ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
    • 7 Kristẹni kan lè fi àṣìṣe rò pé ọkàn tòun kò lè ṣi òun lọ́nà bí ọkàn àwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà ṣe ṣì wọ́n lọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè ronú pé, ‘Mo gbọ́dọ̀ níṣẹ́ gidi kan lọ́wọ́ tí màá fi máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi.’ Ìyẹn ò sì burú. Àmọ́ tí èrò yìí bá wá mú kó wò ó pé, ‘Ó yẹ kí n kàwé sí i kí n lè ríṣẹ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀ táá sì máa mówó gidi wọlé’ ńkọ́? Ìyẹn náà lè má burú lójú tiẹ̀, kó sì máa wá ronú pé: ‘Nǹkan ti yí pa dà láyé ìsìnyí o, téèyàn ò bá lọ yunifásítì ọkàn èèyàn ò lè balẹ̀ lórí iṣẹ́ tó ń ṣe.’ Ẹ ò rí i pé, láìpẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n, tó bojú mu tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye fún wa lórí ọ̀rọ̀ kíkàwé sí i nílé ẹ̀kọ́ gíga, tónítọ̀hún á sì dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ! Àwọn kan tiẹ̀ ti jẹ́ kí ọ̀nà táwọn èèyàn ayé gbà ń ronú àti ojú tí wọ́n fi ń wo ọ̀rọ̀ kíkàwé nílé ẹ̀kọ́ gíga, nípa lórí àwọn. (Éfé. 2:2, 3) Bíbélì kìlọ̀ fún wa lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ayé yìí sọ yín dà bó ṣe dà.”—Róòmù 12:2, Bíbélì Phillips.a

      Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 46

      Ṣé ọkàn rẹ kò ti tàn ọ́ jẹ débi pé kó o máa pa ìpàdé jẹ?

  • Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
    • a Bíbélì NET (2005) kà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ayé mú ẹ tẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀.” Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Ó ṣe kedere pé àwọn kan wo ọ̀rọ̀ náà ‘mú ẹ tẹ̀ sí’ tó wà nínú ẹsẹ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun téèyàn ń ṣe láìfura. Ṣùgbọ́n, . . . déwọ̀n àyè kan, ó lè jẹ́ ohun téèyàn ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Àmọ́ ṣá, ó jọ pé ọ̀nà méjèèjì ni ayé gbà ń múni tẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́