-
Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ LáúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
6. (a) Ọ̀nà wo ni ìhòòhò Bábílónì yóò gbà tú síta? (b) Báwo ni Ọlọ́run kò ṣe ní “ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Jèhófà tún gbẹ́nu lé ẹ̀sín tó ń fi í ṣe, ó ní: “Ó yẹ kí o tú ìhòòhò rẹ síta. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó yẹ kí a rí ẹ̀gàn rẹ. Èmi yóò gbẹ̀san, èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí.” (Aísáyà 47:3)c Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ yóò bá Bábílónì dandan ni. Àṣírí ìwà ibi àti ìwà ìkà tí ó ń hù sí àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò tú. Kò mà sí ọgbọ́n tí ọmọ aráyé lè ta kí ẹ̀san Ọlọ́run máà ké o!
-
-
Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ LáúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
c Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí” jẹ́ “àpólà ọ̀rọ̀ tó ṣòroó” túmọ̀ “gan-an ni.” Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi ọ̀rọ̀ náà, “ṣojú àánú,” kún un láti fi lè jẹ́ kó hàn pé kò ní sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti ti ibòmíràn wá láti wá gba Bábílónì sílẹ̀. Ìtumọ̀ Bíbélì kan, tí àwọn àjọ Jewish Publication Society ṣe, túmọ̀ àpólà ọ̀rọ̀ yìí báyìí: “Èmi . . . kì yóò gbà kí ẹnikẹ́ni bá a bẹ̀bẹ̀.”
-