ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ Láú
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Bábílónì yóò gbà rí “àdánù ọmọ àti ìgbà opó”?

      14 Ibo ni ọ̀ràn Bábílónì yóò wá yọrí sí? Jèhófà ń bọ́rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Ṣùgbọ́n nǹkan méjèèjì wọ̀nyí yóò dé bá ọ lójijì, ní ọjọ́ kan: àdánù àwọn ọmọ àti ìgbà opó. Ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n wọn ni wọn yóò dé bá ọ, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́ rẹ, nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá èèdì rẹ—lọ́nà tí ó peléke.” (Aísáyà 47:9) Dájúdájú, òjijì ni agbára àjùlọ Bábílónì, tó mú kó jẹ́ agbára ayé, yóò dópin. Ní ilẹ̀ ìhà Ìlà-Oòrùn ayé àtijọ́, àjálù tó burú jù lọ fún obìnrin ni pé kí ó di opó kí ó sì tún ṣòfò ọmọ. A ò mọ iye “ọmọ” tí Bábílónì pàdánù lálẹ́ ọjọ́ tó ṣubú.d Ṣùgbọ́n ìlú yẹn yóò sáà padà dá páropáro ni lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Jeremáyà 51:29) Yóò tún di opó ní ti pé wọn yóò yẹ àga mọ́ àwọn ọba rẹ̀ nídìí.

      15. Láfikún sí ìwà ìkà tí Bábílónì hù sí àwọn Júù, ìdí mìíràn wo tún ni Jèhófà fi bínú sí Bábílónì?

      15 Ṣùgbọ́n o, tìtorí pé Bábílónì ṣe àwọn Júù ṣúkaṣùka nìkan kọ́ ló fa ìbínú Jèhófà. “Ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́” rẹ̀ tún bí i nínú pẹ̀lú. Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ka ìbẹ́mìílò léèwọ̀; ṣùgbọ́n ńṣe ni Bábílónì tara bọ ẹgbẹ́ adáhunṣe lójú méjèèjì. (Diutarónómì 18:10-12; Ìsíkíẹ́lì 21:21) Ìwé náà Social Life Among the Assyrians and Babylonians sọ pé ‘ìfòyà ẹgbàágbèje iwin tí àwọn ará Bábílónì gbà pé ó yí àwọn ká kì í tán lára wọn nígbàkigbà lọ́jọ́ ayé wọn.’

  • Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ Láú
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • d Ìwé Nabonidus and Belshazzar, tí Raymond Philip Dougherty kọ, sọ pé lóòótọ́ Àkọsílẹ̀ Ìtàn Nábónídọ́sì sọ pé ńṣe làwọn tó ṣígun wá sí Bábílónì kàn wọ̀lú “láìsí ìjà,” àmọ́ ọmọ Gíríìkì òpìtàn náà, Sẹ́nófọ̀n, fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí iye ẹ̀mí tó ṣòfò máà kéré.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́