ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù
    Ilé Ìṣọ́—2012 | January 15
    • 8, 9. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà ìrìn àjò rẹ̀?

      8 Kí la lè rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gbéra ìrìn àjò lọ sí Éṣíà ni ẹ̀mí Ọlọ́run tó darí rẹ̀. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sì ti dé ìtòsí Bítíníà ni Jésù tó fún un ní ìtọ́ni síwájú sí i. Sì tún kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé Tíróásì ni Jésù tó darí rẹ̀ pé kó lọ sí Makedóníà. Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Ọlọ́run lè darí àwa náà lọ́nà tó fara jọ èyí. (Kól. 1:18) Bí àpẹẹrẹ, o lè ti máa ronú pé wàá fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí kó o lọ sí àgbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àfojúsùn rẹ ni Jésù máa tó fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ. Wo àpèjúwe yìí ná: Kí awakọ̀ kan tó lè darí ọkọ̀ sọ́tùn-ún tàbí sósì, ọkọ̀ náà gbọ́dọ̀ wà lórí ìrìn. Bákan náà, Jésù lè fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa láti mọ bí a ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, àmọ́, ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti sapá gidigidi kí ọwọ́ wa lè tẹ àfojúsùn náà.

  • Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù
    Ilé Ìṣọ́—2012 | January 15
    • 10. Kí ló fi hàn pé ká lè máa wà lójúfò, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àdúrà jẹ wá lọ́kàn?

      10 Ní báyìí, ronú nípa ẹ̀kọ́ kejì tá a lè rí kọ́ nípa bá a ṣe lè máa ṣọ́nà látinú àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin wa ní ọ̀rúndún kìíní: Wọ́n wà lójúfò, wọ́n sì jẹ́ kí àdúrà jẹ àwọn lọ́kàn. (1 Pét. 4:7) Ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà. Rántí pé kí wọ́n tó wá mú Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó sọ fún mẹ́ta nínú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.”—Mát. 26:41.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́