ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • 10. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún àwọn òbí? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí,” báwo ló sì ṣe yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      10 Ọlọ́run tún fún àwọn òbí ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” lè túmọ̀ sí kí wọ́n tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó lè ṣe ohun tó tọ́. Ká sòótọ́, àwọn ọmọ nílò ìbáwí; wọ́n sábà máa ń ṣe dáadáa táwọn òbí bá fún wọn ní ìtọ́ni tó dáa, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. (Òwe 13:24) Torí náà táwọn òbí bá ń lo “ọ̀pá ìbáwí,” kò yẹ kí wọ́n máa lò ó lọ́nà tí wọ́n á fi ṣe àwọn ọmọ wọn léṣe tàbí lọ́nà tí wọ́n á fi kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn.a (Òwe 22:15; 29:15) Tí òbí kan bá ń kanra mọ́ ọmọ ẹ̀ tàbí tó le koko jù mọ́ ọn, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọmọ náà. Ìyẹn ò sì ní fi hàn pé irú òbí bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa fi hàn pé òbí náà ń ṣi agbára rẹ̀ lò. (Kólósè 3:21) Àmọ́, táwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ̀ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n á sì gbà pé ohun tó dáa làwọn òbí wọ́n fẹ́ fún wọn.

  • “Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • a Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ọ̀pá” ni wọ́n máa ń lò fún igi táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi ń da àgùntàn. (Sáàmù 23:4) Torí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé káwọn òbí fi “ọ̀pá” bá àwọn ọmọ wọn wí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, kì í ṣe pé kí wọ́n kanra mọ́ wọn tàbí kí wọ́n hùwà ìkà sí wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́