Ìrètí Mi Tipẹ́tipẹ́—Láti Má Ṣe Kú Láéláé
GẸ́GẸ́ BÍ HECTOR R. PRIEST ṢE SỌ Ọ́
Dókítà náà wí pé: “Àrùn jẹjẹrẹ náà kò gbóògùn. Kò sí ohun mìíràn tí a tún lè ṣe fún ọ.” A ṣe àyẹ̀wò yẹn ní èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Síbẹ̀, mo ṣì ń fọkàn ṣìkẹ́ ìrètí tí a gbé karí Bibeli náà, ti wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé láìní kú rárá láé.—Johannu 11:26.
ÀWỌN òbí mi jẹ́ Methodist olùfọkànsìn tí kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ ní ìgbèríko kékeré kan, tí kò jìnnà sí oko ìdílé wa. A bí mi ní àfonífojì oko ẹlẹ́wà ti Wairarapa, tí ó jẹ́ nǹkan bí 130 kìlómítà sí àríwá ìlà oòrùn Wellington, New Zealand. Níbẹ̀, a gbádùn wíwo òkè ńlá tí yìnyín bò mọ́lẹ̀, àwọn odò mímọ́ gaara lórí òkè ńlá, àwọn òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́ràá.
Ní Ṣọ́ọ̀ṣì Methodist, a kọ́ wa pé gbogbo ẹni rere ni yóò lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n, àwọn ẹni búburú yóò lọ sí ọ̀run àpáàdì, ibi ìfinádánilóró kan. N kò lóye ìdí tí Ọlọrun kò fi kúkú dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn sí ọ̀run ní ìpìlẹ̀, bí ó bá jẹ́ pé, ibẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n máa gbé. Mo máa ń fìgbà gbogbo bẹ̀rù ikú, mo sì sábà máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí a fi ní láti kú. Ní 1927, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 16, ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan ṣẹlẹ̀ sí ìdílé wa. Ìyẹn ni ó sún mi sí wíwá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi.
Èé Ṣe Tí Reg Fi Kú?
Nígbà tí Reg, arákùnrin mi, jẹ ọmọ ọdún 11, àìsàn líle koko kọ lù ú. Dókítà kò lè sọ ohun tí ń yọ ọ́ lẹ́nu, kò sì lè ràn án lọ́wọ́. Màmá ké sí àlùfáà Methodist. Ó gbàdúrà fún Reg, ṣùgbọ́n èyí kò tu Màmá nínú. Ní ti gàsíkíá, ó sọ fún àlùfáà náà pé àdúrà rẹ̀ kò gbéṣẹ́.
Nígbà tí Reg kú, Màmá máa ń bá gbogbo ènìyàn sọ̀rọ̀ láti gbìyànjú láti tẹ́ òùngbẹ rẹ̀ fún àwọn ìdáhùn tòótọ́ lọ́rùn, nípa ìdí tí ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ fi ní láti kú. Nígbà tí ó ń bá ọkùnrin oníṣòwò kan sọ̀rọ̀ ní ìgboro, ó béèrè bóyá ó mọ ohunkóhun nípa ipò tí àwọn òkú wà. Kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó sọ pé: “Ẹnì kan fi ìwé kan sílẹ̀ síhìn-ín tí o lè máa mú lọ.”
Màmá mú ìwé náà wá sílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Kò lè gbé e sílẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, gbogbo ìṣesí rẹ̀ yí padà. Ó sọ fún ìdílé náà pé: “Òun nìyí; òtítọ́ nìyí.” Ìwé náà ni, The Divine Plan of the Ages, ìdìpọ̀ àkọ́kọ́ nínú ìwé Studies in the Scriptures. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo ń ṣiyè méjì, mo sì gbìyànjú láti jiyàn lòdì sí bí ìwé náà ṣe gbé ètè Ẹlẹ́dàá kalẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo dẹ́kun iyàn jíjà.
Títẹ́wọ́ Gba Òtítọ́ Bibeli
Mo ronú pé, ‘Finú wòye wíwà láàyè títí láé ná, tí o kò ní kú láéláé!’ Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kan yóò retí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun onífẹ̀ẹ́. Paradise ilẹ̀ ayé! Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni mo fẹ́.
Lẹ́yìn kíkọ́ nípa àwọn òtítọ́ àgbàyanu wọ̀nyí, Màmá àti àwọn Kristian arábìnrin mẹ́ta láti Wellington—Arábìnrin Thompson, Arábìnrin Barton, àti Arábìnrin Jones—yóò lọ lẹ́ẹ̀kan náà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ní títan irúgbìn Ìjọba jákèjádò àwọn ìgbèríko. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Bàbà kò ní ẹ̀mí míṣọ́nnárì tí Màmá ní, ó tì í lẹ́yìn nínú ìgbòkègbodò rẹ̀.
Òtítọ́ náà dá mi lójú, ṣùgbọ́n fún sáà kan, n kò fọwọ́ dan-in dan-in mú ìgbàgbọ́ mi. Ní 1935, mo gbé Rowena Corlett níyàwó, kò pẹ́ kò jìnnà, a fi ọmọbìnrin kan, Enid, àti ọmọkùnrin kan, Barry, ta wá lọ́rẹ. Mo ṣiṣẹ́ ẹran rírà, ní ríra ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹran lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀ tí ó wà láyìíká. Nígbà tí àwọn àgbẹ̀ wọ̀nyí bá ń jíròrò ọ̀rọ̀ òṣèlú, inú mi máa ń dùn nígbà ti mo bá sọ fún wọn pé: “Kò sí èyíkéyìí nínú ìsapá ènìyàn wọ̀nyí tí yóò kẹ́sẹ járí. Ìjọba Ọlọrun ni ìṣàkóso kan ṣoṣo ti yóò ṣiṣẹ́.”
Ó báni nínú jẹ́ pé, tábà mímu wọ̀ mí lẹ́wù; fìkan-ràn-kan ni mí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìlera mi jó rẹ̀yìn, a sì dá mi dúró sí ilé ìwòsàn nítorí ìṣòro inú rírun. A sọ fún mi pé àrùn ìwúlé ìtẹ́nú ìfun tí sìgá mímu ń fà, ti kọ lù mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, mo pa ìwà náà tì, mo sábà máa ń lá àlá pé, mo ń mu sìgá tàbí tábà àmu-ùn-mután. Ẹ wo bí tábà ti jẹ́ ìwà bárakú búburú jáì tó!
Lẹ́yìn tí mo fi tábà mímu sílẹ̀, mo ṣe àwọn àtúnṣebọ̀sípò pàtàkì míràn. Ní 1939, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 28, mo ṣe batisí ní Odò Mangatai lẹ́bàá ilé wa ní abúlé. Robert Lazenby, tí ó di alábòójútó iṣẹ́ ìwàásù ní New Zealand lẹ́yìn náà, rin ìrìn àjò láti Wellington jíjìnnà réré, láti sọ àsọyé ní ilé wa àti láti batisí mi. Láti ìgbà náà, mo di onígboyà Ẹlẹ́rìí fún Jehofa.
Ṣíṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù
Lẹ́yìn ìbatisí mi, a yàn mí sípò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó Ìjọ Eketahuna. Aya mi, Rowena, kò tí ì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bibeli síbẹ̀. Ṣùgbọ́n, mo jẹ́ kí ó mọ̀ pé, èmi yóò ké sí Alf Bryant láti Pahiatua, láti wá kọ́ mi bí a ṣe ń jẹ́rìí lọ́nà tí ó tọ́ láti ilé dé ilé. Mo fẹ́ ṣètò iṣẹ́ ìwàásù, kí n sì kárí agbègbè ìpínlẹ̀ wa ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.
Rowena wí pé: “Hector, bí o bá jẹ́rìí lọ láti ilé dé ilé, o kò ní padà bá mi níbí. Èmi yóò fi ọ sílẹ̀. Ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ wà níhìn-ín—nínú ilé pẹ̀lú ìdílé rẹ.”
N kò mọ ohun tí mo lè ṣe. Pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀, mo múra. Mo ń ronú nínú ara mi pé, ‘Mo ní láti ṣe é. Ìgbésí ayé mi sinmi lé e, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbésí ayé ìdílé mi pẹ̀lú.’ Nítorí náà, mo jẹ́ kí ó dá Rowena lójú pé, n kò fẹ́ láti mú un bínú lọ́nàkọnà. Mo sọ fún un pé, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ni, ṣùgbọ́n, nítorí pé orúkọ àti ipò ọba aláṣẹ Jehofa, àti ìwàláàyè tiwa fúnra wa wé mọ́ ọn, mo gbọ́dọ̀ wàásù lọ́nà yìí.
Èmi àti Alf lọ sí ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́, ó sì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, mo rí i tí mo gba ìjíròrò náà mọ́ ọn lẹ́nu, ní sísọ fún onílé náà pé, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Noa fara jọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa, àti pé a ní láti ṣe ohun kan nípa mímú kí ìgbàlà wa dájú. (Matteu 24:37-39) Mo fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ díẹ̀ sílẹ̀ níbẹ.
Nígbà tí a fẹ́ máa lọ, Alf wí pé: “Níbo ni o ti rí gbogbo ìmọ̀ yẹn? O kò nílò mi. Máa dá ṣiṣẹ́ fúnra rẹ, a óò sì kárí ìlọ́po méjì agbègbè ìpínlẹ̀ tí à bá kárí tẹ́lẹ̀.” Nítorí náà, ohun tí a ṣe nìyẹn.
Bí a ti ń darí lọ sílé, n kò mọ ohun tí ń dúró dè wá. Inú mi dùn, ó sì yà mí lẹ́nu pé, Rowena ti po tíì sílẹ̀ fún wa. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, aya mi dara pọ̀ mọ́ mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba, ó si di apẹẹrẹ àtàtà fún ìtara Kristian.
Maud Manser, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, William àti Ruby, wà lára àwọn tí ó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àfonífojì oko wa. Ẹni líle, tí ó sì lè pinni lẹ́mìí ni ọkọ Maud. Lọ́jọ́ kan, èmi àti Rowena lọ sí oko wọn láti mú Maud jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ọ̀dọ́mọdé William ti ṣètò fún wa láti lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n, bàbá rẹ̀ ní èrò míràn.
Ipò náà kò bára dé. Mo ní kí Rowena gbé ọmọbìnrin wa jòjòló, Enid, dáni. Mo wọnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ William, mo sì yára wà á jáde láti inú ibi ìgbọ́kọ̀sí bí Ọ̀gbẹ́ni Manser ti ń yára láti gbìyànjú láti ti ilẹ̀kùn ibi ìgbọ́kọ̀sí náà kí a tó lè jáde. Ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe fún un. Lẹ́yìn tí a ti wa ọkọ̀ náà jáde sókè díẹ̀ sójú títì, a dúró, mo sì jáde kúrò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láti pàdé Ọ̀gbẹ́ni Manser tí inú rẹ̀ ń rù fùù. Mo sọ fún un pé: “A ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, Ìyá Ààfin Manser sì ń bá wa lọ.” Mo bẹ̀ ẹ́, ìbínú rẹ̀ sì rọlẹ̀ díẹ̀. Nígbà tí mo bá ronú nípa rẹ̀, mo rò pé ǹ bá ti yanjú ọ̀ràn náà ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀, ṣùgbọ́n, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó túra ká sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kó di Ẹlẹ́rìí.
Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn ènìyàn Jehofa ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, a sí gbádùn ìbẹ̀wò àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí ń dé sọ́dọ̀ wa lóko wa, a sì jàǹfààní nínú ìbẹ̀wò wọn pẹ̀lú. Àwọn àlejò wọ̀nyí ní Adrian Thompson àti arábìnrin rẹ̀, Molly, nínú, àwọn méjèèjì tí wọn lọ sí ọ̀kan lára àwọn kíláàsì àkọ́kọ́ ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead fún àwọn míṣọ́nnárì, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ sìn ní ibi iṣẹ́ àyànfúnni ní ilẹ̀ òkèèrè ní Japan àti Pakistan.
Àwọn Ìrírí Ìgbà Ogun
Ní September 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ó sì di October 1940, ìjọba New Zealand ka ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa léèwọ̀. A wọ́ púpọ̀ lára àwọn Kristian arákùnrin wa lọ sí àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ náà. A fi àwọn kan sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, a kò sì jẹ́ kí wọ́n fojú kan àwọn aya àti ọmọ wọn. Bí ogun náà ṣe ń bá a lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ní oko ìfúnwàrà, mo ṣe kàyéfì bóyá a óò pè mí fún iṣẹ́ ológun. Lẹ́yìn náà ni a ṣe ìkéde náà pé, a kì yóò mú àgbẹ̀ kankan kúrò lókò rẹ̀ láti lọ fún iṣẹ́ ológun mọ́.
Èmi àti Rowena ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian wa nìṣó, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ń lo wákàtí tí ó lé ní 60 lóṣooṣù nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ní àkókò yìí, mo ní àǹfààní ṣíṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n di àìdásítọ̀túntòsì Kristian wọn mú. Mo gbẹnu sọ fún wọn ní àwọn ilé ẹjọ́ ti Wellington, Àríwá Palmerston, Pahiatua àti Masterton. Mẹ́ḿbà kan nínú àwùjọ àlùfáà sábà máa ń wà nínú àjọ agbanisíṣẹ́ ológun, inú mi sì dùn láti táṣìírí ìtìlẹyìn tí kò bá ìlànà Kristian mu, tí wọ́n ń fún ìsapá ogun jíjà.—1 Johannu 3:10-12.
Ní alẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí èmi àti Rowena ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà, àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbé sùnmọ̀mí wọ ilé wa. Bí wọ́n ṣe ń tú ilé wa, wọ́n rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Wọ́n fi tó wa létí pé: “Ẹ lè lọ sẹ́wọ̀n nítorí èyí.” Nígbà tí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà wọnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn láti máa lọ, wọ́n rí i pé ìjánu ọkọ̀ náà ti há, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà kò sì lè lọ mọ́. William Manser bá wọn tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ṣe, a kò sì gbúròó àwọn ọkùnrin náà mọ́.
Nígbà tí ìkàléèwọ̀ náà ń lọ lọ́wọ́, a máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pa mọ́ sínú ilé kan, níbi tí ó jìnnà rere nínú oko wa. Láàárín òru, n óò ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka New Zealand, n óò sì kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi bámúbámú. N óò kó o wá sílé, n óò sì kó o pamọ́ sí ibi àdádó kan. Lóru ọjọ́ kan, bí mo ṣe gúnlẹ̀ sí ẹ̀ka náà láti lọ kó àwọn ẹrù kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ní bòókẹ́lẹ́, wọ́n tan iná ibẹ̀ lójijì! Ọlọ́pàá náà kígbe pé: “Ọwọ́ tẹ̀ ọ́!” Ṣùgbọ́n, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ pé, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí awuyewuye púpọ̀.
Ní 1949, èmi àti Rowena ta oko wa, a sì pinnu láti ṣe aṣáájú ọ̀nà títí tí owo wa yóò fi tán. A ṣí lọ sí ilé kan ní Masterton, a sì ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú Ìjọ Masterton. Láàárín ọdún méjì, a dá Ìjọ Featherston sílẹ̀ pẹ̀lú akéde ògbóṣáṣá 24, mo sì ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága. Nígbà tí ó di 1953, mo gbádùn àǹfààní rírin ìrìn àjò lọ sí United States láti pésẹ̀ síbi àpéjọpọ̀ àgbáyé ọlọ́jọ́ mẹ́jọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee ní Ìlú New York. Rowena kò lè bá mi lọ nítorí àtilè bójú tó ọmọbìnrin wa, Enid, ẹni tí àrùn jàm̀bá ọpọlọ ń yọ lẹ́nu.
Lẹ́yìn tí mo padà sí New Zealand, mo ní láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àjókòótì. A ṣí padà lọ sí Ìjọ Masterton, níbi tí a ti yàn mí sípò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága. Ní nǹkan bí àkókò yìí, William Manser ra Gbọ̀ngàn Ìṣeré Little ní Masterton, èyí sì di Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ ní Wairarapa. Ní àwọn ọdún 1950, ìjọ wa gbádùn ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí àti ní ti iye ènìyàn. Nítorí náà, nígbà tí alábòójútó àyíká bá ṣèbẹ̀wò, ó sábà máa ń fún àwọn tí ó dàgbà dénú níṣìírí láti ṣí lọ sí àwọn àpá mìíràn ní ìgbèríko náà, láti lè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀, àwọn kan sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìdílé wa dúró sí Masterton, ní àwọn ẹ̀wádún tí ó sì tẹ̀ lé e, kì í ṣe pé mo ní ọ̀pọ̀ àǹfààní nínú ìjọ nìkan ni, ṣùgbọ́n, mo gbádùn àwọn iṣẹ́ àyànfúnni ní àwọn àpéjọpọ̀ ti orílẹ̀-èdè àti ti àgbáyé. Rowena fi tìtaratìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, ó sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà gbogbo láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Fífara Da Àwọn Ìdánwò Ìgbàgbọ́
Bí mo ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, ní 1985, àyẹ̀wò ara mi fi hàn pé, mo ní àrùn jẹjẹrẹ tí kò gbóògùn. Ẹ wo bí èmi àti aya mi, Rowena olùṣòtítọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa, ṣe ń fẹ́ láti wà lára àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó wà láàyè nísinsìnyí, tí kì yóò kú láé tó! Ṣùgbọ́n àwọn dókítà náà ní kí n lọ kú sílé. Ṣùgbọ́n, wọ́n kọ́kọ́ bi mí pé, báwo ni mo ṣe rí àyẹ̀wò náà sí.
Mo fèsì pé: “Èmi yóò fi ọkàn balẹ̀, n óò sì lẹ́mìí pé nǹkan yóò sunwọ̀n sí i.” Ní tòótọ́, òwe Bibeli náà pé: “Ọkàn tí ó balẹ̀ ní ìyè ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara,” di ohun tí ó mú mi dúró ṣinṣin.—Owe 14:30, NW.
Àwọn ògbóǹtagí nínú ìtọ́jú arun jẹjẹrẹ gbóríyìn fún ìmọ̀ràn Bibeli yẹn. Wọ́n wí pé: “Ojú ìwòye yẹn ni ìwòsàn fún ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ.” Wọ́n tún dábàá ọ̀nà ìgbàtọ́jú onítànṣán fún ọ̀sẹ̀ méje. Mo láyọ̀ pé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo kẹ́sẹ járí ní kíkojú àrùn jẹjẹrẹ náà.
Láàárín àkókò líle koko yìí, àjálù ńlá já lù mí. Àrùn ẹ̀jẹ̀ títú sí inú ọpọlọ kọlù aya mi òrékelẹ́wà, adúróṣinṣin, ó sì kú. Mo rí ìtùnú nínú àpẹẹrẹ àwọn olùṣòtítọ́ tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ àti bí Jehofa ṣe ń yanjú ìṣòro wọn, bí wọ́n ṣe ń di ìwà títọ́ wọn mú. Nípa báyìí, ìrètí mi nínú ayé tuntun kò ṣákìí.—Romu 15:4.
Síbẹ̀síbẹ̀, mo sorí kọ́, mo sì fẹ́ láti dẹ́kun ṣíṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àwọn arákùnrin ládùúgbò fun mi níṣìírí títí mo fi ní agbára padà láti máa bá a nìṣó. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti ṣiṣẹ́ sìn láìdáwọ́dúró gẹ́gẹ́ bí Kristian alàgbà àti alábòójútó fún ọdún 57 tí ó ti kọjá.
Dídójú Kọ Ọjọ́ Ọ̀la Pẹ̀lú Ìgbọ́kànlé
Ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí ti jẹ́ àǹfààní tí kò ṣeé díye lé. Ẹ wo bí ìbùkún mi ti pọ̀ tó! Àfi bí àná, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 16, tí mo gbọ́ tí màmá mi kígbe pé: “Òun níyì; òtítọ́ nìyí!” Màmá mi dúró gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́, onítara títí tí ó fi kú ní 1979, nígbà tí ó ti lé ní ẹni 100 ọdún. Ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́fà pẹ̀lú di Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́.
Ìfẹ́ ọkàn mí tí ń jó bí iná jẹ́ láti wà láàyè láti rí, bí a óò ṣe mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jehofa. N óò ha rí ìrètí mi tipẹ́tipẹ́, ti kí n máà kù láéláé bí? Ní tòótọ́, n kò tí ì rí ìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní ìgbọ́kànlé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀, àní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ yóò nírìírí ìbùkún yẹn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tì mo bá ṣì wà láàyè, n óò máa ṣìkẹ́ ìfojúsọ́nà ti wíwà lára àwọn tí kì yóò kú láéláé.—Johannu 11:26.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Màmá mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Pẹ̀lú aya mi àti àwọn ọmọ mi