ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 3 ojú ìwé 4-5
  • Ṣé Òótọ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Òótọ́ Ni?
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
  • Ìlànà Bíbélì
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀
  • Ohun To O Lè Ṣe
  • Ṣé O Ní Ìkórìíra?
    Jí!—2020
  • A Ha Ti Ṣe Ẹ̀tanú Sí Ọ Rí Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìwà ẹ̀tanú—ìṣòro tó kárí ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 3 ojú ìwé 4-5
Àwọn ọkùnrin méjì ń fọ̀rọ̀ wá obìnrin kan lẹ́nu wò ní iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe mọ́tò. Ó jọ pé inú obìnrin yẹn ò dùn.

Ṣé Òótọ́ ni?

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Ohun tó sábà máa ń jẹ́ káwọn kan kórìíra àwọn míì ni ohun tí kì í ṣòótọ́ tí wọ́n gbọ́ nípa wọn. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí:

  • Àwọn agbanisíṣẹ́ kan gbà pé àwọn obìnrin ò lè ṣiṣẹ́ tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, iṣẹ́ agbára tàbí iṣẹ́ tó gba àròjinlẹ̀.

  • Nígbà àtijọ́ nílẹ̀ Yúróòpù, wọ́n fẹ̀sùn èké kan àwọn Júù pé wọ́n ń da májèlé sínú àwọn kànga, wọ́n sì ń mú kí àrùn tàn káàkiri. Bákan náà, nígbà ìjọba Násì, wọ́n tún fẹ̀sùn èké kan àwọn Júù. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n sọ pé àwọn ló jẹ́ kí ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Jámánì. Láwọn ìgbà méjèèjì yìí, ìyà ńlá ni wọ́n fi jẹ́ àwọn Júù. Kódà, àwọn kan ṣì ń fojú burúkú wò wọ́n títí dòní.

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé gbogbo àwọn aláàbọ̀ ara ni kì í láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń bà jẹ́.

Àwọn ẹlẹ́tanú tó gba irú ọ̀rọ̀ yìí gbọ́ máa ń tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ tàbí ẹ̀rí tó jọ pé ó bá èrò wọn mu. Wọ́n sì gbà pé aláìmọ̀kan lẹ́ni tó bá ta ko èrò wọn.

Ìlànà Bíbélì

“Kò dára kí èèyàn wà láìní ìmọ̀.”​—ÒWE 19:2.

Kí la rí kọ́? Téèyàn ò bá mọ òótọ́ ọ̀rọ̀, ìpinnu tí kò dáa lèèyàn máa ṣe. Téèyàn bá fòótọ́ sílẹ̀ tó wá gba ìtàn àròsọ gbọ́, ńṣe lá kàn máa fojú burúkú wo àwọn èèyàn.

Ṣé Bíbélì Kọ́ Wa Ní Ìkórìíra?

Àwọn kan sọ pé Bíbélì ń kọ́ni ní ẹ̀mí ìkórìíra. Àmọ́ kí ni Bíbélì sọ gangan?

  • Ibì kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá: ‘Láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.’​—Ìṣe 17:26.

  • Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Ìṣe 10:​34, 35.

  • Ọlọ́run kì í wo ìrísí èèyàn, ọkàn èèyàn ló ń wò: “Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”​—1 Sámúẹ́lì 16:7.a

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì.

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀

Tá a bá mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn èèyàn, a ò ní tètè máa gba ọ̀rọ̀ tí kò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa wọn gbọ́. Nígbà tá a bá sì ti mọ pé wọn ò sọ òótọ́ nípa àwọn èèyàn kan fún wa, a máa fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa wọn.

Ohun Tẹ́nì Kan Sọ: Jovica (Yúróòpù)

Ọkùnrin tó ń jẹ́ Jovica, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí sọ pé látọmọdé lòun ti ń gbọ́ ohun tí ò dáa nípa ẹ̀yà kan látẹnu àwọn ará ìlú òun, lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú ìròyìn. Ó sọ pé, “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀tanú sí wọn, mo sì kórìíra wọn gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, mo rò pé ohun tó dáa ni mò ń ṣe.”

“Àmọ́ nígbà tí mo wọṣẹ́ ológun, mo rí i pé àfi kí n máa bá wọn gbé kí n sì máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn torí a jọ ń ṣiṣẹ́ ológun ni. Nígbà tó yá, mo mọ ohun tó pọ̀ nípa wọn. Mo tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè wọn, mo sì ń gbọ́ orin ìlú wọn. Bó ṣe di pé a mọwọ́ ara wa nìyẹn, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tó dáa nípa wọn. Ṣùgbọ́n, mo mọ̀ pé èrò tí kò dáa ti mo ní tẹ́lẹ̀ tún lè pa dà wá. Torí náà, tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀yà yẹn láìdáa lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, mi ò kì í fetí sí i. Bákan náà, mi ò kì í wo fíìmù tàbí eré aláwàdà tó ń fi àwọn èèyàn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Mo mọ̀ pé tí mo bá ń tẹ́tí sí ohun tí kò dáa nípa wọn, ó lè mú kí n máa bínú sí wọn tàbí kí n kórìíra wọn.

Ohun To O Lè Ṣe

  • Tí wọ́n bá sọ pé ẹ̀yà kan burú, rántí pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá látinú ẹ̀yà náà ló burú.

  • Rántí pé o ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa àwọn èèyàn.

  • Sapá láti gbọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu ẹni tó ṣeé fọkàn tán.

Wọ́n ṣẹ́gun ìkórìíra

Collage: 1. Àwọn ọkùnrin méjì ń bára wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ. 2. Ọ̀kan lára wọn wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó ń rẹ́rìn-ín.

Kí ló mú kí ọmọ Árábù àti Júù kan borí ẹ̀mí ìkórìíra?

Wo fídíò Ìgbà Wo Ni Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Máa Ṣẹ́gun Ìkórìíra? Wá fídíò náà lórí ìkànnì jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́