ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Ní Àkókò Àwọn Aposteli
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | May 15
    • Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Ní Àkókò Àwọn Aposteli

      “Ìmọ́lẹ̀ fúnra rẹ̀ ti bùyẹ̀rì fún àwọn olódodo, àní ìhó-ayọ̀ pàápàá fún àwọn ọlọ́kàn-àyà dídúró ṣánṣán.”—ORIN DAFIDI 97:11, NW.

      1. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí ṣe farajọ àwọn Kristian ìjímìjí?

      ẸWO bí àwa, gẹ́gẹ́ bí Kristian tòótọ́, ṣe mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 97:11 yìí tó! ‘Ìmọ́lẹ̀ ti bùyẹ̀rì’ fún wa léraléra. Níti tòótọ́, àwọn kan lára wa ti rí ìmọ́lẹ̀ Jehofa tí ń bùyẹ̀rì fún àwọn ẹ̀wádún. Gbogbo èyí rán wa létí Owe 4:18, tí ó kà pé: “Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.” Nítorí a mọrírì Ìwé Mímọ́ ju àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lọ, àwa Ẹlẹ́rìí Jehofa dàbíi àwọn Kristian ìjímìjí. A lè rí ìhùwàsí wọn kedere nínú àwọn ìwé ìtàn ti Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki àti láti inú àwọn lẹ́tà rẹ̀, tí a kọ lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá.

      2. Àwọn ohun wo ni ó wà lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu rí gbà?

      2 Lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi ní ìjímìjí kọ́kọ́ rí gbà ni àwọn wọnnì tí ó níí ṣe pẹ̀lú Messia náà. Anderu sọ fún Simoni Peteru arákùnrin rẹ̀ pé: “Awa ti rí Messia naa.” (Johannu 1:41) Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, Bàbá tí ń bẹ ní ọ̀run mú kí ó ṣeé ṣe fún aposteli Peteru láti jẹ́rìí sí i ní ọ̀nà tí ó bá ojú-ìwòye yẹn mu nígbà tí ó sọ fún Jesu Kristi pé: “Iwọ ni Kristi naa, Ọmọkùnrin Ọlọrun alààyè.”—Matteu 16:16, 17; Johannu 6:68, 69.

      Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Níí Ṣe Pẹ̀lú Iṣẹ́ Ìwàásù Tí A Paláṣẹ fún Wọn

      3, 4. Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ìlàlóye wo ni Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ọjọ́-ọ̀la wọn?

      3 Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jesu Kristi fúnni ní àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tí ó já lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ léjìká. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn 500 ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n péjọ ní Galili ni ó sọ fún pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹlu yín ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 28:19, 20; 1 Korinti 15:6) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ di oníwàásù, iṣẹ́ ìwàásù tí a paláṣẹ fún wọn kò sì gbọ́dọ̀ mọ sọ́dọ̀ “awọn àgùtàn ilé Israeli tí wọ́n sọnù.” (Matteu 10:6) Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò níláti ṣe ìbatisí irú èyí ti Johannu ṣe gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti batisí àwọn ènìyàn “ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́.”

      4 Gẹ́rẹ́ ṣáájú kí Jesu tó gòkè lọ sí ọ̀run, àwọn aposteli rẹ̀ 11 olùṣòtítọ́ béèrè pé: “Oluwa, iwọ ha ń mú ìjọba padàbọ̀sípò fún Israeli ní àkókò yii bí?” Dípò dídáhùn ìbéèrè yẹn, Jesu fún wọn ní ìtọ́ni síwájú síi nípa iṣẹ́ ìwàásù tí a paláṣẹ fún wọn, ní sísọ pé: “Ẹ̀yin yoo gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá dé sórí yín, ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalemu ati ní gbogbo Judea ati Samaria ati títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” Títí di àkókò yẹn, wọ́n ti ń jẹ́rìí nípa Jehofa nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn yóò tún jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Kristi.—Ìṣe 1:6-8.

      5, 6. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí gbà ní Pentekosti?

      5 Ọjọ́ mẹ́wàá péré lẹ́yìn náà, ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu rí gbà! Ní ọjọ́ Pentekosti 33 C.E., fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n mọrírì ìjẹ́pàtàkì Joeli 2:28, 29 tí ó sọ pé: “Èmi [Jehofa] óò tú ẹ̀mí mi jáde sí ara ènìyàn gbogbo; àti àwọn ọmọ yin ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yin obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yin yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yin yóò máa ríran. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ obìnrin, ni èmi óò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọnnì.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí ẹ̀mí mímọ́, ní ìrísí ahọ́n bí iná, tí ó bà lé orí gbogbo wọn—nǹkan bí 120 ọkùnrin àti obìnrin—tí wọ́n péjọ ní Jerusalemu.—Ìṣe 1:12-15; 2:1-4.

      6 Bákan náà ní ọjọ́ Pentekosti, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ́kọ́ lóye pé àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 16:10 ń tọ́ka sí Jesu Kristi tí ó ti jíǹde. Onipsalmu náà sọ pé: “Ìwọ [Jehofa Ọlọrun] kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ipò-òkú; bẹ́ẹ̀ni ìwọ kì yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ kí ó rí ìdibàjẹ́.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kò lè máa tọ́ka sí Ọba Dafidi, nítorí pé ibojì rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn títí di ọjọ́ yẹn. Abájọ ti àwọn bíi 3,000 lára àwọn tí wọ́n gbọ́ bí a ṣe ṣàlàyé ìmọ́lẹ̀ titun yìí fi gbàgbọ́ dájú tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe batisí ní ọjọ yẹn gan-an!—Ìṣe 2:14-41.

      7. Ìmọ́lẹ̀ títànyòò wo ni aposteli Peteru rí gbà nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ sọ́dọ̀ Korneliu ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu?

      7 Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn ọmọ Israeli mọrírì ohun tí Ọlọrun sọ nípa wọn pé: “Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé ayé.” (Amosi 3:2) Nítorí náà ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò níti tòótọ́ ni aposteli Peteru àti àwọn wọnnì tí wọ́n bá a lọ sí ilé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu náà Korneliu rí gbà nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn Kèfèrí aláìkọlà aláìgbàgbọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó yẹ fún àfiyèsí pé èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ ṣáájú ìbatisí. Ṣùgbọ́n èyí pọndandan. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Peteru kì bá má ti mọ̀ pé àwọn Kèfèrí aláìkọlà wọ̀nyí tóótun fún ìbatisí. Níwọ̀n bí ó ti mọrírì ìjẹ́pàtàkì ohun mériyìírí yìí, Peteru béèrè pé: “Ẹnikẹ́ni ha lè ka omi léèwọ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kò ní batisí awọn wọnyi [àwọn Kèfèrí] tí wọ́n ti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà àní gẹ́gẹ́ bí awa ti rí i gbà?” Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wà níbẹ̀ tí ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ lòdìsí i, nítorí náà ìbatisí àwọn Kèfèrí wọ̀nyí sì wáyé.—Ìṣe 10:44-48; fiwé Ìṣe 8:14-17.

      Ìkọlà Kò Sí Mọ́

      8. Èéṣe tí ó fi ṣòro fún àwọn kan lára àwọn Kristian ìjímìjí láti pa ẹ̀kọ́ nípa ìkọlà tì?

      8 Ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò síwájú síi ti òtítọ́ jẹyọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbéèrè lórí ìkọlà. Àṣà ìkọlà ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní 1919 B.C.E. pẹ̀lú májẹ̀mú Jehofa pẹ̀lú Abrahamu. Ọlọrun pàṣẹ fún Abrahamu nígbà náà pé òun àti gbogbo ọmọkùnrin mìíràn nínú agbo-ilé rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọlà. (Genesisi 17:9-14, 23-27) Nítorí náà ìkọlà di àmì ìdánimọ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Abrahamu. Ẹ sì wo bí wọ́n ṣe ń fi àṣà yìí yangàn tó! Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, “aláìkọlà” wá di ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. (Isaiah 52:1; 1 Samueli 17:26, 27) Ó rọrùn láti rí ìdí tí àwọn Kristian ìjímìjí kan tí wọ́n jẹ́ Júù ṣe fẹ́ láti jẹ́ kí àmì yìí máa wà títí lọ. Àwọn kan lára wọn ní ìjíròrò púpọ̀ pẹ̀lú Paulu àti Barnaba lórí ọ̀ràn yìí. Láti lè yanjú rẹ̀, Paulu àti àwọn mìíràn lọ sí Jerusalemu láti fi ọ̀ràn náà lọ ẹgbẹ́ olùṣàkóso Kristian.—Ìṣe 15:1, 2.

      9. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni a ṣípayá fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjímìjí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìṣe orí 15.

      9 Nínú ọ̀ràn yìí, kì í ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́-ìyanu híhàn gbangba ni àwọn Kristian ìjímìjí wọ̀nyẹn fi rí ìmọ́lẹ̀ náà gbà pé ìkọlà kì í ṣe ohun tí a béèrè fún mọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gba ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ síi yẹn nípa yíyẹ inú Ìwé Mímọ́ wò, gbígbíyèlé ẹ̀mí mímọ́ fún ìtọ́sọ́nà, àti gbígbọ́ àwọn ìrírí Peteru àti Paulu nípa yíyí àwọn Kèfèrí aláìkọlà lọ́kàn padà. (Ìṣe 15:6-21) Ìpinnu náà ni a gbé jáde nínú lẹ́tà kan tí apákan rẹ̀ kà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ ati awa fúnra wa ti faramọ́ ṣíṣàì tún fi ẹrù-ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi awọn nǹkan pípọndandan wọnyi, lati máa takété sí awọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà ati sí ẹ̀jẹ̀ ati sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa ati sí àgbèrè.” (Ìṣe 15:28, 29) Nípa báyìí a tú àwọn Kristian ìjímìjí sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àṣẹ náà láti kọlà àti kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun mìíràn tí Òfin Mose béèrè fún. Nípa báyìí, Paulu lè sọ fún àwọn Kristian ní Galatia pé: “Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira.”—Galatia 5:1.

      Ìmọ́lẹ̀ Nínú Àwọn Ìròyìnrere

      10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí a ṣípayá nínú Ìròyìnrere Matteu?

      10 Kò sí iyèméjì kankan pé Ìròyìnrere Matteu, tí a kọ ní nǹkan bí 41 C.E., ní ọ̀pọ̀ ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ nínú fún àǹfààní àwọn tí ń kà á. Ìwọ̀nba díẹ̀ ní ìfiwéra lára àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ìnní ti fetí ara wọn gbọ́ bí Jesu ṣe ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní pàtàkì, Ìròyìnrere Matteu tẹnumọ́ ọn pé Ìjọba náà ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu. Ẹ sì wo bí Jesu ṣe fi tagbára tagbára tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ète ìsúnniṣe tí ó tọ̀nà tó! Ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú Ìwàásù rẹ̀ Lorí Òkè, nínú òwe àkàwé rẹ̀ (irú àwọn wọnnì tí a kọsílẹ̀ ní orí 13), àti nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ńláǹlà ní orí 24 àti 25! Gbogbo èyí ni a mú wá sí àfiyèsí àwọn Kristian ìjímìjí nínú àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere Matteu, tí a kọ ní ọdún mẹ́jọ péré lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E.

      11. Kí ni a lè sọ nípa àwọn tí ó wà nínú àwọn Ìròyìnrere Luku àti Marku?

      11 Ní nǹkan bí ọdún 15 lẹ́yìn náà, Luku kọ Ìròyìnrere rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú rẹ̀ farajọ àkọsílẹ̀ Matteu, ìpín 59 nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́ àfikún. Luku ṣàkọsílẹ̀ mẹ́fà nínú àwọn iṣẹ́-ìyanu Jesu àti èyí tí ó ju ìlọ́po méjì ọ̀pọ̀ àkàwé Rẹ̀ tí àwọn akọ̀wé Ìròyìnrere mìíràn kò mẹ́nukàn. Ó hàn gbangba pé ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Marku kọ Ìròyìnrere rẹ̀, tí ó tẹnumọ́ Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí alákíkanjú ọkùnrin, oníṣẹ́ ìyanu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Marku kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Matteu àti Luku ti ṣàkọsílẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó ṣàkọsílẹ̀ òwe àkàwé kan tí àwọn kò mẹ́nukàn. Nínú àpèjúwe yẹn, Jesu fi Ìjọba Ọlọrun wé irúgbìn tí ó hù, tí ó dàgbà, tí ó sì so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.a—Marku 4:26-29.

      12. Dé àyè wo ni Ìròyìnrere Johannu fi pèsè ìlàlóye síwájú síi?

      12 Ìròyìnrere Johannu tún wà níbẹ̀, tí a kọ ní ohun tí ó lè ní 30 ọdún lẹ́yìn tí Marku kọ àkọsílẹ̀ tirẹ̀. Ẹ wo irú ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi tí Johannu tàn sórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu, pàápàá ní pàtàkì nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́ka sí ìwàláàyè Rẹ̀ ṣáájú dídi ènìyàn! Johannu nìkan ni ó pèsè àkọsílẹ̀ àjíǹde Lasaru, òun nìkan ni ó sì fún wa ní ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí àtàtà tí Jesu sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́ àti àdúrà amọ́kànyọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ tí a dà á, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní orí 13 sí 17. Ní tòótọ́, wọ́n sọ pé ìpín 92 nínú ọgọ́rùn-ún Ìròyìnrere Johannu tayọlọ́lá.

      Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Nínú Lẹ́tà Paulu

      13. Èéṣe tí àwọn kan fi wo lẹ́tà Paulu sí àwọn ara Romu gẹ́gẹ́ bíi pé ó jẹ́ ìwé Ìròyìnrere?

      13 A lo aposteli Paulu ní pàtàkì láti mú àwọn ìbùyẹ̀rì òtítọ́ wá fún àwọn Kristian tí wọ́n gbé ní àkókò àwọn aposteli. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́tà Paulu sí àwọn ará Romu wà níbẹ̀, tí ó kọ ní nǹkan bí 56 C.E.—tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àkókò kan náà tí Luku kọ Ìròyìnrere tirẹ̀. Nínú lẹ́tà yìí Paulu tẹnumọ́ òkodoro òtítọ́ náà pé a lè sọ pé a ní ìwà òdodo gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi. Ìtẹnumọ́ Paulu lórí apá ìhìnrere yìí náà ti mú kí àwọn kan fojú wo lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ara Romu gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ Ìròyìnrere karùn-ún.

      14-16. (a) Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn Kristian ní Korinti, ìmọ́lẹ̀ wo ni Paulu tàn sórí àìní náà fún ìṣọ̀kan? (b) Ìmọ́lẹ̀ síwájú síi níti ìṣarasíhùwà wo ni Korinti Kìn-ínní ní nínú?

      14 Paulu kọ̀wé nípa àwọn ọ̀ràn kan tí ó ń kó ìdààmú bá àwọn Kristian ní Korinti. Lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Korinti ní nínú ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí a mí sí tí ó ti ṣàǹfààní fún àwọn Kristian títí di ọjọ́ wa. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó níláti la àwọn ara Korinti lóye nípa àṣìṣe tí wọ́n ń ṣe nípa ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ akésáàfúlà fún àwọn ènìyàn kan ní pàtó. Aposteli náà tún èrò-orí wọn ṣe, ní fífi tìgboyà tìgboyà sọ fún wọn pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, ati pé kí ìpínyà máṣe sí láàárín yín, ṣugbọn kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.”—1 Korinti 1:10-15.

      15 A ti fàyègba ìwà pálapàla tí ó burú lékenkà ní ìjọ Kristian ní Korinti. Ọkùnrin kan níbẹ̀ ti gba aya bàbá rẹ̀, tí ó sì tipa báyìí ṣe ‘irúfẹ́ àgbèrè tí a kò tilẹ̀ rí láàárín awọn orílẹ̀-èdè.’ Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú naa kúrò láàárín ara yín.” (1 Korinti 5:1, 11-13) Ohun titun kan ni ìyẹn jẹ́ fún ìjọ Kristian nígbà náà lọ́hùn-ún—ìyọlẹ́gbẹ́. Ọ̀ràn mìíràn tí ìjọ Korinti nílò ìlàlóye lé lórí níí ṣe pẹ̀lú òkodoro òtítọ́ náà pé àwọn kan lára àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ń fa arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí lọ sí ilé-ẹjọ́ ayé láti lè yanjú aáwọ̀. Paulu bá wọn wí gidigidi fún ṣíṣe èyí.—1 Korinti 6:5-8.

      16 Síbẹ̀ ọ̀ràn mìíràn tí ń yọ ìjọ tí ó wà ní Korinti lẹ́nu níí ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Ní 1 Korinti orí 7, Paulu fi hàn pé nítorí ìwà pálapàla takọtabo tí ó gbilẹ̀, yóò dára bí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan bá ní aya tirẹ̀ kí obìnrin kọ̀ọ̀kan sì ní ọkọ tirẹ̀. Paulu fi hàn pẹ̀lú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún àwọn kòlọ́kọ-kòláya láti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìpínyà ọkàn tí ó dínkù, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀bùn dídúró láìlọ́kọ-láìláya. Bí ọkọ obìnrin kan bá sì kú, òun yóò ní òmìnira láti tún ṣe ìgbéyàwó ṣùgbọ́n “kìkì ninu Oluwa.”—1 Korinti 7:39.

      17. Ìmọ́lẹ̀ wo ni Paulu tàn sórí ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde?

      17 Ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí Oluwa lo Paulu láti tàn sórí àjíǹde! Pẹ̀lú irú ara wo ni a óò fi jí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró dìde? Paulu kọ̀wé pé: “A gbìn ín ní ara ìyára, a gbé e dìde ní ara ti ẹ̀mí.” Kò sí ara ẹlẹ́ran-ara kankan tí a óò gbé lọ sí òkè ọ̀run, nítorí pé “ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun.” Paulu fikún un pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró ni yóò sùn nínú ikú ṣùgbọ́n pé nígbà wíwà níhìn-ín Jesu a óò jí àwọn kan lára wọn dìde sí ìyè àìleèkú ní ìpajúpẹ́.—1 Korinti 15:43-53.

      18. Ìmọ́lẹ̀ wo nípa ọjọ́-ọ̀la ni lẹ́tà Paulu àkọ́kọ́ sí àwọn ará Tessalonika ní nínú?

      18 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Kristian ní Tessalonika, a lo Paulu láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọjọ́-ọ̀la. Ọjọ́ Jehofa yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Paulu tún ṣàlàyé pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà ati ààbò!’ nígbà naa ni ìparun òjijì yoo dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yoo sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tessalonika 5:2, 3.

      19, 20. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn Kristian ní Jerusalemu àti Judea rí gbà nínú lẹ́tà Paulu sí àwọn Heberu?

      19 Nípa kíkọ lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Heberu, Paulu tàtaré àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Kristian ìjímìjí ní Jerusalemu àti Judea. Ẹ wo bí ó ṣe fi bí ọ̀nà ìgbàjọ́sìn àwọn Kristian ṣe galọ́lá ju ọ̀nà ìgbàjọ́sìn ti Mose lọ hàn! Dípò títẹ̀lé Òfin tí àwọn áńgẹ́lì tàtaré rẹ̀, àwọn Kristian ní ìgbàgbọ́ nínú ìgbàlà tí ó jẹ́ pé Ọmọkùnrin Ọlọrun ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹni tí ó galọ́lá fíìfíì ju irú àwọn áńgẹ́lì òjíṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ. (Heberu 2:2-4) Ìránṣẹ́ onítọ̀ọ́jú lásán ni Mose jẹ́ ní ilé Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu Kristi ń darí gbogbo odidi ilé náà. Kristi ni olórí àlùfáà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣètò pàtàkì ti Melkisedeki, ó ní ipò kan tí ó galọ́lá fíìfíì ju ti ipò àlùfáà Aaroni lọ. Paulu tún tọ́ka sí i pé kò ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Israeli láti wọnú ìsinmi Ọlọrun nítorí àìní ìgbàgbọ́ àti àìṣègbọràn, ṣùgbọ́n àwọn Kristian wọnú rẹ̀ nítorí ìṣòtítọ́ àti ìgbọràn wọn.—Heberu 3:1-4, 11.

      20 Lẹ́yìn náà, májẹ̀mú titun, pẹ̀lú galọ́lá fíìfíì ju májẹ̀mú Òfin lọ. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní 600 ọdún ṣáájú ní Jeremiah 31:31-34, àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú titun ni a kọ òfin Ọlọrun sí ọkàn-àyà wọn wọ́n sì ń gbádùn ìdáríjì tòótọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò níní olórí àlùfáà kan tí ó níláti máa rú ẹbọ lọ́dọọdún fún ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ àti ti àwọn ènìyàn, àwọn Kristian ní Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olórí Àlùfáà wọn, ẹni tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí ó sì rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ láìní padà tún un ṣe mọ́. Dípò wíwọnú ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ láti gbé ìrúbọ rẹ̀ kalẹ̀ ó wọnú ọ̀run gan-an lọ, láti lè fara hàn níwájú Jehofa fúnra rẹ̀. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, fífi ẹran rúbọ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin Mose kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá, bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọn kì bá tí máa rú u lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n ẹbọ ti Kristi, tí ó rú láìní tún un ṣe mọ́, ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Gbogbo èyí tan ìmọ́lẹ̀ sórí tẹ́ḿpìlì ńlá tẹ̀mí, nínú àgbàlá èyí tí àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró àti “awọn àgùtàn mìíràn” ti ń ṣiṣẹ́sìn lónìí.—Johannu 10:16; Heberu 9:24-28.

      21. Kí ni ohun tí ìjíròrò yìí ti fi hàn nípa ìmúṣẹ Orin Dafidi 97:11 àti Owe 4:18 ní àkókò àwọn aposteli?

      21 Àyè kò tó láti fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ púpọ̀ síi, irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí a rí nínú àwọn lẹ́tà aposteli Peteru àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jakọbu àti Juda. Ṣùgbọ́n àwọn tí a ti mẹ́nukàn wọ̀nyí yẹ kí ó tó láti fi hàn pé Orin Dafidi 97:11 àti Owe 4:18 ní ìmúṣẹ tí ó pe àfiyèsí ní àkókò àwọn aposteli. Òtítọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀síwájú láti orí àwọn irú-oríṣi àti àwọn òjìji sí àwọn ìmúṣẹ àti òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀.—Galatia 3:23-25; 4:21-26.

      22. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, kí sì ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò fi hàn?

      22 Lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Jesu àti ìbẹ̀rẹ̀ ìpẹ̀yìndà tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà jó réúréú. (2 Tessalonika 2:1-11) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Jesu, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún Ọ̀gá náà padà dé ó sì rí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí ń fún “awọn ará ilé” ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, Jesu Kristi yan ẹrú náà sípò “lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Matteu 24:45-47) Irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tẹ̀lé e? Èyí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Ilẹ̀ níhìn-ín ń tọ́ka sí àyíká náà níbi tí Kristian ti yàn láti mú àwọn ànímọ́ ipò jíjẹ́ ẹnìkan dàgbà.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1980, ojú-ìwé 22 sí 23.

  • Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀—Ńlá àti Kékeré Apá Kìn-Ínní
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | May 15
    • Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀—Ńlá àti Kékeré Apá Kìn-Ínní

      “Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.”—OWE 4:18.

      1. Èéṣe tí a fi ṣípayá òtítọ́ náà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?

      Ẹ̀RÍ ọgbọ́n àtọ̀runwá ni ó jẹ́ pé ní ìbámu pẹ̀lú Owe 14:18, ṣíṣí òtítọ́ tẹ̀mí payá ti ṣẹlẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a rí bí ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí ṣe ní ìmúṣẹ ní àkókò àwọn aposteli. Bí a bá ti ṣípayá èyí tí ó pọ̀ jù nínú òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ lẹ́ẹ̀kan náà ni, à bá má ti lóye rẹ̀ ìbá sì ti dàrú mọ́ wa lójú—ìyọrísí rẹ̀ ìbá ti dàbí jíjáde láti inú ihò tí ó ṣókùnkùn sínú oòrùn títànyòò. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, òtítọ́ tí a ṣípayá ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristian lókun lọ́nà tí ń bá a nìṣó. Ó túbọ̀ ń mú kí ìrètí wọn máa tànyòò síi kí ipa-ọ̀nà tí wọ́n sì túbọ̀ máa ṣe kedere síi.

      “Olùṣòtítọ́ ati Ọlọ́gbọ́n-Inú Ẹrú”

      2. Ta ni Jesu fi hàn pé òun yóò lo láti mú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wá fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun, àwọn wo sì ni irin-iṣẹ́ yẹn ní nínú?

      2 Ní àkókò àwọn aposteli Jesu Kristi rí i pé ó tọ́ láti lo ọ̀nà tí ó rékọjá ti ẹ̀dá láti fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ àkọ́kọ́. A ní àpẹẹrẹ méjì nípa èyí: Pentekosti 33 C.E. àti ìyílọ́kànpadà Korneliu ní 36 C.E. Láti ìgbà yìí lọ, Kristi rí i pé ó tọ́ láti lo aṣojú tí ó jẹ́ ẹ̀dà ènìyàn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti sọtẹ́lẹ̀: “Níti tòótọ́ ta ni olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú tí ọ̀gá rẹ̀ yànsípò lórí awọn ará ilé rẹ̀, lati fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu? Aláyọ̀ ni ẹrú naa bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Oun yoo yàn án sípò lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Matteu 24:45-47) Ẹrú yìí kò lè jẹ́ ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo nítorí pé ó níláti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí láti ìgbà tí ìjọ Kristian ti bẹ̀rẹ̀ ní Pentekosti títí di ìgbà tí Ọ̀gá náà, Jesu Kristi, wá fún ìjíhìn. Òkodoro òtítọ́ náà fi hàn pé ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú yìí ní nínú gbogbo àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan lórí ilẹ̀-ayé ní àkókò kan pàtó.

      3. Àwọn wo ni ó wà lára mẹ́ḿbà àkọ́kọ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà?

      3 Àwọn wo ni ó kọ́kọ́ jẹ́ mẹ́ḿbá ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà? Ọ̀kan ni aposteli Peteru, ẹni tí ó kọbiara sí àṣẹ Jesu pé: “Máa bọ́ awọn àgùtàn mi kéékèèké.” (Johannu 21:17) Àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ ẹrú náà ní nínú Matteu, ẹni tí ó kọ Ìròyìnrere tí a fi orúkọ rẹ̀ mọ̀, àti Paulu, Jakọbu, àti Juda, àwọn tí wọ́n kọ àwọn lẹ́tà tí a mí sí. Aposteli Johannu, ẹni tí ó kọ ìwé Ìṣípayá, Ìròyìnrere rẹ̀, àti àwọn lẹ́tà rẹ̀, pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kọ̀wé ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí Jesu paláṣẹ fún wọn.

      4. Àwọn wo ni “awọn ará ilé”?

      4 Bí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan, láìka ibi yòówù tí wọ́n lè máa gbé lórí ilẹ̀-ayé sí, bá jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ẹrú náà, àwọn wo ni “awọn ará ilé”? Ẹni-àmì-òróró ni wọ́n bákan náà ṣùgbọ́n tí a gbé yẹ̀wò láti ojú-ìwòye mìíràn tí ó yàtọ̀—gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóò jẹ́ “ẹrú” tàbí wọn yóò jẹ́ “awọn ara ilé,” ó sinmi lórí bóyá wọ́n ń fúnni ní oúnjẹ tẹ̀mí tàbí wọ́n ń ṣàjọpín nínú rẹ̀. Láti ṣàpèjúwe: Gẹ́gẹ́ bì a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní 2 Peteru 3:15, 16, aposteli Peteru tọ́ka sí àwọn lẹ́tà Paulu. Nígbà tí ó ń kà wọ́n, Peteru yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ara ilé tí ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Paulu pèsè gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ ẹrú náà.

      5. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú náà láàárín àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn àwọn aposteli? (b) Àwọn ìdàgbàsókè wo ni ó wáyé ní apá tí ó kẹ́yìn apá ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún?

      5 Nípa èyí, ìwé náà God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached sọ pé: “Nípa bí ẹgbẹ́ ‘olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú’ náà ṣe wáyé tí ó sì ṣiṣẹ́sìn jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Ọ̀gá náà Jesu Kristi, a kò ní àkọsílẹ̀ ìtàn nípa rẹ̀. Ó ṣe kedere pé ìran ẹgbẹ́ ‘ẹrú’ náà kan bọ́ ìran tí ó tẹ̀lé tirẹ̀. (2 Timoteu 2:2) Ṣùgbọ́n bí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ti ń parí lọ àwọn ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí ti Bibeli Mímọ́ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti jẹ nínú rẹ̀ . . . A dá àwọn kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli . . . sílẹ̀ wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú òye nípa òtítọ́ ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀. Àwọn olóòótọ́-ọkàn aláìmọtara-ẹni-nìkan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ̀nyí háragàgà láti ṣàjọpín àwọn apá ṣíṣekókó ti oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ní ẹ̀mí ìṣòtítọ́ ti ‘ẹrú’ náà tí a yànsípò láti fún ‘awọn ara ilé’ ní ‘oúnjẹ’ tẹ̀mí tí wọ́n nílò ‘ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.’ Wọ́n jẹ́ ‘ọlọ́gbọ́n-inú’ ní fífòyemọ̀ pé àkókò tí ó tọ́ tí ó sì bẹ́tọ̀ọ́mu nìyẹn àti àwọn ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti pín oúnjẹ náà. Wọ́n sakun láti pín in.”—Ojú-ìwé 344 sí 345.a

      Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ ní Àkókò Òde-Òní

      6. Òkodoro òtítọ́ wo ni ó tayọ gédégbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ṣíṣí òtítọ́ náà payá ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?

      6 Òkodoro òtítọ́ kan tí ó tayọ gédégbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí Jehofa lò láti mú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí ń mọ́lẹ̀ síi ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yìí wá ni pé wọn kò gba ìyìn fún ara wọn. Ìṣarasíhùwà C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, ni pé ó dùn mọ́ Oluwa nínú láti lo ẹbun wọn tí kò ṣàrà ọ̀tọ̀. Nípa àwọn ọ̀rọ̀ èébú tí a sún àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti lò, Arákùnrin Russell mú kí ó di mímọ̀ pé òun kò tí ì bá “Ọmọlẹ́yìn Russell” kankan pàdé rí àti pé kò sí ohunkóhun tí ń jẹ́ “Ìgbàgbọ́ Russell.” Ọlọrun ni a fi gbogbo ìyìn fún.

      7. Ẹ̀rí wo ni Arákùnrin Russell àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ fúnni níti pé nítòótọ́ ni àwọn darapọ̀ mọ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà?

      7 Bí a bá fi ìyọrísí rẹ̀ gbé e yẹ̀wò, kò lè sí iyèméjì pé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ń darí akitiyan Arákùnrin Russell àti àwọn wọnnì tí ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ara ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwùjọ àlùfáà ti àkókò náà jẹ́wọ́ pé àwọn gbàgbọ́ pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí àti pé Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun, wọ́n fọwọ́ sí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Babiloni, tí ó jẹ́ èké, irú bí Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, àti ìdálóró ayérayé. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Jesu, níti tòótọ́ ẹ̀mí mímọ́ àti ìsapá àfìrẹ̀lẹ̀ṣe tí Arákùnrin Russell àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe ni ó mú kí òtítọ́ mọ́lẹ̀ síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Johannu 16:13) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ẹni-àmì-òróró yẹn fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ apákan ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà níti tòótọ́, ẹni tí iṣẹ́ tí a fàṣẹ yàn fún un jẹ́ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ará ilé Ọ̀gá náà. Ìsapá wọn jẹ́ àrànṣe ńláǹlà ní kíkó àwọn ẹni-àmì-òróró jọ.

      8. Òkodoro òtítọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ wo nípa Jehofa, Bibeli, Jesu Kristi, àti ẹ̀mí mímọ́ ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóye ní kedere?

      8 Bí Jehofa ṣe fi àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ fojúrere ńláǹlà hàn sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí wọ̀nyí, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, yẹ fún àfiyèsí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n fi ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ hàn pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ àti pé ó ní orúkọ títayọlọ́lá náà Jehofa. (Orin Dafidi 83:18; Romu 1:20) Wọ́n rí i pé Jehofa ní àwọn ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì—agbára, ìdájọ́-òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́. (Genesisi 17:1; Deuteronomi 32:4; Romu 11:33; 1 Johannu 4:8) Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí fi ẹ̀rí hàn ní kedere pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí òhun sì ni òtítọ́. (Johannu 17:17; 2 Timoteu 3:16, 17) Síwájú síi, wọ́n gbà pé Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, ni a dá àti pé ó fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún gbogbo aráyé. (Matteu 20:28; Kolosse 1:15) Ẹ̀mí mímọ́, kàkà tí ìbá fi jẹ́ ẹni kẹta nínú Mẹ́talọ́kan, ni wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí ipá agbékánkán ṣiṣẹ́ Ọlọrun.—Ìṣe 2:17.

      9. (a) Àwọn òtítọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóye ní kedere nípa irú ẹni tí ènìyàn jẹ́ àti kádàrá tí Bibeli nawọ́ rẹ̀ jáde? (b) Àwọn òtítọ́ mìíràn wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa rí kedere?

      9 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rí i ní kedere pé ènìyàn kò ní àìleèkú ọkàn ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọkàn tí ó lè kú. Wọ́n mọ̀ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” kì í ṣe ìdálóró ayérayé, kò sí ibì kankan tí ó jẹ́ hẹ́ẹ̀lì tí iná ti ń jó. (Romu 5:12; 6:23; Genesisi 2:7; Esekieli 18:4) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n rí i ní kedere pé kì í ṣe pé àbá èrò-orí ẹfolúṣọ̀n kò bá ìwé mímọ́ mu nìkan ni ṣùgbọ́n a sọ ọ́ láìní ẹ̀rí ìpìlẹ̀ òtítọ́ kankan. (Genesisi, orí 1 àti 2) Àwọn pẹ̀lú fòyemọ̀ pé kádàrá méjì ni Bibeli nawọ́ rẹ̀ jáde—ti ọ̀run fún 144,000 ẹni-àmì-òróró àwọn ọmọlẹ́yìn tí ń tẹ̀lé ipasẹ̀ Kristi àti ilẹ̀-ayé tí a sọ di paradise fun àìmọye “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “awọn àgùtàn mìíràn.” (Ìṣípayá 7:9; 14:1; Johannu 10:16) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn mọ̀ pé ilẹ̀-ayé yóò wà títíláé a kì yóò sì jó o run, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn ti fi kọ́ni. (Oniwasu 1:4; Luku 23:43) Wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ìpadàbọ̀ Kristi yóò jẹ́ àìṣeé fojúrí àti pé nígbà náà òun yóò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò sì mú paradise ilẹ̀-ayé wá.—Ìṣe 10:42; Romu 8:19-21; 1 Peteru 3:18.

      10. Àwọn òtítọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kọ́ nípa ìbatisí, fífi ìyàtọ̀ sí àwùjọ àlùfáà àti ọmọ ìjọ, àti Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi?

      10 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kẹ́kọ̀ọ́ pé ìbatisí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu kì í ṣe ọ̀ràn bíbu omi wọ́n àwọn ọmọ-ọwọ́ lórí ṣùgbọ́n pé ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Jesu ní Matteu 28:19, 20, ó jẹ́ ríri àwọn aláìgbàgbọ́ tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bọmi. Wọ́n wá rí i pé kò sí ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ kankan fún fífi ìyàtọ̀ sáàárín àwùjọ àlùfáà àti àwọn ọmọ ìjọ. (Matteu 23:8-10) Ní ìyàtọ̀ gedegbe, gbogbo Kristian gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwàásù ìhìnrere náà. (Ìṣe 1:8) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mọrírì pé a níláti máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní Nisan 14. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n rí i pé Easter jẹ́ họlidé àwọn abọ̀rìṣà. Ní àfikún síi, àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyẹn ní ìdánilójú pé Ọlọrun ń ti iṣẹ́ wọn lẹ́yìn débi pé wọ́n kò gba ìdáwó rí. (Matteu 10:8) Láti ìgbà ìjímìjí, wọ́n lóye pé àwọn Kristian níláti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bibeli, èyí tí ó ní nínú mímú àwọn èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun dàgbà.—Galatia 5:22, 23.

      Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Tí Ń Mọ́lẹ̀ Síi

      11. Ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tàn sórí iṣẹ́ tí a paláṣẹ fún àwọn Kristian àti òwe àkàwé Jesu nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́?

      11 Ní pàtàkì láti 1919 ni a ti ń bùkún àwọn ìránṣẹ́ Jehofa pẹ̀lú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi. Ẹ wo irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò tí ó tàn ní àpéjọpọ̀ Cedar Point ní 1922 bí J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society kejì, ṣe tẹnumọ́ kókó náà lọ́nà lílágbára pé olórí ojúṣe àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ni láti ‘fọnrere, fọnrere, fọnrere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀’! Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gan-an, ìmọ́lẹ̀ títànyòò náà tàn sórí òwe àkàwé ti àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́. A rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ Oluwa ti ìsinsìnyí, kì í ṣe ní ọjọ́-ọ̀la nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti rò tẹ́lẹ̀. Lákòókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà àwọn arákùnrin Kristi kì yóò ṣàìsàn, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì yóò fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, Jehofa Ọlọrun, kì í ṣe Jesu Kristi, ni yóò ṣe ìdájọ́.—Matteu 25:31-46.

      12. Ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni ó wá nípa Armageddoni?

      12 Ní 1926 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ mìíràn ni a ṣípayá pé ogun Armageddoni kì yóò jẹ́ ìyípadà tegbò tigaga ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe ronú nígbà kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ogun kan nínú èyí tí Jehofa yóò ti fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tí ó ṣe kedere tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ dájú pé òun ni Ọlọrun.—Ìṣípayá 16:14-16; 19:17-21.

      Kérésìmesì—Họlidé Àwọn Abọ̀rìṣà

      13. (a) Ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tàn sórí ayẹyẹ Kérésìmesì? (b) Èéṣe tí a kò fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mọ́? (Fí àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé kún un.)

      13 Kété lẹ́yìn náà, ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ kan mú kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dẹ́kun ṣíṣayẹyẹ Kérésìmesì. Ṣáájú àkókò yẹn Kérésìmesì ti fìgbà gbogbo jẹ́ ayẹyẹ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli máa ń ṣe kárí-ayé, ayẹyẹ rẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn sì máa ń jẹ́ àjọyọ̀ sísọkutuyọ̀yọ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n nígbà náà a fòye mọ̀ pé níti gidi ṣíṣayẹyẹ December 25 jẹ́ àṣà àwọn abọ̀rìṣà, àwọn Kristẹndọm apẹ̀yìndà ni ó sì yàn án kí ó baà lè rọrùn láti yí àwọn abọ̀rìṣà lọ́kàn padà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a tún rí i pé kò lè jẹ́ àkókò òtútù ni a bí Jesu, níwọ̀n bí o tí jẹ́ pé ní àkókò ìbí rẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùtàn ń da agbo ẹran wọn ní pápá—ohun kan tí wọn kì bá ti lè ṣe ní òru ní apá ìparí oṣù December. (Luku 2:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé a bí Jesu ní nǹkan bí October 1. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tún mọ̀ pé àwọn tí a ń fẹnu lásán pè ní ọkùnrin amòye tí wọ́n bẹ Jesu wò ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn ìbí rẹ̀ jẹ́ àwọn magi abọ̀rìṣà.b

      Orúkọ Titun

      14. Èéṣe tí orúkọ náà àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kò fi bá àwọn ènìyàn Jehofa mu tó?

      14 Ní 1931 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣí orúkọ kan tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu payá fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ̀nyẹn. Àwọn ènìyàn Jehofa ti lóye pé wọn kò lè tẹ́wọ́gba èyíkéyìí lára àwọn orúkọ ìnagijẹ tí àwọn mìíràn ti fún wọn, irú bí àwọn Ọmọlẹ́yìn Russell, Onígbàgbọ́ Ilẹ́ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Fẹ́rẹ̀ẹ́ Mọ́, àti “onígbàgbọ́ kò-sí-hẹ́ẹ̀lì.”c Ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí mọrírì pé orúkọ náà tí àwọn ti yàn fúnra wọn—Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Káàkiri Orílẹ̀-Èdè—kò bá wọ́n mu tó. Wọ́n ju kìkì àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn púpọ̀ mìíràn tún wà tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣùgbọ́n tí wọn kò farajọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rárá.

      15. Orúkọ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tẹ́wọ́gbà ní 1931, èésìtiṣe ti ó fi bá a mu wẹ́kú?

      15 Báwo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe wá rí orúkọ titun kan? Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Ile-Iṣọ Na ti ń fi orúkọ Jehofa hàn ketekete. Nítorí náà, ó bá a mu wẹ́kú jùlọ pé kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tẹ́wọ́gba orúkọ náà tí a rí ní Isaiah 43:10 (NW): “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni ọ̀rọ̀ àsọjáde Jehofa, ‘àní ìránṣẹ́ mi ti mo ti yàn, kí ẹ̀yin kí ó baà lè mọ̀ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, àti kí ẹ̀yin kí ó lè lóye pé èmi ni Ẹni kan náà. Ṣáájú mi kò sí Ọlọrun kan tí a ṣe, àti lẹ́yìn mi kò tún ní sí ọ̀kankan.’”

      Ìdáláre àti “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”

      16. Èéṣe tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò kò fi lè tọ́ka sí àwọn Júù àbínibí tí wọ́n padà sí Palestine, ṣùgbọ́n àwọn wo ni wọ́n tọ́ka sí?

      16 Nínú ìdìpọ̀ kejì ìwé Vindication, tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde ní 1932, ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí Isaiah, Jeremiah, Esekieli, àti àwọn wòlíì mìíràn ṣàkọsílẹ̀ kò tọ́ka sí àwọn Júù àbínibí (gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rò nígbà kan), àwọn tí wọ́n ń padà sí Palestine pẹ̀lú àìgbàgbọ́ àti ète ìsúnniṣe òṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò wọ̀nyí, èyí tí ó ní ìmúṣẹ ráńpẹ́ nígbà tí àwọn Júù padà láti ìgbèkùn Babiloni ní 537 B.C.E., ní ìmúṣẹ títóbi wọn nínú ìdáǹdè Israeli tẹ̀mí àti ìmúpadàbọ̀sípò wọn tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1919 àti nínú aásìkí tí ó yọrí sí nínú paradise tẹ̀mí tí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tòótọ́ ń gbádùn lónìí.

      17, 18. (a) Nígbà tí ó ṣe, nípasẹ̀ ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ kan, kí ni a fi hàn pé ó jẹ́ olórí ète Jehofa? (b) Irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo nípa Ìṣípayá 7:9-17 ni ó ṣẹlẹ̀ ní 1935?

      17 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá pé olórí ète Jehofa, kì í ṣe ìgbàlà ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n ìdáláre ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Ẹṣin-ọ̀rọ̀ Bibeli tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni a rí pé, kì í ṣe ìràpadà, bíkòṣe Ìjọba náà, nítorí pé yóò dá ipò ọba aláṣẹ Jehofa láre. Ẹ wo irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ìyẹn jẹ́! Bí wọn yóò ṣe dé ọ̀run kì í ṣe ohun tí ó ṣe pàtàkì tí ó jẹ àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ lógún mọ́.

      18 Ní 1935 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò ṣípayá pé ogunlọ́gọ̀ ńlá tí a mẹ́nukàn nínú Ìṣípayá 7:9-17 kì í ṣe ẹgbẹ́ kejì tí yóò lọ sí ọ̀run. A ti rò ó tẹ́lẹ̀ pé àwọn wọnnì tí a mẹ́nukàn nínú àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ àwọn kan lára àwọn ẹni-àmì-òróró tí wọn kò jẹ́ olùṣòtítọ́ délẹ̀délẹ̀ nítorí náà wọ́n ń dúró níwájú ìtẹ́ dípò kí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ kí wọ́n máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n kò sí ohun kankan tí ń jẹ́ jíjẹ́ olùṣòtítọ́ díẹ̀. Ẹnì kan yóò kúkú jẹ́ olùṣòtítọ́ tàbí aláìṣòtítọ́. Nítorí náà a rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí tọ́ka sí àìníye ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí a ti ń kójọpọ̀ nísinsìnyí tí ìrètí wọn sì jẹ́ ti orí ilẹ̀-ayé. Àwọn ni “awọn àgùtàn” ti Matteu 25:31-46 àti “awọn àgùtàn mìíràn” ti Johannu 10:16.

      Àgbélébùú —Kì í Ṣe Àmì Ìṣàpẹẹrẹ Kristian

      19, 20. Èéṣe tí àgbélébùú kò fi lè jẹ́ àmì ìṣàpẹẹrẹ fún ìsìn Kristian tòótọ́?

      19 Fún ọ̀pọ̀ ọdún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fi àgbélébùú sí ipò pàtàkì gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ ìsìn Kristian. Wọ́n tilẹ̀ ní ohun ọ̀ṣọ́ tí ó ní “àgbélébùú àti adé.” Gẹ́gẹ́ bí King James Version ṣe sọ, Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbé “àgbélébùú” wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wá gbàgbọ́ pé orí àgbélébùú ni a kàn án mọ́. (Matteu 16:24; 27:32) Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún àmì àpẹẹrẹ yìí tún fara hàn lẹ́yìn èèpo ìwé ìròyìn Ile-Iṣọ Na.

      20 Ìwé náà Ọrọ̀, tí Society tẹ̀ jáde ní 1936, mú un ṣe kedere pé Jesu Kristi ni a kàn mọ́, kì í ṣe àgbélébùú, bíkòṣe òpó dídúró ṣánṣán, tàbí òpó igi. Gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Griki náà (stau·rosʹ) tí a pè ní “àgbélébùú” nínú Bibeli King James Version “túmọ̀ sí, ní pàtàkì, òpó tàbí igi dídúró ṣánṣán. Ó yẹ kí a dá [a] mọ̀ yàtọ̀ sí àgbélébùú olópòó méjì tí ṣọ́ọ̀ṣì hùmọ̀ rẹ̀. . . . Èyí tí a mẹ́nukàn gbẹ̀yìn yìí pilẹ̀ ní Kaldea, a sì lò ó gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ fún ọlọrun Tammusi.” Dípò sísọ ọ di òrìṣà, ohun tí a kan Jesu mọ́ ni a níláti wò pẹ̀lú ìkórìíra.

      21. Kí ni a óò gbé yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e?

      21 Àwọn àpẹẹrẹ síwájú síi wà nípa àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ńlá àti àwọn wọnnì tí a lè wò gẹ́gẹ́ bíi kékeré. Fún ìjíròrò àwọn wọ̀nyí, jọ̀wọ́ wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

      b Nígbà tí ó ṣe, a rí i pé bí a kò bá ní máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, a kò ní máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí kankan. Yàtọ̀ sí ìyẹn, yálà àwọn ọmọ Israeli tàbí àwọn Kristian ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Bibeli mẹ́nukan ọjọ́ ìbí méjì péré, ọ̀kan jẹ́ ti Farao èkejì sì jẹ́ ti Herodu Antipa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni a fi ìpànìyàn bàjẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí nítorí pé àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí pilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ó sì ń gbé ọlọ́jọ́ ìbí ga.—Genesisi 40:20-22; Marku 6:21-28.

      c Èyí jẹ́ àṣìṣe tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀ka ìsìn Kristẹndọm ṣe. Àwọn onísìn Luther jẹ́ orúkọ ìnagijẹ tí àwọn ọ̀tá Martin Luther fun àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí àwọn náà sì tẹ́wọ́gbà á. Bákan náà, àwọn onísìn Baptist tẹ́wọ́gba orúkọ ìnagijẹ náà tí àwọn ará-ìta fún wọn nítorí pé wọ́n wàásù ìbatisí nípa ìrìbọmi. Òmíràn tí ó farajọ ọ́ ni, àwọn onísìn Methodist tí wọ́n tẹ́wọ́gba orúkọ náà tí àwọn ará-ìta fún wọn. Nípa bí àwọn onísìn Society of Friends ṣe rí orúkọ wọn Quakers gbà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà Quaker (amúniwárìrì) ni a ń lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àbùkù sí Fox [olùdásílẹ̀ rẹ̀], ẹni tí ó sọ fún adájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan pé kí ó ‘wárìrì fún Ọ̀rọ̀ Oluwa.’ Adájọ́ náà pè Fox ni ‘amúniwárìrì.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́