ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 24, 25. (a) Ìpè wo ni Jèhófà pè, kí sì ni ìdí tó fi dájú pé ìlérí rẹ̀ yóò ṣẹ? (b) Kí ni Jèhófà fi ẹ̀tọ́ sọ pé òun ń fẹ́?

      24 Àánú tí Jèhófà ní mú kó pe ìpè yìí pé: “Ẹ yíjú sọ́dọ̀ mi kí a sì gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin tí ń bẹ ní òpin ilẹ̀ ayé; nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn. Mo ti fi ara mi búra—ẹnu ara mi ni ọ̀rọ̀ náà ti jáde lọ nínú òdodo, tí kì yóò fi padà—pé gbogbo eékún yóò tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n yóò búra, pé, ‘Dájúdájú, inú Jèhófà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo àti okun wà. Gbogbo àwọn tí ń gbaná jẹ mọ́ ọn yóò wá tààrà sọ́dọ̀ rẹ̀, ojú yóò sì tì wọ́n. Nínú Jèhófà, gbogbo irú-ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò tọ̀nà, wọn yóò sì máa ṣògo nípa ara wọn.’”—Aísáyà 45:22-25.

  • Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 26. Báwo ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń jẹ́ ìpè Jèhófà pé kí wọ́n yíjú sí òun?

      26 Àmọ́ o, àwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ayé àtijọ́ nìkan kọ́ ni Ọlọ́run pè pé kí wọ́n yíjú sí òun. (Ìṣe 14:14, 15; 15:19; 1 Tímótì 2:3, 4) Ìpè yìí ṣì ń lọ lọ́wọ́, “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” sì ń jẹ́ ìpè yìí, tí wọ́n sì ń polongo pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa . . . àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] ni ìgbàlà wa ti wá.” (Ìṣípayá 7:9, 10; 15:4) Lọ́dọọdún, ẹgbàágbèje ẹni tuntun tó ń yíjú sí Ọlọ́run, tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kéde fáyé gbọ́ pé òun ló ni ìfọkànsìn àwọn, ló ń kún iye ogunlọ́gọ̀ yìí. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tún ń fi àìyẹhùn gbárùkù ti Ísírẹ́lì tẹ̀mí, “irú-ọmọ Ábúráhámù.” (Gálátíà 3:29) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ìṣàkóso òdodo Jèhófà nípa kíkéde kárí ayé pé: “Dájúdájú, inú Jèhófà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo àti okun wà.”a Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ọ̀rọ̀ Aísáyà 45:23 yìí ló fà yọ látinú ìtumọ̀ Septuagint nígbà tó ń fi hàn pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn gbogbo ẹní bá ń bẹ láàyè ni yóò tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run, tí yóò sì máa yin orúkọ rẹ̀ títí gbére.—Róòmù 14:11; Fílípì 2:9-11; Ìṣípayá 21:22-27.

  • Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • a Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo gbólóhùn náà, “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo,” nítorí pé ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun púpọ̀ ló wà ní ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ní èdè Hébérù. Ńṣe ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun púpọ̀ níhìn-ín láti fi gbé bí òdodo Jèhófà ṣe pọ̀ gidigidi tó yọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́