ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Ń tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
    • 8. Báwo làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ní Pẹ́ńtíkọ́sì ṣe fi hàn pé àwọn mọ ọ̀nà tí Kristi ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn?

      8 Àtìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Kristi tó ti jíǹde náà ti ń lo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti máa bọ́ àwọn ẹni àmì òróró yòókù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ka Ìṣe 2:41, 42.) Èyí sì ṣe kedere sí àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n di Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́jọ́ yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn fún wọn láti máa “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “bá a lọ ní fífi ara wọn fún,” lè túmọ̀ sí pé “kéèyàn fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú nǹkan, tàbí kéèyàn pa gbogbo ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí nǹkan.” Ebi tẹ̀mí ń pa àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni náà, wọ́n sì mọ ibi tó yẹ kí wọ́n lọ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi gbára lé àwọn àlàyé táwọn àpọ́sítélì ṣe nípa àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù. Wọ́n sì fara mọ́ àwọn òye tuntun lórí ìtúmọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù.c—Ìṣe 2:22-36.

  • Jésù Ń tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́—2013 | July 15
    • c Ìpínrọ̀ 8: Níwọ̀n bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ti ń “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì,” ó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì máa ń kọ́ àwọn èèyàn déédéé. Díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì yìí ló wá di ara Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́