ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • Àwọn Alájọgbáyé Yóò Rí I

      11. Kí ni Jésù sọ nípa “ìran yìí”?

      11 Ọ̀pọ̀ Júù ló gbà gbọ́ pé ọ̀nà ìgbàjọ́sìn wọn, èyí tí wọ́n gbé ka lílọ sí tẹ́ńpìlì, yóò máa bá a lọ títí ayé. Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ . . . yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ . . . pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà.”—Mátíù 24:32-35.

      12, 13. Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn lóye pé ó jẹ́ “ìran yìí” tí Jésù sọ nípa rẹ̀?

      12 Ní àwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 66 Sànmánì Tiwa, ó dájú pé àwọn Kristẹni yóò ti rí ìmúṣẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀ka àmì alápá púpọ̀ náà—ogun, ìyàn, àní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà lọ́nà gbígbòòrò pàápàá. (Ìṣe 11:28; Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n, nígbà wo ni òpin náà yóò dé? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: ‘Ìran yìí [ge·ne·aʹ lédè Gíríìkì] kì yóò kọjá lọ’? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti pe àwọn Júù alátakò tí wọ́n jẹ́ alájọgbáyé rẹ̀, títí kan àwọn aṣáájú ìsìn, ní ‘ìran burúkú onípanṣágà.’ (Mátíù 11:16; 12:39, 45; 16:4; 17:17; 23:36) Nítorí náà, nígbà tó wà lórí Òkè Ólífì, tó tún sọ nípa “ìran yìí,” ó dájú pé kì í ṣe gbogbo ìran àwọn Júù jálẹ̀ ìtàn ló ní lọ́kàn; kì í sì í ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́.” (1 Pétérù 2:9) Jésù kò sì tún sọ pé “ìran yìí” jẹ́ àkókò kan pàtó.

      13 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Júù alátakò ni Jésù ní lọ́kàn, àwọn tó jẹ́ pé nígbà náà lọ́hùn-ún wọ́n rí ìmúṣẹ àmì tó fún wọn. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Joel B. Green ń sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́kasí tó wà lórí “ìran yìí” nínú Lúùkù 21:32, ó sọ pé: “Nínú ìwé Ìhìn Rere Kẹta, ‘ìran yìí’ (àti àwọn ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ọn) sábà máa ń dúró fún àwùjọ èèyàn kan tí wọ́n lòdì sí ète Ọlọ́run. . . . [Ó ń tọ́ka] sáwọn èèyàn tí oríkunkun mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ète Ọlọ́run.”b

      14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí “ìran” yẹn, ṣùgbọ́n kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni?

      14 Ìran búburú, ìran àwọn Júù alátakò tí wọ́n rí àmì náà tó nímùúṣẹ ni yóò tún rí òpin náà. (Mátíù 24:6, 13, 14) Wọ́n sì rí i lóòótọ́! Lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá, Titus, ọmọ Olu Ọba Vespasian, ló kó wọn wá. Ìyà tó jẹ àwọn Júù tí wọ́n ká mọ́nú ìlú náà kò ṣeé fẹnu sọ.c Flavius Josephus tó fojú ara rẹ̀ rí ohun tó ṣẹlẹ̀ ròyìn pé nígbà tí àwọn ará Róòmù fi máa pa ìlú náà run, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gọ́ta Júù [1,100,000] ló ti kú, wọ́n sì ti kó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] nígbèkùn, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lebi máa tó pa kú tàbí kí wọ́n kú sínú gbọ̀ngàn ìwòran àwọn ará Róòmù. Lóòótọ́, ìpọ́njú tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa ni èyí tó burú jù lọ nínú ìtàn Jerúsálẹ́mù àti ètò àwọn Júù, kò sì tún sírú ẹ̀ mọ́ nínú ìtàn wọn. Ẹ wá wo bí ìyọrísí rẹ̀ ti yàtọ̀ tó fáwọn Kristẹni tí wọ́n ti kọbi ara sí ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jésù, tí wọ́n sì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù kógun wọn lọ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa! Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “àwọn àyànfẹ́” ni a “gbà là,” tàbí ni a pa mọ́, lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.—Mátíù 24:16, 22.

  • “Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • b Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, G. R. Beasley-Murray, sọ pé: “Kò yẹ kí ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” fa ìṣòro fún àwọn alálàyé Bíbélì rárá. Níwọ̀n ìgbà táa ti gbà pé nínú ìtumọ̀ Gíríìkì ìgbàanì genea túmọ̀ sí ìbímọ, irú-ọmọ, tó sì lè wá túmọ̀ sí ìran, . . . nínú ìtumọ̀ [ti Gíríìkì Septuagint] a sábà ń túmọ̀ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Hébérù náà, dôr, tó túmọ̀ sí sànmánì, sànmánì ìran ènìyàn, tàbí ìran ní ìtumọ̀ ti àwọn alájọgbáyé. . . . Nínú àwọn ọ̀rọ̀ táa sọ pé Jésù sọ, ó dà bí ẹni pé ọ̀rọ̀ náà nítumọ̀ méjì: lọ́nà kan ó máa ń tọ́ka sí àwọn alájọgbáyé rẹ̀, lọ́nà kejì ẹ̀wẹ̀ ó sábà máa ń túmọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìbániwí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́