-
“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, ó jọ pé ó mẹ́nu kan àwọn ọrẹ tó mú wá láti ilẹ̀ Yúróòpù. Ó dájú pé inú àwọn ará yẹn máa dùn gan-an láti mọ̀ pé àwọn ará tó ń gbé láwọn apá ibi tó jìnnà gan-an nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn alàgbà náà gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo”! (Ìṣe 21:20a) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fara da àjálù tàbí àìsàn tó le gan-an. Tá a bá ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a sì fún wọn níṣìírí tó bọ́ sákòókò, ara máa tù wọ́n gan-an.
Ọ̀pọ̀ Ṣì “Ní Ìtara fún Òfin” (Ìṣe 21:20b, 21)
6. Ìṣòro wo ni wọ́n fi tó Pọ́ọ̀lù létí?
6 Àwọn alàgbà yẹn wá sọ fún Pọ́ọ̀lù pé ìṣòro kan wà ní Jùdíà, orí ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ náà dá lé. Wọ́n ní: “Arákùnrin, wo bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ tó wà láàárín àwọn Júù ṣe pọ̀ tó, gbogbo wọn ló sì ní ìtara fún Òfin. Àmọ́ wọ́n ti gbọ́ àhesọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo Júù tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n kẹ̀yìn sí Mósè, tí ò ń sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn.”a—Ìṣe 21:20b, 21.
7, 8. (a) Èrò tí kò tọ́ wo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà ní? (b) Kí nìdí tí èrò tí kò tọ́ táwọn kan lára àwọn Júù tó di Kristẹni ní ò fi sọ wọ́n di apẹ̀yìndà?
7 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ Kristẹni ṣì fi ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè, nígbà tó jẹ́ pé ó ti lé ní ogún ọdún sẹ́yìn tí Jèhófà ti fòpin sí Òfin náà? (Kól. 2:14) Lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tí wọ́n pàdé ní Jerúsálẹ́mù ti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn ìjọ láti ṣàlàyé fún wọn pé kò pọn dandan fáwọn tó di onígbàgbọ́ láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láti dádọ̀dọ́ tàbí pa Òfin Mósè mọ́. (Ìṣe 15:23-29) Àmọ́, lẹ́tà yẹn ò sọ̀rọ̀ nípa àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ò mọ̀ pé Òfin Mósè ò wúlò mọ́.
8 Ṣé èrò tí kò tọ́ táwọn Júù yìí ní wá túmọ̀ sí pé wọn kì í ṣe Kristẹni mọ́? Rárá o. Kì í kúkú ṣe pé wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ abọ̀rìṣà tí wọ́n wá tún pa dà sídìí àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà náà. Ó ṣe tán, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fún àwọn Júù tó di onígbàgbọ́ yẹn ní Òfin tí wọ́n ṣì kà sí pàtàkì yìí. Òfin yẹn ò ní ìbẹ́mìílò nínú, kò sì sí nǹkan tó burú nínú ẹ̀. Àmọ́, májẹ̀mú yìí dá lórí Òfin Mósè, nígbà tó sì jẹ́ pé májẹ̀mú tuntun làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé báyìí. Jèhófà ó retí pé kí wọ́n pa òfin Mósè mọ́ kí òun tó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Àwọn Júù tó di Kristẹni tí wọ́n ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè ò gbára lé Jèhófà, wọn ò fẹ́ tẹ̀ lé ètò tuntun tí Jèhófà ṣe, wọn ò sì lóye pé àwọn ò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin mọ́. Ó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe èrò wọn kó lè wà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa májẹ̀mú Òfin.b—Jer. 31:31-34; Lúùkù 22:20.
-
-
“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
a Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn Júù tó di Kristẹni pọ̀ tóyẹn ní Jerúsálẹ́mù, ó ní láti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń pàdé nínú ilé àdáni.
-