-
Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ GaÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
21, 22. (a) Kí ni Mèsáyà bá àwọn ẹlòmíràn gbé, kí ló sì bá wọn rù? (b) Irú ojú wo ni ọ̀pọ̀ fi wo Mèsáyà, kí sì ni ìjìyà rẹ̀ yọrí sí?
21 Kí wá nìdí tí Mèsáyà fi ní láti jìyà kí ó sì kú? Aísáyà ṣàlàyé pé: “Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé; àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n. Ṣùgbọ́n àwa fúnra wa kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọlù, tí ó sì ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n a gún un nítorí ìrélànàkọjá wa; a ń tẹ̀ ẹ́ rẹ́ nítorí àwọn ìṣìnà wa. Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀, àti nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa. Gbogbo wa ti rìn gbéregbère bí àgùntàn; olúkúlùkù wa ni ó ti yíjú sí bíbá ọ̀nà ara rẹ̀ lọ; Jèhófà alára sì ti mú kí ìṣìnà gbogbo wa ṣalábàápàdé ẹni yẹn.”—Aísáyà 53:4-6.
22 Mèsáyà gbé àìsàn àwọn ẹlòmíràn, ó sì ru ìrora wọn. Ó gbé ẹrù ìnira wọn kúrò lórí wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó gbé e lé èjìká tirẹ̀, ó sì bá wọn rù ú. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ tí aráyé jẹ́ ló fa àìsàn àti ìrora fún wọn, bí Mèsáyà ṣe gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ni kò mọ ìdí tó fi ń jìyà, wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run ń jẹ ẹ́ níyà ni, tó ń fi àrùn burúkú yọ ọ́ lẹ́nu.c Kódà àwọn ọ̀rọ̀ líle tó ń fi hàn pé Mèsáyà yóò kú ikú gbígbóná àti ikú oró ni ibí yìí lò, ó ní ó jìyà débi pé wọ́n gún un ní nǹkan, wọ́n tẹ̀ ẹ́ rẹ́, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára. Àmọ́, kíkú tó kú yìí pàápàá, ó fi ṣètùtù ni; ó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún jíjèrè àwọn tó ń rìn gbéregbère nínú ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ padà, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.
-
-
Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ GaÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
24. (a) Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, kí ló dé tó fi jọ pé Ọlọ́run ló kó “ìyọnu bá” Jésù? (b) Kí ni ìdí tí Jésù fi jìyà tó sì kú?
24 Síbẹ̀ o, lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ṣe ló jọ pé Ọlọ́run ló kó “ìyọnu bá” Jésù. Ṣebí àwọn sàràkí-sàràkí nínú àwọn aṣáájú ìsìn ló sáà lé àwọn èèyàn lóro tí wọ́n fi fìyà jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n, ká rántí pé kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí wọ́n fi ń jẹ ẹ́ níyà o. Pétérù sọ pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀. Òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí òpó igi, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, kí a sì wà láàyè sí òdodo. Àti pé ‘nípa ìnà rẹ̀ ni a mú yín lára dá.’” (1 Pétérù 2:21, 22, 24) Gbogbo wa ló jẹ́ pé àsìkò kan wà tí a ṣèranù lọ nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá, “bí àwọn àgùntàn, tí ń ṣáko lọ.” (1 Pétérù 2:25) Àmọ́ Jèhófà lo Jésù láti fi pèsè ìràpadà fún wa kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀. Jèhófà mú kí ìṣìnà wa “ṣalábàápàdé” Jésù, kí Jésù sì rù ú. Ńṣe ni Jésù aláìṣẹ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti gba ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ. Nígbà tó sì ti jẹ ìyà tí kò tọ́ sí i, ní ti pé ó kú ikú ẹ̀sín lórí igi oró, ó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bá Ọlọ́run rẹ́ padà.
-