-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | November
-
-
Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó kìlọ̀ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni nínú wọn má ṣe máa wá ipò ọlá. Ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni a ń pè ní àwọn Olóore. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.”—Lúùkù 22:25, 26.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | November
-
-
Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀”? Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kí wọ́n má lọ́wọ́ sóhun tó lè ṣe àwọn aráàlú láǹfààní tàbí kí wọ́n má rí tàwọn èèyàn rò? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí Jésù fẹ́ tẹnu mọ́ ni ohun tó ń mú káwọn èèyàn máa ṣe oore.
Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn olówó máa ń fẹ́ káwọn èèyàn kan sárá sí wọn. Torí náà, wọ́n máa ń ṣe agbátẹrù àwọn eré ìdárayá àtàwọn géèmù ní gbọ̀ngàn ìwòran, wọ́n máa ń kọ́ tẹ́ńpìlì àtàwọn ibi téèyàn ti lè gbafẹ́, wọ́n sì máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì. Àmọ́, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn, wọ́n fẹ́ lókìkí tàbí káwọn èèyàn dìbò fún wọn. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tinútinú làwọn kan fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí, síbẹ̀ torí àǹfààní tí wọ́n máa rí ni ọ̀pọ̀ fi ń ṣe é.” Irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra fún.
Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọ̀làwọ́. Ó kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́r. 9:7..
-