ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́—2011 | July 1
    • Síwájú sí i, ohun tí Bíbélì sọ pé kò sí ohun tó gbé ayé dúró mú kéèyàn béèrè ìbéèrè míì pé: Kí ló mú kí ayé àtàwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run máa tọ òpó ọ̀nà wọn tí wọ́n kò yà gba ibòmíràn? Kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Ọlọ́run fi béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jóòbù, ó ní: “Ìwọ ha lè so àwọn ìdè àgbájọ ìràwọ̀ Kímà pinpin, tàbí ìwọ ha lè tú àní àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?” (Jóòbù 38:31) Ní alaalẹ́, ní gbogbo ìgbésí ayé Jóòbù, ó máa ń rí àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n jọra wọn, tí wọ́n máa ń yọ, tí wọ́n sì máa ń wọ̀.c Àmọ́, kí nìdí tí àwọn ìràwọ̀ yẹn fi jọ ara wọn, tí wọn kò sì yàtọ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún, àní fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá? Ìdè wo ló so àwọn ìràwọ̀ yẹn àtàwọn nǹkan míì tó wà lójú ọ̀run sí àyè wọn? Ó dájú pé, ohun àgbàyanu ló máa jẹ́ lójú Jóòbù bó ti ń ronú nípa nǹkan wọ̀nyẹn.

      Àwọn ìdè wọ̀nyẹn kò ní wúlò tó bá jẹ́ pé ara àwọn àgbá kan tí Aristotle sọ pé ó wà lọ́run ni àwọn ìràwọ̀ so rọ̀ sí. Ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wá mọ̀ sí i nípa “àwọn ìdè” tàbí “àwọn okùn” tí a kò lè fojú rí tó so àwọn ìràwọ̀ mọ́ra wọn bí wọ́n ti ń lọ lójú sánmà. Ọ̀gbẹ́ni Isaac Newton àti Albert Einstein di olókìkí nítorí ohun tí wọ́n ṣàwárí nípa ojú ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kò mọ ohunkóhun nípa ohun tí Ọlọ́run fi so àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run pọ̀. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé Jóòbù ti jẹ́ òótọ́ fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún, ó sì wúlò fíìfíì ju èrò ọ̀mọ̀wé Aristotle lọ. Ta ló lè ní irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe Ẹni tó ṣe òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run?

  • Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́—2011 | July 1
    • c Ó lè jẹ́ àwùjọ ìràwọ̀ Pleiades ló ń jẹ́ “àgbájọ ìràwọ̀ Kímà.” Ó lè jẹ́ pé àgbájọ ìràwọ̀ Orion ló ń jẹ́ “àgbájọ ìràwọ̀ Késílì.” Ó máa tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kí ìrísí àwọn ìràwọ̀ náà tó lè yí pa dà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́