Ó Ha Gbé Jona Mì Bi?
BIBELI sọ fun wa pe Jona, wolii Jehofa ni ọrundun kẹsan-an B.C.E., ní sísá fun iṣẹ-ayanfunni kan, wọ ọkọ̀ oju-omi kan. Lakooko irin-ajo oju-omi oníjì líle ní Meditereniani, ẹgbẹ́ atukọ̀ naa tì í sinu omi. “Oluwa ti pese ẹja ńlá kan lati gbé Jona mì. Jona sì wà ninu ẹja naa ni ọ̀sán mẹta ati òru mẹta.”—Jona 1:3-17.
Awọn kan sọ pe, ‘Kò ṣeeṣe! Kò sí iṣẹda kan ninu òkun ti ó lè gbé eniyan mì.’ Ṣugbọn yálà ẹja àbùùbùtán ńlá kan tabi ekurá funfun titobi kan lè ṣe bẹẹ. Iwe National Geographic (December 1992) pese iṣeeṣe miiran—ẹja ekurá gbigborin. Ekurá titobi julọ ti a mọ̀, ó lè dagba tó 20 mita (70 ẹsẹ bata) ní gígùn ó sì lè wọn 70 tọọnu.
“Kúlẹ̀kúlẹ̀ àyẹ̀wò òòlọ̀ ounjẹ inu ẹja ekurá ńlá naa ṣe wẹ́kú fun ìtàn Jona. Ó rọrùn lati ronu pe ẹja ekurá ńlá yii sọ ọ́ mì pàkà lairotẹlẹ gba ẹnu rẹ̀ ti o tobi gidigidi . . . Ẹnu gbàràmù ẹja ekurá ti kò tíì dagba pupọ ju paapaa lè fi tirọrun-tirọrun gba Jona meji.”
Ẹja ekurá ńlá naa ń jẹ plankton ati krill tín-ín-tìn-ìn-tín, eyi ti “ń ṣàn lọ si isalẹ ọ̀nà-ọ̀fun lọ sinu ile-ounjẹ ńlá tí ń ràn bọ̀n-ùn eyi ti o jẹ́ ikùn ti ó wà lẹgbẹẹ ọkan-aya.” Sibẹ, bawo ni ẹnikan ṣe lè jade? Iwe-irohin National Geographic sọ pe: “Awọn ẹja ekurá ní ọ̀nà alailepanilara tí wọn lè gbà pọ awọn ohun ti kò dájú pe ó lè dà ninu wọn ti wọn bá gbé mì . . . Ẹja ekurá kan lè pọ ohun ti ó wà ninu ikùn rẹ̀ ti o wà lẹgbẹẹ ọkan-aya jade diẹdiẹ nipa yíyí inú rẹ̀ sóde ati títì í jade gba ẹnu rẹ̀. . . . Nitori naa, iwọ lè jade wọ́ọ́rọ́wọ́ gba ori ìtẹ́nú ikùn rẹ̀ tí ohun ayọ́gbọ̀lọ̀ bò latokedelẹ, ara rẹ lè yọ̀ jù ṣugbọn boya yoo tubọ mu ki o jẹ́ ọlọgbọn bi o ti kẹkọọ ohun kan lati inu iriri naa.”
Lonii awọn ẹja ekurá gbigborin ni a kò rí ninu Meditereniani, bi o tilẹ jẹ pe a ti rí wọn ni iha ariwa jijinna bii New York City. Wọn ha wà ninu Meditereniani ni akoko Jona bi? Ta ni lè sọ? Bibeli kò sọ pàtó iru iṣẹda òkun ti Jehofa lò, ṣugbọn Jesu funraarẹ jẹrii sii pe akọsilẹ Jona jẹ otitọ.—Matteu 12:39, 40.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Norbert Wu/Peter Arnold Inc.