“Ṣaaju Awọn Oke-nla”
“IWỌ ti jẹ́ ibi gbígbé wa jalẹ gbogbo awọn iran. Ṣaaju ki a tó bi awọn oke-nla tabi ki o tó mú ilẹ̀-ayé ati ayé jade wá, lati ainipẹkun de ainipẹkun iwọ ni Ọlọrun.” (Orin Dafidi 90:1, 2, New International Version) Awọn ọ̀rọ̀ wọnni ni a dari si Ẹlẹdaa wa, wọn sì ti jẹ́ atuni-ninu tó—ni pataki lonii, nigba ti ó dabi pe kò sí ohunkohun ti o duro sojukan!
Ninu ipo iṣunna-owo ti ń bajẹ sii, awọn diẹ ni wọn ni igbọkanle nipa ọjọ-ọla. Ibisi ninu iwa-ọdaran ati ilokulo oogun ti ń dáyàfoni ti yí awọn ilu-nla kan pada si agbegbe ogun. Àní eto-idasilẹ atọjọmọjọ yẹn paapaa, idile, ti ń wópalẹ̀. A ń gbọ́ iru awọn ohun ti wọn jẹ́ titun bẹẹ bi idile abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Awọn idile anìkàntọ́mọ ń pọ sii ni iye, nibi ti òbí kan ti sábà maa ń fàyà rán idaamu ńláǹlà. Alaafia ọpọlọpọ idile ni a ń fọ́ yángá nipa iru awọn ohun ìríra bẹẹ, bii nína olubaṣegbeyawo-ẹni ati lilo ọmọ ni ilokulo.
Ta ni yoo dari wa la awọn akoko lilekoko wọnyi já? Ó dara, a kò ṣalaini imọran ti o pọ̀ tó lati ọ̀dọ̀ awọn afiṣemọronu-ẹda, olùkọ́ni, ati awọn miiran, ṣugbọn ọpọ julọ ninu rẹ̀ ni ó ń takora. Fun gbogbo sáà akoko iran kan ni apa Iwọ-oorun, Dokita Benjamin Spock ni olugbaninimọran ti ó gba ipo iwaju julọ ninu ọ̀ràn ẹkọ awọn ọmọde. Nigba naa ó gbà pe amọran oun ti jẹ́ aṣiṣe!
Ó ti bọgbọn mu julọ tó lati ní Ọlọrun gẹgẹ bi “ibi gbigbe” wa! Ni awọn akoko onírúgúdù wọnyi, oun ni apata iduro-gbọnyingbọnyin, ti o ti ń wà “lati ainipẹkun de ainipẹkun.” Ó sọ nipa araarẹ̀ nipasẹ wolii Malaki pe: “Emi ni Oluwa, emi kò yipada.” (Malaki 3:6) Awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun, gẹgẹ bi a ṣe ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli, ṣee gbarale patapata. Oun ti wà “ṣaaju awọn oke-nla,” imọran rẹ̀, ti ó sì wà larọọwọto ninu Iwe Mimọ, ni a gbekari ọgbọn ayeraye rẹ̀. Oun gan-an ni ohun ti a nilo fun ayọ ati aṣeyọri.
Ó bọgbọnmu, nigba naa, lati ni igbọkanle ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Kẹkọọ rẹ̀ lati janfaani lati inu ọgbọn Ọlọrun. Ni igbẹkẹle ninu ohun ti o kọ́, ki o sì jẹ ki ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ lati tọ́ ọ loju ọ̀nà igbesi-aye. (Orin Dafidi 119:105) Kìkì awọn wọnni ti wọn bá ṣe bẹẹ ni wọn ni idi lati ni igbọkanle ti wọn sì ní ojulowo alaafia ọkàn ninu ọjọ-ọla.