Fi Hàn Pé O Bìkítà
Láti ọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní Kánádà
Ṣíṣàìnáání ọ̀pọ̀ arúgbó ló ń mú kí wọ́n máa pa ara wọn gan-an ní Kánádà. A ka ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Vancouver Sun pé, nígbà tó jẹ́ pé ọ̀kan lára igba ọ̀dọ́ tó gbìyànjú àtipa ara wọn ló máa ń kú, ọ̀kan nínú mẹ́rin ni ti àwọn tí ọjọ́ orí wọn lé ní márùnlélọ́gọ́ta. Òtítọ́ sì ni pé “ìròyìn kò sọ bí àwọn arúgbó ṣe ń pa ara wọn tó, nítorí pé ó lè ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín òun àti ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ tí àwọn arúgbó tí wọ́n ní ìṣòro ìlera lílekoko ń kú.”
Kí ló wá fà á tí ayé fi ń sú ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó? Oníṣègùn ọpọlọ ní Yunifásítì British Columbia, Olúwáfẹ́mi Àgbàyẹwá, tó jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn àwọn arúgbó tí ń pa ara wọn, tọ́ka sí ìsoríkọ́, àìbá ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ṣe, àti ìdáwà bí ohun tí ń dá kún un. Gerry Harrington, olùdarí Ibùdó Ìsọfúnni àti Ìlanilóye Nípa Ọ̀ràn Ìpara-Ẹni ní Calgary, Alberta, sọ pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń darúgbó sí i ni wọ́n “ń pàdánù ọ̀wọ́ wọn, agbára wọn, agbára ìdarí wọn. . . . Lójijì, kò sí ẹni tó tún ń béèrè fún èrò wọn mọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń bá ara wọn ní ilé ìtọ́jú arúgbó, tí kò sì sí ohun tí wọ́n ń ṣe ju kí wọ́n máa ta káàdì kí wọ́n sì máa wo tẹlifíṣọ̀n.” Ohun tó tún ń mú kí ọ̀ràn yìí burú sí i ni pé ohun tí àwùjọ òde òní kà sí pàtàkì ni àwọn èwe, òmìnira, ohun tí a lè ṣe, àti bí a ṣe lè yára ṣe nǹkan—àwọn ànímọ́ tí ń dín kù bí a ti ń darúgbó.
Ṣùgbọ́n, lójú Jèhófà Ọlọ́run àwọn arúgbó ṣe pàtàkì gan-an. A lè rí ẹ̀rí pé ó lóye àìní wọn ní ti ìmọ̀lára nínú àṣẹ tó pa fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.”—Léfítíkù 19:32.
Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè wá “fi ìgbatẹnirò hàn” fún àwọn arúgbó? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n lè máà jáde lẹ́nu wọn léraléra tí ọjọ́ ogbó sì lè túbọ̀ mú kí a rí àìpé wọn, ó tọ́ kí a bọ̀wọ̀ fún wọn. Fi hàn pé o bìkítà nípa wọn. Fi iyì, ọlá, hàn sí wọn, kí o sì fi wọ́n pè nípa kíkọ́ lára ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n wọn, pàápàá tí wọ́n bá fi ẹ̀mí Ọlọ́run àti òye pípé nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe atọ́nà ìgbésí ayé wọn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa ní púpọ̀ nǹkan sí i lórí ọ̀ràn títọ́jú àwọn arúgbó àti bíbọlá fún wọn. Láti rí ìsọfúnni sí i, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí, kí o sì béèrè bí o ṣe lè rí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé gbà.