-
Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn ẸlòmírànIlé Ìṣọ́—2002 | June 15
-
-
6, 7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká kọ́kọ́ kọ́ ara wa? (b) Báwo làwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ṣe kùnà gẹ́gẹ́ bí olùkọ́?
6 Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé ká kọ́kọ́ kọ́ ara wa ná? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò lè kọ́ àwọn ẹlòmíì dáadáa bí a kò bá kọ́kọ́ kọ́ ara wa. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nínú ọ̀rọ̀ kan tí ń ró kìì lọ́kàn ẹni, tó ní ìtumọ̀ wíwúwo fáwọn Júù ayé ìgbà yẹn, tó sì kan àwa Kristẹni gbọ̀ngbọ̀n lóde òní. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ, ẹni tí ń fi ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn hàn sí àwọn òrìṣà, ìwọ ha ń ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè bí? Ìwọ, ẹni tí ń yangàn nínú òfin, ǹjẹ́ ìwọ nípasẹ̀ ríré tí o ń ré Òfin kọjá ha ń tàbùkù sí Ọlọ́run bí?”—Róòmù 2:21-23.
7 Nípa lílo ìbéèrè mọ̀ọ́nú, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ìwà àìtọ́ méjì tí Òfin Mẹ́wàá dìídì kà léèwọ̀, ìyẹn ni: Má jalè, má ṣe panṣágà. (Ẹ́kísódù 20:14, 15) Àwọn Júù kan nígbà ayé Pọ́ọ̀lù ń yangàn pé àwọn ní Òfin Ọlọ́run. A ‘fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún wọn ní ìtọ́ni láti inú Òfin, wọ́n sì gbà pé àwọn ni afinimọ̀nà fún àwọn afọ́jú àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn, olùkọ́ àwọn ọmọ kéékèèké.’ (Róòmù 2:17-20) Àmọ́ alágàbàgebè làwọn kan nínú wọn. Nítorí pé wọ́n ń jalè, wọ́n sì ń ṣe panṣágà lábẹ́lẹ̀. Wọ́n ń tàbùkù sí Òfin àti sí Ọlọ́run tó ṣòfin. Ìwọ náà kò ní ṣàìgbà pé wọn ò tóótun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn; àní wọn ò kọ́ ara wọn.
8. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí àwọn Júù kan nígbà ayé Pọ́ọ̀lù gbà máa “ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè”?
8 Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan jíja àwọn tẹ́ńpìlì lólè. Ó ha lè jẹ́ pé àwọn Júù kan ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi ni bí? Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ká sòótọ́, nítorí àìsí ìsọfúnni púpọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, a ò lè sọ pàtó bí àwọn Júù kan ṣe “ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè.” Kó tó dìgbà yẹn, akọ̀wé ìlú Éfésù kéde pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù kì í ṣe “ọlọ́ṣà tẹ́ńpìlì,” tó fi hàn pé ó kéré tán àwọn èèyàn kan ronú pé ẹ̀sùn yẹn ṣeé fi kan àwọn Júù. (Ìṣe 19:29-37) Ó ha lè jẹ́ pé wọ́n ń lo àwọn ohun iyebíye tí àwọn ajagunṣẹ́gun tàbí àwọn onítara ẹ̀sìn kó nínú àwọn tẹ́ńpìlì abọ̀rìṣà, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń ta nǹkan wọ̀nyí? Ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ ni pé kí wọ́n ba wúrà àti fàdákà ara àwọn òrìṣà jẹ́, wọn ò gbọ́dọ̀ mú un lò. (Diutarónómì 7:25)a Ó kúkú lè jẹ́ àwọn Júù tó tàpá sófin Ọlọ́run, tí wọ́n ń lo àwọn ohun tó wá látinú tẹ́ńpìlì abọ̀rìṣà tàbí tí wọ́n fi ń ṣòwò ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí.
9. Àwọn ìwà àìtọ́ wo làwọn kan ń hù ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì lólè?
9 Yàtọ̀ síyẹn, Josephus ròyìn nǹkan ìtìjú tí àwọn Júù mẹ́rin, tí òléwájú wọ́n jẹ́ olùkọ́ Òfin, ṣe nílùú Róòmù. Àwọn mẹ́rin yìí lọ tan obìnrin ará Róòmù kan, tó jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù jẹ, pé kí ó kó wúrà àtàwọn nǹkan ìní rẹ̀ mìíràn wá, kí àwọ́n bá a fi ta tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́rẹ. Gbàrà tí wọ́n gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ rẹ̀, ńṣe ni wọ́n sọ ìṣúra yìí di tara wọn—tí kò yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì lólè.b Àwọn mìíràn ń ṣe ohun tí kò yàtọ̀ sí jíja tẹ́ńpìlì Ọlọ́run lólè nípa fífi àwọn ẹran tó lábùkù rúbọ àti nípa títa àwọn nǹkan ní ọ̀wọ́n gógó ní àgbègbè tẹ́ńpìlì, tí wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ tẹ́ńpìlì di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Mátíù 21:12, 13; Málákì 1:12-14; 3:8, 9.
-
-
Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn ẸlòmírànIlé Ìṣọ́—2002 | June 15
-
-
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Josephus sọ pé àwọn Júù kò tàbùkù sí àwọn nǹkan mímọ́, ó tún òfin Ọlọ́run sọ lọ́nà yìí: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣáátá òrìṣà táwọn ìlú mìíràn ń bọ, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe ja àwọn tẹ́ńpìlì ilẹ̀ òkèèrè lólè, kí wọ́n má sì lọ kó ìṣúra tí wọ́n ti yà sí mímọ́ fún òrìṣà èyíkéyìí.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—Jewish Antiquities, Ìwé Kẹrin, orí kẹjọ, ìpínrọ̀ kẹwàá.
-