ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 18. Kí ni yóò ṣẹ́ kù fún àwọn tó kẹ̀yìn sí Jèhófà, kí sì ni lílò tí a óò máa lo orúkọ wọn láti fi búra ṣeé ṣe kí ó túmọ̀ sí?

      18 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ sáwọn tó kẹ̀yìn sí i lọ, ó ní: “Dájúdájú, ẹ ó sì to orúkọ yín jọ fún ìbúra nípasẹ̀ àwọn àyànfẹ́ mi, ṣe ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò sì fi ikú pa yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ ni yóò fi orúkọ mìíràn pè; tí yóò fi jẹ́ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń súre fún ara rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́ súre fún ara rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń sọ gbólóhùn ìbúra ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́ búra; nítorí pé àwọn wàhálà àtijọ́ ni a ó gbàgbé ní ti tòótọ́ àti nítorí pé a ó fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 65:15, 16) Orúkọ lásán ni yóò ṣẹ́ kù fún àwọn tó kẹ̀yìn sí Jèhófà, ìyẹn orúkọ láti kàn máa fi búra, tàbí láti máa fi gégùn-ún. Èyí lè túmọ̀ sí pé, ńṣe ni àwọn tó bá fẹ́ búra láti fi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọmọnìkejì wọn yóò sọ pé: ‘Bí mi ò bá mú ẹ̀jẹ́ mi yìí ṣẹ kí ìyà tó jẹ àwọn apẹ̀yìndà yẹn jẹ mi.’ Ó tiẹ̀ lé túmọ̀ sí pé orúkọ wọn yóò di lílò lọ́nà àpèjúwe bíi ti Sódómù àti Gòmórà, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìyà àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run yóò fi jẹ àwọn olubi.

      19. Báwo la ó ṣe fi orúkọ mìíràn pe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kí sì nìdí tí wọ́n ó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ìṣòtítọ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé pẹ̀lú.)

      19 Ọ̀ràn ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mà kúkú yàtọ̀ sí tiwọn o! Orúkọ mìíràn la ó fi pè wọ́n. Ìyẹn dúró fún ipò aásìkí àti iyì tí wọn yóò bọ́ sí ní ìlú ìbílẹ̀ wọn lọ́hùn-ún. Wọn kò ní tọ òrìṣà èyíkéyìí lọ láti tọrọ aásìkí, wọn kò sì ní fi ère aláìlẹ́mìí kankan búra. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá ń súre tàbí bí wọ́n bá ń búra, Ọlọ́run ìṣòtítọ́ ni wọn yóò fi búra. (Aísáyà 65:16, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ yẹn yóò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, nítorí yóò ti mu àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ lóòótọ́.c Kò sì ní pẹ́ táwọn Júù yóò fi gbàgbé ìpọ́njú àtẹ̀yìnwá bí ìfọ̀kànbalẹ̀ bá ti wà fún wọn ní ìlú ìbílẹ̀ wọn.

  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • c Nínú ìwé ti àwọn Másórẹ́tì tó jẹ́ èdè Hébérù, Aísáyà 65:16 sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tí í ṣe Àmín.” “Àmín” túmọ̀ sí “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “ó ti dájú,” ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé èèyàn fara mọ́ ohun tó gbọ́ tàbí pé ó dáni lójú pé ohun kan jẹ́ òótọ́ tàbí pé yóò ṣẹ dájúdájú. Bí Jèhófà sì ṣe mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ńṣe ló fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ òun.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́