-
Àwọn Ẹ̀bùn Tó Tọ́ Sí ỌbaIlé Ìṣọ́—2015 | March 1
-
-
Ibo ni wọ́n ti ń rí àwọn èròjà atasánsán tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí? Àwọn ibi tá a wá mọ̀ sí Ṣáínà, Íńdíà àti Sri Lanka lóde òní ni wọ́n ti ń rí álóè, kaṣíà àti sínámónì. Ara àwọn igi àti igbó tó wà ní aṣálẹ̀ gúúsù Arébíà títí lọ dé Sòmálíà nílẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti ń rí òjíá àti oje igi tùràrí. Àwọn ará Íńdíà ló ń ṣe èròjà náádì tàbí sípíkénádì, agbègbè Himalayas ni wọ́n sì ti ń rí i.
-