-
Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn WaIlé Ìṣọ́—2005 | November 1
-
-
“Èmi Kò Bẹ̀rù Ohun Búburú Kankan, Nítorí Tí Ìwọ Wà Pẹ̀lú Mi”
13. Báwo ni Dáfídì ṣe sọ̀rọ̀ nínú Sáàmù 23:4, tó fi hàn pé ó sún mọ́ Jèhófà gan-an, kí sì nìdí tí èyí kò fi yà wá lẹ́nu?
13 Dáfídì sọ ìdí kejì tó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ó ní: Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. A kà á pé: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.” (Sáàmù 23:4) Dáfídì wá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó sún mọ́ Jèhófà gan-an, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìwọ” fún Jèhófà. Èyí kò yà wá lẹ́nu nítorí pé ńṣe ni Dáfídì ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìpọ́njú. Dáfídì ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu kọjá, ìyẹn ni pé àwọn àkókò kan wà tí ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ wà nínú ewu. Àmọ́ kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí òun, nítorí ó mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú òun, “ọ̀pá” Rẹ̀ àti “ọ̀pá ìdaran” Rẹ̀ sì wá ní sẹpẹ́. Mímọ̀ tí Dáfídì mọ̀ nípa ààbò yìí tù ú nínú gan-an, ó sì dájú pé ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa.b
14. Báwo ni Bíbélì ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà á dáàbò bò wá, àmọ́ kí ni èyí kò túmọ̀ sí?
14 Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀ lónìí? Bíbélì mú un dá wa lójú pé kò sí alátakò kankan, ì báà jẹ́ ẹ̀mí èṣù tàbí èèyàn, tí yóò lè pa àwọn àgùntàn Ọlọ́run rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà kò ní fàyè gba ìyẹn láé. (Aísáyà 54:17; 2 Pétérù 2:9) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Olùṣọ́ Àgùntàn wa yóò gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ewu o. Àwa náà máa ń kojú àdánwò tó máa ń bá gbogbo èèyàn, a sì ń dojú kọ àtakò táwọn èèyàn máa ń ṣe sí gbogbo Kristẹni tòótọ́. (2 Tímótì 3:12; Jákọ́bù 1:2) Àwọn àkókò kan wà tá a lè máa “rìn ní àfonífojì ibú òjìji.” Bí àpẹẹrẹ, ikú lè fẹjú mọ́ wa nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa tàbí nígbà tá a bá ń ṣàìsàn. Ẹnì kan tó sún mọ́ wa gan-an lè wà ní bèbè ikú tàbí kó tiẹ̀ kú pàápàá. Ní irú àkókò tí nǹkan le gan-an fún wa yẹn, Olùṣọ́ Àgùntàn wa wà pẹ̀lú wa, yóò sì dáàbò bò wá. Lọ́nà wo?
15, 16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó lè dojú kọ wá? (b) Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ lásìkò àdánwò.
15 Jèhófà ò ṣèlérí pé òun á máa dá sí ọ̀ràn wa lọ́nà ìyanu.c Àmọ́ a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí ohunkóhun tó bá fẹ́ jẹ́ ìdènà fún wa. Ó lè fún wa ní ọgbọ́n láti fara da “onírúurú àdánwò.” (Jákọ́bù 1:2-5) Kì í ṣe pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń fi ọ̀pá tàbí ọ̀pá ìdaran rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá sẹ́yìn nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń lò ó láti rọra darí àwọn àgùntàn rẹ̀ sí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà. Jèhófà lè “rọra darí” wa, bóyá nípasẹ̀ ẹnì kan tá a jọ jẹ́ olùjọsìn rẹ̀, ká lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì sílò, èyí tó lè ṣèrànwọ́ gan-an nínú ipò tá a bá wa. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà lè fún wa lókun láti ní ìfaradà. (Fílípì 4:13) Ó lè tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tí Sátánì lè mú bá wa. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà múra tán láti ràn wá lọ́wọ́?
16 Dájúdájú, bó ti wù kí àfonífojì tá a bára wa ṣókùnkùn tó, a ò ní láti dá nìkan rìn ín. Olùṣọ́ Àgùntàn wa wà pẹ̀lú wa, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tá a lè má tètè kíyè sí. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà yẹ̀ wò, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fún un fi hàn pé kókó kan tó lè ṣekú pa á wà nínú ọpọlọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé bóyá Jèhófà ń bínú sí mi ni tàbí bóyá kò nífẹ̀ẹ́ mi. Àmọ́ mo wá pinnu pé mi ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Dípò ìyẹn, ńṣe ni mo sọ gbogbo ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn mi fún un. Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń tù mí nínú nípasẹ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Ọ̀pọ̀ ló sọ ohun tójú àwọn fúnra wọn ti rí fún mi, tí wọ́n sì jẹ́ kí n mọ báwọn náà ṣe borí àìsàn líle. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ kí n mọ̀ pé ohun tó ń ṣe mi kì í ṣe ohun tójú ò rí rí. Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún mi, títí kan inú rere tí wọ́n fi hàn sí mi túbọ̀ mú un dá mi lójú pé kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sí mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ò tíì fi mí sílẹ̀, tí mi ò sì mọ ibi tó máa já sí, síbẹ̀ ó dá mi lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi, yóò sì máa bá a lọ láti ràn mí lọ́wọ́ jálẹ̀ àkókò àdánwò mi yìí.”
-