ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 6. Ọ̀nà wo ni ẹnu Mèsáyà gbà dà bí idà mímú, báwo ni Jèhófà ṣe pa Mèsáyà yìí mọ́?

      6 Mèsáyà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ẹnu mi bí idà mímú. Inú òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi mí pa mọ́ sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ mí di ọfà dídán. Ó tọ́jú mi pa mọ́ sínú apó tirẹ̀.” (Aísáyà 49:2) Nígbà tí àsìkò tó tí Jésù, Mèsáyà Jèhófà, yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, ńṣe ni ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ dà bí àwọn ohun ìjà mímú tó ń dán, tó lè wọlé ṣinṣin sínú ọkàn àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 4:31, 32) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀ sì bí Sátánì, ọ̀tá Jèhófà paraku, àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nínú. Látìgbà ìbí Jésù ni Sátánì ti ń sapá láti gbẹ̀mí Rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ọfà tí Jèhófà fi pa mọ́ sínú apó tirẹ̀ ni Jésù jẹ́.a Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ pé ààbò Baba òun ń bẹ lórí òun. (Sáàmù 91:1; Lúùkù 1:35) Nígbà tí àkókò tó, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ọmọ aráyé. Ṣùgbọ́n ìgbà ń bọ̀ tí yóò jáde lọ bí akọni jagunjagun ọ̀run tó dìhámọ́ra lọ́nà tó yàtọ̀, tòun ti idà mímú tí ń jáde lẹ́nu rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, idà mímú yẹn dúró fún àṣẹ tí Jésù ní láti kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọ̀tá Jèhófà, àti láti mú ìdájọ́ yẹn ṣẹ.—Ìṣípayá 1:16.

  • “Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • a “Ó dájú pé, gbogbo ipá ni Sátánì sà láti sáà rẹ́yìn Jésù, níwọ̀n bó ti mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ló jẹ́, àti pé òun ni ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò pa òun ní orí. (Jẹ 3:15) Ṣùgbọ́n nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ń sọ fún Màríà nípa bí yóò ṣe lóyún Jésù, ó sọ fún un pé: ‘Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.’ (Lk 1:35) Jèhófà fi ìṣọ́ ṣọ́ Ọmọ rẹ̀. Gbogbo ìsapá láti rẹ́yìn Jésù ní rèwerèwe sì já sí pàbó.”—Ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ewé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́jọ [868], tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́