ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Wọ́n Ń gbèrú Nígbà Orí Ewú’
    Ilé Ìṣọ́—2007 | September 15
    • ‘Wọ́n Ń gbèrú Nígbà Orí Ewú’

      Ọ̀PỌ̀ àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà lágbègbè Òkun Mẹditaréníà ló ń gbin ọ̀pẹ déètì sí àgbàlá wọn. Igi ẹlẹ́wà ni ọ̀pẹ déètì yìí jẹ́, èso rẹ̀ sì máa ń dùn gan-an ni. Yàtọ̀ síyẹn, ó rọ́kú, ó sì máa ń so èso fún èyí tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ.

  • ‘Wọ́n Ń gbèrú Nígbà Orí Ewú’
    Ilé Ìṣọ́—2007 | September 15
    • Àmọ́, àwọn arẹwà obìnrin nìkan kọ́ ni wọ́n fi ń wé igi ọ̀pẹ o. Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ; gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá. Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà, nínú àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa, wọn yóò yọ ìtànná. Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀.”—Sáàmù 92:12-14.

      Ọ̀pọ̀ ọ̀nà làwọn tó ti dàgbà àmọ́ ti wọ́n ṣì ń fi ìṣòtítọ́ bá ìjọsìn Ọlọ́run nìṣó fi dà bí igi ọ̀pẹ ẹlẹ́wà yìí. Bíbélì ní: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Lóòótọ́, ara wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán mọ́ nítorí pé àgbà ti dé, síbẹ̀ wọ́n ṣì lè jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí bí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń fúnni lókun àti agbára. (Sáàmù 1:1-3; Jeremáyà 17:7, 8) Ọ̀rọ̀ alárinrin tó máa ń tẹnu àwọn àgbà jáde àti àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n jẹ́ máa ń fún àwọn èèyàn níṣìírí gan-an, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ méso jáde látọdún dé ọdún. (Títù 2:2-5; Hébérù 13:15, 16) Dájúdájú, àwọn àgbàlagbà lè máa méso jáde bí igi ọ̀pẹ lọ́jọ́ ogbó wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́