-
“Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
-
-
13. Kí ni ìwé Ìṣípayá 18:7 fi hàn pé aṣẹ́wó náà tàbí Bábílónì Ńlá ń ṣe, títí kan ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
13 Ẹ̀kẹta, ẹkún àti ìpayínkeke. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ańgẹ́lì bá ti di àwọn èpò jọ? Nígbà tí Jésù ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò, ó sọ pé: “Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.” (Mát. 13:42) Ṣé ìyẹn ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí? Rárá. Ní báyìí ná, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá kan aṣẹ́wó náà tàbí Bábílónì Ńlá, ń sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í sì í ṣe opó, èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.” (Ìṣí. 18:7) Òótọ́ ni pé ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gbà pé ọwọ́ òun ni àṣẹ wà, ó tiẹ̀ tún ń ṣe bí ọba lórí àwọn olóṣèlú. Ní báyìí ná, àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò kò sunkún, ṣe ni wọ́n ń yan fanda kiri. Àmọ́, nǹkan ò ní pẹ́ yí pa dà.
Àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn olóṣèlú máa tó wá sópin (Wo ìpínrọ̀ 13)
14. (a) Ìgbà wo làwọn Kristẹni afàwọ̀rajà máa payín keke, kí sì nìdí? (b) Báwo ni òye tuntun tá a ní nípa Mátíù 13:42 ṣe bá ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 112:10 mu? (Wo àfikún àlàyé.)
14 Nígbà ìpọ́njú ńlá, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa gbogbo ìsìn èké run, àwọn tó ń ṣe ìsìn wọ̀nyẹn á máa wá ibi tí wọ́n á forí pa mọ́ sí, àmọ́ ẹ̀pa kò ní bóró mọ́. (Lúùkù 23:30; Ìṣí. 6:15-17) Nígbà tí wọ́n bá rí i pé kò sí ibi táwọn lè sá sí mọ́, wọ́n á wá máa sunkún kíkorò, wọ́n á sì máa payín keke bí inú ṣe ń bí wọn. Ìgbà yẹn ni wọ́n á máa “lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn,” bí Jésù ṣe sọ pé wọ́n máa ṣe lákòókò ìpọ́njú ńlá.e—Mát. 24:30; Ìṣí. 1:7.
15. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èpò, ìgbà wo ló sì máa ṣẹlẹ̀?
15 Ẹ̀kẹrin, gbígbé wọn sọ sínú ìléru oníná. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èpò tí wọ́n dì jọ? Àwọn ańgẹ́lì máa “gbé wọn sọ sínú ìléru oníná.” (Mát. 13:42) Ìparun yán-án-yán-án nìyẹn túmọ̀ sí. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn tó ti ń ṣe ìsìn èké run nínú apá tó máa kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, ìyẹn ogun Amágẹ́dọ́nì.—Mál. 4:1.
-
-
“Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
-
-
e Ìpínrọ̀ 14: Òye tuntun lèyí jẹ́ nípa Mátíù 13:42. Tẹ́lẹ̀, a sọ nínú àwọn ìwé wa pé àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà yìí ti ń sunkún tí wọ́n sì ń payín keke fún ọ̀pọ̀ ọdún torí bí “àwọn ọmọ Ìjọba náà” ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà” ni wọ́n jẹ́. (Mát. 13:38) Àmọ́ o, ẹ kíyè sí i pé ìgbà tí Ọlọ́run bá máa pa wọ́n run ni wọ́n tó máa payín keke.—Sm. 112:10.
-