ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • 15, 16. (a) Báwo ni Míkà ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà? (b) Kí ni ‘ríré tí Ọlọ́run ń ré ìṣìnà kọjá’ túmọ̀ sí?

      15 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini la fẹ́ fara wé. (Éfésù 4:32–5:1) Ní ti ọ̀nà tí Òun ń gbà jẹ́ kí ọ̀ràn parí, wòlíì Míkà kọ̀wé pé: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, ẹni tí ń dárí ìrélànàkọjá jì, tí ó sì ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Míkà 7:18.

      16 Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ‘ń ré ìṣìnà kọjá’, kò sọ pé kò lè rántí ìwà àìtọ́, kò sọ ọ́ dẹni tí iyè rẹ̀ ti ra. Gbé ọ̀ràn Sámúsìnì àti Dáfídì yẹ̀ wò, àwọn méjèèjì ló dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Ọlọ́run rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kódà lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti ṣẹ̀; ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ díẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí pé Jèhófà mú ká kọ wọn sínú Bíbélì. Síbẹ̀, Ọlọ́run wa tí ń dárí jini ṣàánú àwọn méjèèjì, ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ táa lè fara wé.—Hébérù 11:32; 12:1.

      17. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ré àṣìṣe, tàbí ohun táwọn ẹlòmíràn ṣe tó dùn wá kọjá? (b) Báa bá gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lé fara wé Jèhófà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      17 Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti ‘ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá,’a àní gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti rọ̀ ọ́ léraléra láti ṣe. (2 Sámúẹ́lì 12:13; 24:10) Ṣé a lè fara wé Ọlọ́run nínú èyí, nípa gbígbà láti ré ohun tí kò tó nǹkan táwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa ṣe sí wa kọjá àti èyí tí wọ́n ṣe to dùn wá, nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìpé? Gbà pé o wà nínú ọkọ̀ òfuurufú kan tó ń sáré geerege lórí ilẹ̀ kó tó gbéra. Yíyọjú tóo yọjú lójú fèrèsé ọkọ̀, lo bá rí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣe húù, ọ̀ọ́-bì, ọ̀ọ́-bì, bí ìgbà tọ́mọdé bá ń fínràn. O mọ̀ pé inú ló ń bí i, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ gan-an ló ń bá wí. Ó sì lè jẹ́ pé kò ronú kàn ọ́ rárá o. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, bí bàlúù náà ti ń pòòyì kó bàa lè fò lókè dáadáa, o ti ré obìnrin yìí kọjá ní tìrẹ, lo bá ń wò ó nísàlẹ̀-nísàlẹ̀, kò wá ju eèrà lọ mọ́. Láàárín wákàtí kan, ibi tóo ti fi jìnnà sí i ti tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀, oò rí gbogbo húù, ọ̀ọ́-bì, ọ̀ọ́-bì tó ń ṣe lẹ́ẹ̀kan mọ́, oò rí gbogbo ìwà rẹ̀ tó ń bí ẹ nínú yẹn mọ́. Bákan náà, báa bá gbìyànjú láti fara wé Jèhófà, ká sì fi ọgbọ́n ré ìwà tẹ́nì kan hù tó dùn wá kọjá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè dárí jini. (Òwe 19:11) Lọ́dún mẹ́wàá síbi táa wà yìí tàbí táa bá fi máa lo igba ọdún nínú Ẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀ yìí, ǹjẹ́ ìwà ẹ̀gàn náà kò ti ni di ohun tí kò tó nǹkan? Kí ló wá dé tóò fi gbójú fò ó?

  • Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ àfiwé tó jẹ̀ ti èdè Hébérù táa lò nínú Míkà 7:18 wá “láti inú ìwà arìnrìn-àjò kan tó kàn ń kọjá lọ ní tirẹ̀, tí kò mọ̀ pé ohun kan wà níbì kan, nítorí tí kò fiyè sí i. Kì í ṣe pé àpèjúwe yìí ń sọ pé, Ọlọ́run kì í kíyè sí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn bá dá o, tàbí pé ó ń fojú kékeré wò ó tàbí pé o kà á sí ohun tí kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n ohun tó ń sọ ni pé nínú àwọn ọ̀ràn kan, Ọlọ́run kì í kíyè sí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú èrò àtifìyàjẹni; nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ kò ní fìyà jẹni, ṣe ni yóò dárí jini.”—Onídàájọ́ 3:26; 1 Sámúẹ́lì 16:8.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́