-
Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Lo Fi Ń Wò Ó?‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
16. Ìlànà inú Bíbélì wo ló jẹ mọ́ oyún ṣíṣẹ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
16 Ẹ̀mí àwọn ọmọ inú oyún pàápàá ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Láyé ọjọ́un, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni tó bá ta lu aláboyún tí aláboyún náà tàbí ọmọ rẹ̀ sì kú ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, ó ti di apààyàn, ẹ̀mí ara ẹ̀ ló sì máa fi dí i, ìyẹn ló túmọ̀ sí “ọkàn fún ọkàn.”c (Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23) O lè wá fojú yàwòrán bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá rí báwọn èèyàn ṣe ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye oyún dà nù lọ́dọọdún, bóyá nítorí pé wọn ò tíì nílò wọn báyìí tàbí bóyá nítorí ìwà ìṣekúṣe tó ti jàrábà wọn.
-
-
Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Lo Fi Ń Wò Ó?‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
c Àwọn tó ń ṣèwádìí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù yìí “jẹ́ kó hàn kedere pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣíṣé aláboyún léṣe nìkan lọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.” Ẹ máà tún gbàgbé pé Bíbélì ò sọ bí oyún náà ṣe gbọ́dọ̀ dàgbà tó kẹ́ni tó jẹ́ kó wálẹ̀ tó lè rí ìdájọ́ mímúná Jèhófà.
-