-
Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára MàríàIlé Ìṣọ́—2009 | January 1
-
-
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ ni Jósẹ́fù àti Màríà. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Lára àwọn ẹ̀rí díẹ̀ tá a rí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù jẹ́ ká mọ̀ pé ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tí Màríà bímọ, òun àti Jósẹ́fù lọ sí tẹ́ńpìlì láti lọ rúbọ bí òfin ṣe sọ, “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” ni wọ́n sì mú dání.a (Lúùkù 2:22-24) Àwọn tó bá kúṣẹ̀ẹ́ débi pé wọn ò lè rówó ra ọmọ àgùntàn nìkan ni wọ́n máa ń gbà láyè láti firú nǹkan tí wọ́n mú wá yìí rúbọ. Torí náà, ọ̀ràn àtijẹ àtimu ò rọrùn fún Jósẹ́fù àti Màríà. Síbẹ̀, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìdílé wọn. Kò sì sí àníàní pé ọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún jù lọ.—Diutarónómì 6:6, 7.
-
-
Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára MàríàIlé Ìṣọ́—2009 | January 1
-
-
a Wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ wọ̀nyẹn ṣe ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. (Léfítíkù 12:6, 8) Bí Màríà sì ṣe rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé, ó gbà pé bíi ti gbogbo èèyàn aláìpé tó kù, òun náà ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́.— Róòmù 5:12.
-