ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
    • Bó ṣe rí i pé kò sóun tóun lè ṣe sí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀, ó lọ wábì kan sùn sí nínú ọkọ̀ náà. Ó sì sùn lọ fọnfọn.b Ọ̀gákọ̀ náà rí i níbi tó sùn sí, ló bá jí i pé kóun náà gbàdúrà sí ọlọ́run tiẹ̀ náà. Àwọn atukọ̀ òkun náà ti wá rí i pé ìjì tó ń jà náà kì í ṣe ojú lásán, wọ́n bá ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó fa ìṣòro náà. Ó dájú pé ọkàn Jónà á ti máa lù kìkì bí wọ́n ṣe ń dárúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kàn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Nígbà tó yá, àṣírí tú. Torí Jónà ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìjì náà jà, òun náà sì ni kèké mú!—Jónà 1:5-7.

  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
    • b Bíbélì Septuagint sọ pé Jónà hanrun, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ bó ṣe sùn wọra tó. Àmọ́, kò ní dáa tá a bá rò pé torí kí Jónà má bàa dá sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ló ṣe lọ wábi sùn sí, a lè rántí pé nígbà míì oorun máa ń kun àwọn tó bá rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà tí Jésù wà lọ́gbà Gẹtisémánì lákòókò tí nǹkan ò rọrùn fún un, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù “ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Lúùkù 22:45.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́