́ọ̀lù náà wo ọkùnrin kan tó ti yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i sàn. (Ìṣe 14:8-10) Nítorí iṣẹ́ ìyanu tí Pétérù ṣe, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́. (Ìṣe 3:1-10) Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ ìyanu yàtọ̀ pátápátá.

      10 Bá a ṣe ṣàlàyé níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, nígbà tí ọkùnrin arọ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í rìn tó sì ń fò káàkiri, ojú ẹsẹ̀ ni àwọn abọ̀rìṣà ará Lísírà yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò dáa. Wọ́n pe Bánábà ní Súúsì, ìyẹn olórí àwọn òrìṣà, wọ́n sì pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, ìyẹn ọmọ Súúsì àti agbẹnusọ fáwọn òrìṣà. (Wo àpótí náà, “Lísírà àti Ìjọsìn Òrìṣà Súúsì àti Hẹ́mísì.”) Àmọ́, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yé àwọn èèyàn náà pé kì í ṣe nípasẹ̀ àṣẹ àwọn òrìṣà wọn làwọn fi ń sọ̀rọ̀ táwọn sì ń ṣiṣẹ́ ìyanu, àmọ́ nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà.​—Ìṣe 14:11-14.

      LÍSÍRÀ ÀTI ÌJỌSÌN ÒRÌṢÀ SÚÚSÌ ÀTI HẸ́MÍSÌ

      Ibi àfonífojì kan tó dá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà tọ́pọ̀ èèyàn máa ń gbà, ni ìlú Lísírà wà. Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì sọ ìlú náà ní Julia Felix Gemina Lustra, ó sì ń ṣàkóso ibẹ̀ láti ìlú Róòmù. Wọ́n yan àwọn ọmọ ogun ìlú yìí pé kí wọ́n máa dáàbò bo ìpínlẹ̀ Gálátíà lọwọ́ àwọn ẹ̀yà tó wà láàárín àwọn òkè ńlá. Òfin táwọn ará Róòmù gbé kalẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣàkóso ìlú náà, inú èdè Látìn ni wọ́n sì ti mú orúkọ oyè tí wọ́n fi ń pe àwọn aláṣẹ ibẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ará Lísírà ò fi ọ̀pọ̀ lára àwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ èdè Látìn, èdè Likaóníà ni wọ́n ń sọ. Kódà, èdè yìí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa wọn ń sọ.

      Lára àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí lágbègbè Lísírà àtijọ́ ni àwọn àkọsílẹ̀ kan tó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àlùfáà Súúsì” àti ère òrìṣà Hẹ́mísì. Bákan náà, wọ́n rí pẹpẹ kan tí wọ́n ṣe fún Súúsì àti Hẹ́mísì lágbègbè yẹn.

      Akéwì ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Ovid (tó gbé ayé láàárín ọdún 43 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 17 Sànmánì Kristẹni) kọ ìtàn àtẹnudẹ́nu kan, tó lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn nǹkan tí ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ọ̀gbẹ́ni Ovid sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí wọ́n sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sí òrìṣà àwọn ará Róòmù náà Jupiter àti Mercury tí wọ́n ń pè ní Súúsì àti Hẹ́mísì lédè Gíríìkì. Ọ̀gbẹ́ni Ovid sọ pé, nígbà kan, Jupiter àti Mercury ṣèbẹ̀wò sí ìlú olókè kan tó ń jẹ́ Fíríjíà, wọ́n fara hàn bí èèyàn. Wọ́n lọ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé bóyá wọ́n máa rí ẹni tó máa gbà wọ́n lálejò, àmọ́ wọn ò rí. Tọkọtaya àgbàlagbà kan tí wọ́n ń jẹ́ Philemon àti Baucis nìkan ló gbà wọ́n sínú ilé wọn tí ò jù kékeré lọ. Torí náà, Súúsì àti Hẹ́mísì sọ ilé yẹn di tẹ́ńpìlì tí wọ́n fi mábù àti wúrà kọ́, wọ́n sì fi tọkọtaya yẹn ṣe bàbálóòṣà àti ìyálóòṣà. Wọ́n wá pa gbogbo ilé àwọn tí kò gbà wọ́n sílé run. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìwé Ìṣe, ìyẹn The Book of Acts in Its Graeco-Roman Setting sọ pé: “Táwọn ará Lísírà bá rántí ìtàn àtẹnudẹ́nu yìí nígbà tí wọ́n rí i tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà mú ọkùnrin arọ kan lára dá, ó dájú pé wọ́n á fẹ́ rúbọ láti kí wọn káàbọ̀.”

      Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò fẹ́ káwọn ará ìlú Lísírà júbà àwọn. Àwọn èèyàn náà ń kọrin, wọ́n gbé ẹbọ kalẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba fáwọn ọkùnrin méjì náà.

      “Ẹ . . . yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.”​—Ìṣe 14:15

      11-13. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ fáwọn ará ìlú Lísírà? (b) Kí ni ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú ohun tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ?

      11 Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣì rí i pé àwọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó wọ àwọn olùgbọ́ àwọn lọ́kàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ tí Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ká rí ọ̀nà tó dáa gan-an láti wàásù ìhìn rere fáwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Kíyè sí bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe pàrọwà fáwọn èèyàn náà. Wọ́n ní: “Ẹ̀yin èèyàn, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Èèyàn bíi tiyín ni wá, àwa náà ní àwọn àìlera tí ẹ ní. Ìhìn rere ni à ń kéde fún yín, kí ẹ lè yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn. Ní àwọn ìran tó ti kọjá, ó gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa ṣe bó ṣe wù wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”​—Ìṣe 14:15-17.

      12 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kò sọ̀rọ̀ bí ẹni pé àwọn sàn ju àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ wọn lọ. Wọn ò ṣe bíi pé ẹ̀dá àràmàǹdà kan làwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n gbà pé àwọn ní àìlera kan náà bíi tàwọn kèfèrí tó ń gbọ́rọ̀ wọn. Òótọ́ ni pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ti dòmìnira kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ èké. Bákan náà, wọ́n tún nírètí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi. Àmọ́, wọ́n mọ̀ pé àwọn ará Lísírà náà lè gba irú ẹ̀bùn yìí tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Kristi.

      13 Kí lèrò tiwa náà nípa àwọn tá à ń wàásù fún? Ṣé a gbà pé a ò sàn jù wọ́n lọ? Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, ṣé àwa náà kì í gbé ara wa lárugẹ? Àpẹẹrẹ tó dáa ni Arákùnrin Charles Taze Russell fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àgbà olùkọ́ ni, òun ló sì ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní nǹkan bí ọdún 1870 sí 1916. Ó kọ̀wé pé: “A ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa júbà wa tàbí àwọn ìwé wa, a ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè wá ní Ẹni Ọ̀wọ̀ tàbí Rábì.” Arákùnrin Russell náà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Bákan náà, kì í ṣe torí ká lè gbayì la ṣe ń wàásù, àmọ́ ńṣe la fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè yí pa dà sọ́dọ̀ “Ọlọ́run alààyè.”

      14-16. Kí ni ẹ̀kọ́ kejì àti ìkẹta tá a lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ fáwọn ará ìlú Lísírà?

      14 Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ kejì tá a lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ yìí. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà mọ béèyàn ṣe ń mú ọ̀rọ̀ bá onírúurú èèyàn mu lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó wà ní Íkóníónì yàtọ̀ sáwọn ará ìlú Lísírà tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ àti àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́ o, iṣẹ́ àgbẹ̀ làwọn ará ìlú Lísírà ń ṣe, ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè jẹ́ kéèyàn mọ irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ ló sì wà láyìíká wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìlú náà rẹwà, ilẹ̀ wọn sì ń méso jáde. Torí náà, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lo ohun táwọn èèyàn náà mọ̀ dáadáa láti bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.​—Róòmù 1:19, 20.

      15 Ṣé àwa náà máa ń mú kí ọ̀rọ̀ wa bá onírúurú èèyàn mu lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àgbẹ̀ kan lè gbin irúgbìn kan náà sínú ilẹ̀ bíi mélòó kan, ó ní láti lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti mú kí ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan wà ní sẹpẹ́ fún ohun tó fẹ́ gbìn. Àwọn ilẹ̀ kan lè ti rọ̀ dáadáa, kí wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́ láti gba irúgbìn. Àwọn ilẹ̀ míì sì lè nílò àtúnṣe díẹ̀ sí i. Lọ́nà kan náà, irúgbìn kan náà là ń gbìn, ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ tá a bá dà bíi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, àá máa gbìyànjú láti fòye mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tá à ń wàásù fún àti ẹ̀sìn wọn. Àá wá lo ohun tá a mọ̀ yìí láti pinnu ọ̀nà tó yẹ ká gbà wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn.​—Lúùkù 8:11, 15.

      16 Ẹ̀kọ́ kẹta tá a lè rí kọ́ látinú ìtàn Pọ́ọ̀lù, Bánábà àtàwọn ará ìlú Lísírà ni pé, bó ti wù ká gbìyànjú tó, Èṣù lè já irúgbìn náà gbà nígbà míì tàbí kó bọ́ sórí àpáta. (Mát. 13:18-21) Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, má rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Róòmù létí pé, “kálukú wa [àtàwọn tá à ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún] ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”​—Róòmù 14:12.

      “Wọ́n . . . Fà Wọ́n Lé Jèhófà Lọ́wọ́” (Ìṣe 14:20-28)

      17. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kúrò ní Déébè, ibo ni wọ́n lọ, kí sì nìdí?

      17 Lẹ́yìn tí wọ́n wọ́ Pọ́ọ̀lù sẹ́yìn òde ìlú Lísírà nígbà tí wọ́n rò pé ó ti kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó sì dìde, ó sì sun ìlú ńlá náà mọ́jú. Lọ́jọ́ kejì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rìnrìn àjò ọgọ́rùn-ún (100) kìlómítà lọ sílùú Déébè. Ẹ wo bí ìrora Pọ́ọ̀lù á ṣe pọ̀ tó nígbà tó ń rìnrìn àjò yẹn, ẹni tó jẹ́ pé wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n sọ ọ́ lókùúta. Síbẹ̀, òun àti Bánábà forí tì í, nígbà tí wọ́n sì dé ìlú Déébè, wọ́n sọ “àwọn díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn.” Lẹ́yìn náà, dípò kí wọ́n pa dà lọ síbi tí wọ́n máa ń dé sí ní Áńtíókù ti Síríà tí kò jìn sílùú Déébè, “wọ́n pa dà sí Lísírà, Íkóníónì àti Áńtíókù [ti Písídíà.]” Kí nìdí tí wọ́n fi lọ síbẹ̀? Wọ́n fẹ́ lọ “fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun,” kí wọ́n sì “fún wọn ní ìṣírí láti má ṣe kúrò nínú ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 14:20-22) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere làwọn ọkùnrin méjì yìí fi lélẹ̀! Ọ̀rọ̀ ìjọ jẹ wọ́n lógún ju ìrọ̀rùn ara wọn lọ. Àpẹ̀ẹ̀rẹ wọn làwọn alábòójútó àyíká àtàwọn míṣọ́nnárì òdé òní ń tẹ̀ lé.

      18. Kí ni ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ń ṣe kí wọ́n tó dámọ̀ràn pé kí arákùnrin kan di alàgbà?

      18 Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ wọn, wọ́n tún yan “àwọn alàgbà fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé “ẹ̀mí mímọ́” ló rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jáde láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, síbẹ̀ wọ́n gbàdúrà wọ́n sì gbààwẹ̀ nígbà tí wọ́n “fà wọ́n [àwọn alàgbà] lé Jèhófà lọ́wọ́.” (Ìṣe 13:1-4; 14:23) Ohun táwa náà ń ṣe lóde òní nìyẹn. Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tó dámọ̀ràn pé kí wọ́n yan arákùnrin kan láti di alàgbà nínú ìjọ, wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n sì máa ń wò ó bóyá arákùnrin náà kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. (1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Kì í ṣe ìgbà tí arákùnrin náà di Kristẹni ni wọ́n máa fi pinnu bóyá ó kúnjú ìwọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀, ìwà ẹ̀ àti irú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí ló máa fi hàn bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ tó nígbèésí ayé ẹ̀. Bí arákùnrin náà bá kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alábòójútó, èyí ló máa fi hàn pé ó yẹ lẹ́ni tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.​—Gál. 5:22, 23.

      19. Ta ni àwọn alàgbà máa jíhìn fún, báwo sì ni wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà?

      19 Àwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa bí wọ́n ṣe ń bójú tó ìjọ. (Héb. 13:17) Àwọn alàgbà máa ń fìtara wàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Wọ́n máa ń fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lókun nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Wọ́n sì máa ń bójú tó ìjọ tinútinú, kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún wọn.​—Fílí. 2:3, 4.

      20. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ka ìtàn àwọn ará wa tí wọ́n ń fòótọ́ ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

      20 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pa dà sí Áńtíókù ti Síríà, ìyẹn ibi tí wọ́n máa ń dé sí lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn, “wọ́n ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn àti pé ó ti ṣí ilẹ̀kùn fún àwọn orílẹ̀-èdè láti di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 14:27) Bá a ṣe ń ka ìtàn àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tá a sì ń rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ kíṣẹ́ wọn so èso rere, èyí ń fún wa níṣìírí ká lè máa “fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà.”

      a Wo àpótí náà, “Íkóníónì​—Ìlú Àwọn Ará Fíríjíà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́