-
Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?Ilé Ìṣọ́—2011 | May 15
-
-
7, 8. Àwọn àdánwò wo ló dé bá Jóòbù, kí ni bó ṣe fi ìṣòtítọ́ fara dà á sì fi hàn?
7 Jèhófà fàyè gba Sátánì láti mú ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìjábá dé bá Jóòbù, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. (Jóòbù 1:12-19) Báwo ni ìyípadà tó dé bá Jóòbù yìí ṣe rí lára rẹ̀? Bíbélì sọ fún wa pé “kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.” (Jóòbù 1:22) Síbẹ̀, Sátánì kò dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. Ó tún ṣàròyé síwájú sí i pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.”a (Jóòbù 2:4) Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù pé bí ọwọ́ ìyà bá tó o, ó máa pinnu pé kì í ṣe Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé òun.
-
-
Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?Ilé Ìṣọ́—2011 | May 15
-
-
a Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lérò pé gbólóhùn náà “awọ fún awọ” lè túmọ̀ sí pé Jóòbù kò ní bìkítà bí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹran rẹ̀ bá pàdánù ẹran ara wọn, tàbí ìwàláàyè wọn, bí ohunkóhun kò bá ṣáà ti ṣẹlẹ̀ sí ẹran ara, tàbí ìwàláàyè tirẹ̀. Àwọn mìíràn lérò pé ńṣe ni gbólóhùn náà ń tẹnu mọ́ ọn pé ẹnì kan á múra tán láti pàdánù díẹ̀ lára ẹran ara rẹ̀ bó bá jẹ́ pé ọ̀nà tó fi lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá fẹ́ fi ohun kan gbá ẹnì kan lórí, ó lè na apá rẹ̀ sókè láti fi gba nǹkan náà dúró, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù díẹ̀ lára awọ apá rẹ̀ kó lè dáàbò bo awọ orí rẹ̀. Ohun yòówù kí àkànlò èdè náà túmọ̀ sí, ó ṣe kedere pé ohun tó ń sọ ni pé inú Jóòbù máa dùn láti pàdánù gbogbo ohun tó ní kó lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
-