-
“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”Ilé Ìṣọ́—2010 | October 15
-
-
13. Báwo ni níní òye nípa ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
13 Tá a bá mọ ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó dà bíi pé ó ṣòro láti lóye. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ère ọmọ màlúù kan yẹ̀ wò. Ọlọ́run sọ pé: “Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn yìí, sì kíyè sí i, ọlọ́rùn-líle ènìyàn ni wọ́n. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́ mi, kí ìbínú mi lè ru sí wọn, kí n lè pa wọ́n run pátápátá, kí o sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”—Ẹ́kís. 32:9, 10.
14. Kí ni Mósè ṣe nípa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún un?
14 Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó wí pé: ‘Jèhófà, èé ṣe tí ìbínú rẹ yóò fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ tí o fi agbára ńlá àti ọwọ́ líle mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì? Èé ṣe tí àwọn ará Íjíbítì yóò fi wí pe, “Ète ibi ni ó fi mú wọn jáde kí ó lè pa wọ́n láàárín àwọn òkè ńlá, kí ó sì lè pa wọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀”? Yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ jíjófòfò, kí o sì pèrò dà ní ti ibi sí àwọn ènìyàn rẹ. Rántí Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí o fi ara rẹ búra fún, ní ti pé, o wí fún wọn pé, “Èmi yóò sọ irú-ọmọ yín di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gbogbo ilẹ̀ yìí tí mo sì ti tọ́ka sí ni èmi yóò fi fún irú-ọmọ yín, kí wọ́n lè gbà á fún àkókò tí ó lọ kánrin.”’ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pèrò dà ní ti ibi tí ó sọ pé òun fẹ́ ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Ẹ́kís. 32:11-14.a
15, 16. (a) Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fún Mósè látàrí ohun tí Jèhófà sọ? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “pèrò dà”?
15 Ǹjẹ́ Mósè tiẹ̀ ní láti yí Jèhófà lérò pa dà? Rárá o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà sọ ohun tó wù ú láti ṣe, síbẹ̀ ohun tó sọ yẹn kọ́ ni abẹ gé. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni Jèhófà ń dán Mósè wò, bí Jésù ṣe wá ṣe fún Fílípì àti obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì nígbà tó yá. Ọlọ́run yọ̀ǹda fún Mósè láti sọ èrò rẹ̀ jáde.b Jèhófà ti yan Mósè gẹ́gẹ́ bí alárinà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Òun fúnra rẹ̀, Jèhófà kò sì fojú kékeré wo yíyàn tó yan Mósè sí ipò yẹn. Ǹjẹ́ Mósè á ṣe ohun tí kò tọ́ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì já a kulẹ̀. Ǹjẹ́ Mósè á lo àǹfààní yẹn láti rọ Jèhófà pé kó pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tì, kó sì sọ àwọn àtọmọdọ́mọ òun di orílẹ̀-èdè ńlá?
-
-
“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”Ilé Ìṣọ́—2010 | October 15
-
-
b Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, àkànlò èdè Hébérù tá a túmọ̀ sí “jọ̀wọ́ mi” nínú Ẹ́kísódù 32:10 la lè wò ó gẹ́gẹ́ bí ìkésíni, ìyẹn ni pé kí Ọlọ́run gba Mósè láyè láti bá wọn bẹ̀bẹ̀, tàbí ‘kí ó dúró sí àlàfo,’ tó wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè náà. (Sm. 106:23; Ìsík. 22:30) Ohun yòówù kí ọ̀rọ̀ náà jẹ́, ará rọ Mósè láti sọ èrò rẹ̀ jáde fàlàlà fún Jèhófà.
-